ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 57
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Àìsáyà

      • Olódodo àti àwọn olóòótọ́ ṣègbé (1, 2)

      • Àgbèrè ẹ̀sìn tí Ísírẹ́lì ń ṣe hàn síta (3-13)

      • A tu àwọn ẹni rírẹlẹ̀ nínú (14-21)

        • Àwọn ẹni burúkú dà bí òkun tó ń ru (20)

        • Kò sí àlàáfíà fún ẹni burúkú (21)

Àìsáyà 57:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn ni pé, wọ́n kú.

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “Kúrò lọ́wọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mik 7:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 262-263

Àìsáyà 57:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, nínú sàréè.

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 262-263

Àìsáyà 57:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 263-264

Àìsáyà 57:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 1:4; 30:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 263-264

Àìsáyà 57:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 1:29
  • +Di 12:2; 1Ọb 14:22, 23
  • +2Ọb 16:1, 3; Jer 7:31

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 263-264

Àìsáyà 57:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ṣé kí n fi àwọn nǹkan yìí tu ara mi nínú ni?”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 3:9
  • +Jer 7:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 264-265

Àìsáyà 57:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 2:20; Isk 16:16; 23:17
  • +Isk 20:28

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 265

Àìsáyà 57:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìjọsìn òrìṣà ló ń sọ.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 16:25, 33; 23:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 265-266

Àìsáyà 57:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “ọba.”

  • *

    Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 266-267

Àìsáyà 57:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “tí kò fi rẹ̀ ọ́.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 268

Àìsáyà 57:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “fi ọ̀rọ̀ pa mọ́?”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 30:9, 10; 59:3
  • +Ais 1:3; Jer 2:32; 9:3
  • +Ais 42:24, 25
  • +Sm 50:21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 268-269

Àìsáyà 57:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 58:2
  • +Ais 66:3
  • +Jer 7:4; Mik 3:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 269

Àìsáyà 57:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 10:14; Ais 42:17
  • +Ais 56:6, 7; 66:20; Isk 20:40; Joẹ 3:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 269-270

Àìsáyà 57:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 35:8; 40:3; 62:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 270, 272

Àìsáyà 57:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Tó ń gbé.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 21:33; Sm 90:2; Ais 40:28; 1Ti 1:17
  • +Ẹk 15:11; Lk 1:46, 49
  • +1Ọb 8:27
  • +Sm 34:18; 147:3; Ais 61:1; 66:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/15/2005, ojú ìwé 26-27

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 270-272

Àìsáyà 57:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 103:9; Mik 7:18
  • +Job 34:14, 15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 271

Àìsáyà 57:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 6:13; 8:10
  • +Jer 3:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 271-272

Àìsáyà 57:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Màá sì fi ìtùnú san àsandípò fún òun àti àwọn èèyàn rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 33:6; Ho 14:4
  • +Ais 49:10
  • +Ais 61:2; Ida 1:4
  • +Ais 12:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 271-272

Àìsáyà 57:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 48:18; Ef 2:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 272-274

Àìsáyà 57:20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 272-274

Àìsáyà 57:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 13:9; Ais 3:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 272-274

    Ilé Ìṣọ́,

    10/1/1999, ojú ìwé 11

Àwọn míì

Àìsá. 57:1Mik 7:2
Àìsá. 57:4Ais 1:4; 30:9
Àìsá. 57:5Ais 1:29
Àìsá. 57:5Di 12:2; 1Ọb 14:22, 23
Àìsá. 57:52Ọb 16:1, 3; Jer 7:31
Àìsá. 57:6Jer 3:9
Àìsá. 57:6Jer 7:18
Àìsá. 57:7Jer 2:20; Isk 16:16; 23:17
Àìsá. 57:7Isk 20:28
Àìsá. 57:8Isk 16:25, 33; 23:18
Àìsá. 57:11Ais 30:9, 10; 59:3
Àìsá. 57:11Ais 1:3; Jer 2:32; 9:3
Àìsá. 57:11Ais 42:24, 25
Àìsá. 57:11Sm 50:21
Àìsá. 57:12Ais 58:2
Àìsá. 57:12Ais 66:3
Àìsá. 57:12Jer 7:4; Mik 3:4
Àìsá. 57:13Ond 10:14; Ais 42:17
Àìsá. 57:13Ais 56:6, 7; 66:20; Isk 20:40; Joẹ 3:17
Àìsá. 57:14Ais 35:8; 40:3; 62:10
Àìsá. 57:15Jẹ 21:33; Sm 90:2; Ais 40:28; 1Ti 1:17
Àìsá. 57:15Ẹk 15:11; Lk 1:46, 49
Àìsá. 57:151Ọb 8:27
Àìsá. 57:15Sm 34:18; 147:3; Ais 61:1; 66:2
Àìsá. 57:16Sm 103:9; Mik 7:18
Àìsá. 57:16Job 34:14, 15
Àìsá. 57:17Jer 6:13; 8:10
Àìsá. 57:17Jer 3:14
Àìsá. 57:18Jer 33:6; Ho 14:4
Àìsá. 57:18Ais 49:10
Àìsá. 57:18Ais 61:2; Ida 1:4
Àìsá. 57:18Ais 12:1
Àìsá. 57:19Ais 48:18; Ef 2:17
Àìsá. 57:21Owe 13:9; Ais 3:11
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Àìsáyà 57:1-21

Àìsáyà

57 Olódodo ṣègbé,

Àmọ́ ẹnì kankan ò fi sọ́kàn.

Àwọn olóòótọ́ èèyàn ti lọ,*+

Ẹnì kankan ò sì fòye mọ̀ pé olódodo ti lọ

Torí* àjálù náà.

 2 Ó wọnú àlàáfíà.

Wọ́n sinmi lórí ibùsùn wọn,* gbogbo àwọn tó ń rìn lọ́nà títọ́.

 3 “Àmọ́ ní tiyín, ẹ sún mọ́ tòsí,

Ẹ̀yin ọmọ àjẹ́,

Ẹ̀yin ọmọ alágbèrè àti aṣẹ́wó:

 4 Ta lẹ fi ń ṣe yẹ̀yẹ́?

Ta lẹ la ẹnu gbàù sí, tí ẹ sì yọ ahọ́n yín sí?

Ṣebí ọmọ ẹ̀ṣẹ̀ ni yín,

Ẹ̀yin ọmọ ẹ̀tàn,+

 5 Tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti kó sí lórí láàárín àwọn igi ńlá,+

Lábẹ́ gbogbo igi tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀,+

Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń pa àwọn ọmọ ní àwọn àfonífojì,+

Lábẹ́ àwọn pàlàpálá àpáta?

 6 Ìpín rẹ wà níbi àwọn òkúta tó jọ̀lọ̀ ní àfonífojì.+

Àní, àwọn ni ìpín rẹ.

Kódà, àwọn lò ń da ọrẹ ohun mímu sí, tí o sì ń mú ẹ̀bùn wá fún.+

Ṣé àwọn nǹkan yìí máa tẹ́ mi lọ́rùn?*

 7 Orí òkè tó ga, tó ta yọ lo gbé ibùsùn rẹ sí,+

O sì gòkè lọ síbẹ̀ láti rúbọ.+

 8 Ẹ̀yìn ilẹ̀kùn àti férémù ilẹ̀kùn lo gbé ìrántí rẹ kalẹ̀ sí.

O fi mí sílẹ̀, o sì ṣí ara rẹ sílẹ̀;

O lọ, o sì mú kí ibùsùn rẹ fẹ̀ dáadáa.

O sì bá wọn dá májẹ̀mú.

O máa ń fẹ́ bá wọn pín ibùsùn wọn,+

O sì ń wo nǹkan ọkùnrin.*

 9 O sọ̀ kalẹ̀ lọ sọ́dọ̀ Mélékì* pẹ̀lú òróró

Àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ́fínńdà.

O rán àwọn aṣojú rẹ lọ sọ́nà jíjìn,

Tí o fi sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú Isà Òkú.*

10 O ti ṣiṣẹ́ kára láti rìn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà rẹ.

Àmọ́ o ò sọ pé, ‘Kò sírètí!’

A wá sọ agbára rẹ dọ̀tun.

Ìdí nìyẹn tí o kò fi sọ̀rètí nù.*

11 Ta ló ń já ọ láyà, tí ẹ̀rù rẹ̀ sì ń bà ọ́,

Tí o fi bẹ̀rẹ̀ sí í parọ́?+

O ò rántí mi.+

O ò fi nǹkan kan sọ́kàn.+

Ṣebí mo ti dákẹ́, tí mo sì fà sẹ́yìn?*+

O ò wá bẹ̀rù mi rárá.

12 Màá fi ‘òdodo’+ rẹ àti àwọn iṣẹ́ rẹ+ hàn,

Wọn ò sì ní ṣe ọ́ láǹfààní.+

13 Tí o bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́,

Àwọn òrìṣà tí o kó jọ ò ní gbà ọ́ sílẹ̀.+

Atẹ́gùn máa gbé gbogbo wọn lọ,

Èémí lásán máa fẹ́ wọn lọ,

Àmọ́ ẹni tó bá fi mí ṣe ibi ààbò máa jogún ilẹ̀ náà,

Ó sì máa gba òkè mímọ́ mi.+

14 Wọ́n máa sọ pé, ‘Ẹ ṣe ọ̀nà, ẹ ṣe é! Ẹ tún ọ̀nà ṣe!+

Ẹ mú gbogbo ohun ìdíwọ́ kúrò ní ọ̀nà àwọn èèyàn mi.’”

15 Torí ohun tí Ẹni Gíga àti Ẹni Tó Ta Yọ sọ nìyí,

Tó wà láàyè* títí láé,+ tí orúkọ rẹ̀ sì jẹ́ mímọ́:+

“Ibi gíga àti ibi mímọ́ ni mò ń gbé,+

Àmọ́ mo tún ń gbé pẹ̀lú àwọn tí a tẹ̀ rẹ́, tí wọ́n sì rẹ̀wẹ̀sì ní ẹ̀mí,

Láti mú kí ẹ̀mí ẹni tó rẹlẹ̀ sọ jí,

Kí n sì mú kí ọkàn àwọn tí a tẹ̀ rẹ́ sọ jí.+

16 Torí mi ò ní ta kò wọ́n títí láé,

Mi ò sì ní máa bínú títí lọ;+

Torí àárẹ̀ máa bá ẹ̀mí èèyàn nítorí mi,+

Títí kan àwọn ohun tó ń mí, tí mo dá.

17 Inú bí mi torí ẹ̀ṣẹ̀ tó dá, bó ṣe ń wá èrè tí kò tọ́,+

Torí náà, mo kọ lù ú, mo fi ojú mi pa mọ́, inú sì bí mi.

Àmọ́ kò yéé rìn bí ọ̀dàlẹ̀,+ ó ń ṣe ìfẹ́ ọkàn rẹ̀.

18 Mo ti rí àwọn ọ̀nà rẹ̀,

Àmọ́ màá wò ó sàn,+ màá sì darí rẹ̀,+

Màá mú kí òun àti àwọn èèyàn rẹ̀+ tó ń ṣọ̀fọ̀ pa dà rí ìtùnú.”*+

19 “Màá dá èso ètè.

Màá fún ẹni tó wà lọ́nà jíjìn àti ẹni tó wà nítòsí ní àlàáfíà tí kò lópin,”+ ni Jèhófà wí,

“Màá sì wò ó sàn.”

20 “Àmọ́ àwọn ẹni burúkú dà bí òkun tó ń ru, tí kò lè rọ̀ wọ̀ọ̀,

Omi rẹ̀ sì ń ta koríko inú òkun àti ẹrẹ̀ sókè.

21 Kò sí àlàáfíà fún ẹni burúkú,”+ ni Ọlọ́run mi wí.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́