Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní December: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Bí àwọn ọmọdé bá wà nínú ilé náà, kẹ́ ẹ lo ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà tàbí Ìwé Ìtàn Bíbélì. January: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà àkọ́kọ́ tẹ́ ẹ bá fún ẹnì kan ní ìwé náà. Bí onílé bá ti ní ìwé yìí tí kò sì gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ẹ fún un ní ìwé ìròyìn tàbí ìwé pẹlẹbẹ èyíkéyìí tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ tí onílé náà máa nífẹ̀ẹ́ sí. February: Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé àti Sún Mọ́ Jèhófà. March: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà àkọ́kọ́ tẹ́ ẹ bá fún ẹnì kan ní ìwé náà.
◼ Ọjọ́ Tuesday, March 26 la máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi lọ́dún 2013.