Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní December: Ẹ lo àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú tẹ́ ẹ bá ní lọ́wọ́. Bí onílé bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa, ẹ fi bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn án, kí ẹ lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, Tẹ́tí sí Ọlọ́run tàbí Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé. January àti February: Ẹ lo ọ̀kan lára àwọn ìwé olójú ewé méjì-lé-lọ́gbọ̀n yìí: Tẹ́tí sí Ọlọ́run, Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé tàbí Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run! Kẹ́ ẹ sì sapá láti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà ìpadàbẹ̀wò, ẹ lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni tàbí èyí tẹ́ ẹ bá rí i pé ó máa túbọ̀ wúlò dáadáa fún onílé lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ náà. March: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò ẹ lè fún onílé ní ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni tàbí kẹ́ ẹ fún un ní èyí tẹ́ ẹ bá rí i pé ó máa nífẹ̀ẹ́ sí nínú ìwé pẹlẹbẹ Tẹ́tí sí Ọlọ́run tàbí Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé, kẹ́ ẹ sì sapá láti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
◼ Ọjọ́ Monday, April 14 la máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi lọ́dún 2014.
◼ Àwọn akéde tó bá fẹ́ ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ní oṣù March ọdún 2013, máa ní àǹfààní láti pinnu bóyá ọgbọ̀n [30] wákàtí tàbí àádọ́ta [50] wákàtí làwọn máa ṣe ní oṣù náà. Láfikún sí i, láwọn ìjọ tí alábòójútó àyíká bá bẹ̀ wò ní oṣù náà, gbogbo àwọn tó bá ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù yẹn, yálà ọgbọ̀n [30] wákàtí tàbí àádọ́ta [50] wákàtí ni wọ́n pinnu láti ṣe, ló máa láǹfààní láti wà ní ìpàdé tí alábòójútó àyíká máa bá àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé ṣe, wọ́n sì máa wà níbẹ̀ látìbẹ̀rẹ̀ dópin.