Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Saturday Àkọ́kọ́ Lóṣù January
“Àwọn kan gbà pé ìwé àsọtẹ́lẹ̀ tó ṣeé fọkàn tán ni Bíbélì. Àwọn míì rò pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí kò ṣe kedere, tí ẹnikẹ́ni lè túmọ̀ rẹ̀ sí ibi tó wù ú ló wà nínú rẹ̀. Kí lèrò tìẹ?” Jẹ́ kí ó fèsì. Lẹ́yìn náà, fún onílé ní ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ January 1, kẹ́ ẹ sì jọ ṣàyẹ̀wò àlàyé tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí àkọ́kọ́ lójú ìwé 16, kẹ́ ẹ wá ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, ó kéré tán. Béèrè bóyá ó máa fẹ́ láti gba ìwé ìròyìn náà, kẹ́ ẹ sì jọ ṣàdéhùn ìgbà tó o máa pa dà lọ láti dáhùn ìbéèrè tó kàn.
Ilé Ìṣọ́ January 1
“Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ la lè rí kọ́ lára àwọn ọkùnrin àti obìnrin tó jẹ́ èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn tí wọ́n ti gbé ayé rí. Ṣé o gbà bẹ́ẹ̀? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sọ̀rọ̀ nípa ọkùnrin kan tó jẹ́ ẹni ńlá, òun sì ni ẹnì kan ṣoṣo tí Bíbélì pè ní ‘ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.’ [Ka Jákọ́bù 2:23.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ìdí tí Ọlọ́run fi pè Ábúráhámù ní ọ̀rẹ́ òun, àti ẹ̀kọ́ tá a lè rí kọ́ lára rẹ̀.”
Ji! January–March
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ni nǹkan ti sú nítorí ìṣòro àìrówóná. Kí lo rò pé ó fà á tí awọ kò fi kájú ìlù? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n wà nínú Bíbélì èyí tó ti mú kí àwọn èèyàn mọ bí wọ́n ṣe lè máa ṣọ́wó ná. [Ka ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà ní ojú ìwé 8 àti 9.] Ìwé ìròyìn yìí fúnni ní àwọn àbá tó wúlò, tó lè ṣèrànwọ́ fún àwọn tí wọ́n ń wá bí wọ́n ṣe máa bọ́ nínú gbèsè.”