Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ January 2
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JANUARY 2, 2012
Orin 118 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 15 ìpínrọ̀ 1 sí 7, àti àpótí tó wà lójú ìwé 116 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Aísáyà 24-28 (10 min.)
No. 1: Aísáyà 27:1-13 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Má Ṣiyèméjì Láé Pé Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Rẹ—Aísá. 57:15 (5 min.)
No. 3: Lílo Ère Nínú Ìjọsìn Jẹ́ Ẹ̀gàn sí Ọlọ́run—td 9A (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Àwọn Ìfilọ̀. Lo àbá tó wà lójú ìwé yìí láti ṣe àṣefihàn béèyàn ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Saturday àkọ́kọ́ lóṣù January.
10 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
15 min: Àwọn àbá tá a lè lò láti fi ìwé ìròyìn lọni ní oṣù January. Ìjíròrò. Fi ìṣẹ́jú kan tàbí méjì tọ́ka sí àwọn àpilẹ̀kọ tó lè fa àwọn èèyàn mọ́ra ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Lẹ́yìn náà, lo àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Ilé Ìṣọ́ yìí, kó o sì ní kí àwọn ará sọ àwọn ìbéèrè tó lè mú kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wọn, kí wọ́n sì sọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n á fi ti ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn. Ohun kan náà ni kó o ṣe nípa àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Jí! January–March, tí àkókò bá ṣì wà, ẹ tún lè jíròrò àpilẹ̀kọ mìíràn nínú ìwé ìròyìn méjèèjì. Ẹ rọ àwọn akéde pé kí wọ́n sapá lákànṣe láti fi Jí! January–March lọ àwọn èèyàn ní àwọn ibi tí wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ ajé. Ní kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn sọ ètò tí ìjọ ṣe nípa èyí. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà lọni. Nínú àṣefihàn tẹ́ ẹ ti máa fi Jí! lọni, ẹ ṣe é níbi tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ ajé.
Orin 86 àti Àdúrà