Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣe àtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní December 26, 2011.
1. Báwo ni ìtọ́ni tó wà nínú Òwe 30:32 ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ tí a kò fi ní jẹ́ kí inú túbọ̀ bí ẹnì kan tó ṣeé ṣe ká ti ṣẹ̀ tẹ́lẹ̀? [w87 5/15 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 11]
2. Irú “ayọ̀ yíyọ̀” wo ló máa ń jẹ́ kéèyàn nímọ̀lára pé àṣedànù lòun ń ṣe? (Oníw. 2:1) [g 4/06 ojú ìwé 6, ìpínrọ̀ 1 àti 2]
3. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èrò àwọn kan ni pé ọ̀rọ̀ Sólómọ́nì tó wà ní Oníwàásù 3:1-9 fi hàn pé Ọlọ́run ti kádàrá gbogbo ohun tá à ń ṣe láyé, báwo ni ohun tí Sólómọ́nì kọ ní Oníwàásù 9:11 ṣe fi hàn pé Ọlọ́run kò kádàrá gbogbo ohun tá à ń ṣe láyé? [w09 3/1 ojú ìwé 4, ìpínrọ̀ 4]
4. Ewu wo ló wà nínú kéèyàn jẹ́ “olódodo àṣelékè”? (Oníw. 7:16) [w10 10/15 ojú ìwé 9, ìpínrọ̀ 8 àti 9]
5. Báwo ni Orin Sólómọ́nì 2:7 ṣe fi hàn pé ìwà ọgbọ́n ló jẹ́ fún àwọn tó ń gbèrò láti ṣègbéyàwó pé kí wọ́n má ṣe kánjú tí wọ́n bá fẹ́ yan ẹni tí wọ́n máa fẹ́? [w06 11/15 ojú ìwé 19, ìpínrọ̀ 1; w80 10/15 ojú ìwé 19, ìpínrọ̀ 7]
6. Kí ló gba àfiyèsí nínú bí ‘afárá oyin ṣe ń kán tótó ní ètè’ omidan Ṣúlámáítì àti bí ‘oyin àti wàrà ṣe wà lábẹ́ ahọ́n rẹ̀’? (Orin Sól. 4:11) [w06 11/15 ojú ìwé 19, ìpínrọ̀ 6]
7. Báwo ni àwọn orúkọ oyè náà “Àgbàyanu Agbani-nímọ̀ràn,” “Ọlọ́run Alágbára Ńlá,” àti “Baba Ayérayé” ṣe jẹ́ ká ní òye nípa àwọn ànímọ́ tí Jésù ní àti bí ìṣàkóso rẹ̀ nínú ayé tuntun ṣe máa rí? (Aísá. 9:6) [w91 4/15 ojú ìwé 5 àti 6, ìpínrọ̀ 7]
8. Àwọn wo la lè fi “orílẹ̀-èdè apẹ̀yìndà,” ìyẹn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wé lóde òní, ta ló sì máa jẹ́ “ọ̀pá” tí Jèhófà máa lò láti fọ́ wọn túútúú? (Aísá. 10:5, 6) [ip-1 ojú ìwé 145, ìpínrọ̀ 4 àti 5; ojú ìwé 152 àti 153, ìpínrọ̀ 20]
9. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà pé Bábílónì máa dahoro ṣe nímùúṣẹ, báwo sì ni ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ ẹni lágbára? (Aísá. 13:19, 20) [bh ojú ìwé 24 àti 25, ìpínrọ̀ 16 àti 17]
10. Ìgbà wo ni Jésù gba “kọ́kọ́rọ́ ilé Dáfídì,” báwo ló sì ṣe ń lo kọ́kọ́rọ́ náà? (Aísá. 22:22) [w09 1/15 ojú ìwé 31, ìpínrọ̀ 2]