Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ January 5
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JANUARY 5, 2015
Orin 113 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl 18 ìpínrọ̀ 9 sí 19 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jóṣúà 16-20 (8 min.)
No. 1: Jóṣúà 17:11-18 (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ta Ni Ọlọ́run?—igw ojú ìwé 2 ìpínrọ̀ 1 sí 3 (5 min.)
No. 3: Bí Ìbẹ̀rù Ikú Ṣe Ń Sọ Àwọn Èèyàn Di Ẹrú—Héb. 2:15 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: Máa Mú àwọn “ohun rere” jáde láti inú ìṣúra rere tá a fi sí ìkáwọ́ wa.—Mát. 12:35á.
30 min: “Àwọn Orin Tuntun Tí A Ó Máa Lò Nínú Ìjọsìn!” Ìjíròrò. Tí ẹ bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 6, jẹ́ kí àwọn ará kọ́kọ́ gbọ́ orin tí a fi dùrù kọ tá a pe àkọlé rẹ̀ ní “Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso—Jẹ́ Kó Dé!” Lẹ́yìn náà, ní kí àwọn ará dìde dúró, kí wọ́n kọ orin tuntun yìí. Ẹ lè kọ orin yìí lẹ́ẹ̀mejì kí àwọn ará bàa lè mọ̀ ọ́n kọ. Tí ẹ bá kọ orin yìí tán, ẹ jókòó kí ẹ sì parí ìjíròrò ìpínrọ̀ tó kù. Ní ìparí ìpàdé, ní kí àwọn ará tún dìde dúró láti kọ orin tuntun yìí.
Orin tuntun “Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso—Jẹ́ Kó Dé!” àti Àdúrà