Àwọn Ìfilọ̀
◼Ìwé tá a máa lò ní December: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? tàbí Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́? January àti February: Ẹ lo èyíkéyìí lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé méjìlélọ́gbọ̀n yìí: Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!, Tẹ́tí sí Ọlọ́run tàbí Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé. March: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí!
◼ Ìrántí Ikú Kristi ti ọdún 2016 yóò wáyé ní Wednesday, March 23, 2016.
◼ Bẹ̀rẹ̀ láti January 1, 2015, ètò tí a ṣe pé kí àwọn ìjọ máa bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Sátidé àkọ́kọ́ lóṣooṣù yóò dópin. Dípò èyí, àwọn akéde lè máa lo ìwé ìròyìn bí wọ́n ti máa ń ṣe láwọn Sátidé yòókù. A lè máa fi àwọn ìwé ìròyìn tàbí àwọn ìtẹ̀jáde míì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbàkigbà lóṣù.