Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ January 7
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JANUARY 7, 2013
Orin 104 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 3 ìpínrọ̀ 13 sí 19 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Mátíù 1-6 (10 min.)
No. 1: Mátíù 5:21-32 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Àwọn Wo Ni Òfin Sábáàtì Wà Fún?—td 42B (5 min.)
No. 3: Kí Ló Túmọ̀ sí Láti Fi Jèhófà Ṣe “Ìpín Rẹ?”—Núm. 18:20 (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Àwọn Àbá Tá A Lè Lò Láti Fi Ìwé Ìròyìn Lọni Lóṣù January. Ìjíròrò. Fi ààbọ̀ ìṣẹ́jú sí ìṣẹ́jú kan sọ ìdí táwọn èèyàn fi máa nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ìwé ìròyìn wa ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Lẹ́yìn náà, lo àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Ilé Ìṣọ́ January, ní kí àwọn ará sọ àwọn ìbéèrè tó lè jẹ́ kí àwọn onílé nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wọn. Lẹ́yìn náà, ní kí wọ́n tún sọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè fi ti ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn. Ohun kan náà ni kó o ṣe nípa àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Jí! January–February 2013. Bí àkókò bá ṣì wà, ẹ tún lè jíròrò àpilẹ̀kọ mìíràn nínú ọ̀kan lára ìwé ìròyìn méjèèjì. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà lọni.
10 min: Ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Gbọ̀ngàn Ìjọba Tó Mọ́ Tónítóní Ń Bọlá Fún Jèhófà. Alàgbà ni kó sọ àsọyé yìí. Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run mímọ́, torí náà ó yẹ kí àwa èèyàn rẹ̀ máa fún ọ̀rọ̀ ìmọ́tótó ní àfiyèsí àrà ọ̀tọ̀. (Ẹ́kís. 30:17-21; 40:30-32) Tá a bá ń rí i dájú pé ibi tá a ti ń jọ́sìn wà ní mímọ́ tónítóní tá a sì ń tún un ṣe bó ṣe yẹ, èyí á máa fògo fún Jèhófà. (1 Pét. 2:12) Sọ ìrírí kan tó ṣẹlẹ̀ lágbègbè yín tàbí èyí tó o kà nínú ìtẹ̀jáde wa nípa bí Gbọ̀ngàn Ìjọba tó mọ́ tónítóní ṣe ṣí ọ̀nà sílẹ̀ láti wàásù. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu arákùnrin tó ń bójú tó ìmọ́tótó Gbọ̀ngàn Ìjọba nínú ìjọ yín. Gba àwọn ará níyànjú láti máa kópa déédéé nínu iṣẹ́ ìmọ́tótó náà.
Orin 127 àti Àdúrà