ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/12 ojú ìwé 8
  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
km 12/12 ojú ìwé 8

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Sátidé Àkọ́kọ́ Lóṣù January

“Jọ̀wọ́ mo fẹ́ mọ ohun tó o rò lórí ọ̀rọ̀ yìí. Tí wọ́n bá bi ẹ́ pé kí lorúkọ Ọlọ́run, kí lo máa sọ? [Jẹ́ kó fèsì.] Wo ohun tí ìwé yìí sọ.” Fún onílé ní Ilé Ìṣọ́ January 1, fi àpilẹ̀kọ tó wà ní èèpo ẹ̀yìn ìwé hàn án, kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò ìsọfúnni tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí àkọ́kọ́ àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí níbẹ̀. Fún un ní ìwé ìròyìn náà, kó o sì ṣètò láti pa dà lọ jíròrò ìdáhùn sí ìbéèrè tó kàn.

Ilé Ìṣọ́ January 1

“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń sọ pé ayé yìí máa pa rẹ́. Ǹjẹ́ o rò pé ó yẹ ká máa bẹ̀rù pé ayé yìí máa pa rẹ́? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì sọ pé kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa ṣègbé. [Ka 1 Jòhánù 2:17.] Ìwé ìròyìn yìí jẹ́ ká mọ bí Bíbélì ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè mẹ́rin táwọn èèyàn sábà máa ń béèrè nípa òpin ayé.”

Jí! January–February

“À ń lọ sọ́dọ̀ àwọn ìdílé láti bá wọn jíròrò àwọn kókó pàtàkì kan tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́. Ǹjẹ́ o rò pé ó ṣe pàtàkì pé kí bàbá, ìyá àtàwọn ọmọ máa ṣe ohun tí Jésù sọ nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí? [Ka Ìṣe 20:35b. Lẹ́yìn náà, jẹ́ kó fèsì.] Ẹ ò rí i pé iṣẹ́ kékeré kọ́ làwọn òbí máa ṣe kí wọ́n tó lè kọ́ àwọn ọmọ wọn níwà ọmọlúwàbí lóde òní. Ìwé yìí sọ báwọn òbí ṣe lè kọ́ àwọn ọmọ wọn ní ìwà ọmọlúwàbí.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́