“Ìrànlọ́wọ́ Ní Àkókò Tí Ó Tọ́”
1 Ẹ wo bí ó ti ń tuni lára tó láti rí ìrànlọ́wọ́ gbà lákòókò tí a nílò rẹ̀ gẹ́lẹ́! (Héb. 4:16) Ní Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọ́run,” a láyọ̀ nígbà tí a fún wa ní àkànṣe ìpèsè ìrànwọ́ méjì ní àkókò tí ó tọ́ gan-an.
2 Ìwé tuntun náà, Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, dé ní àkókò tí ó bá a mu wẹ́kú. Ó darí àfiyèsí sí àwọn ohun pàtàkì mẹ́rin tí ń gbé ìgbésí ayé ìdílé aláyọ̀ lárugẹ: (1) Ìkóra-ẹni-níjàánu, (2) dídá ipò orí mọ̀, (3) ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ rere, àti (4) ìfẹ́. Ìṣílétí tí a fúnni nínú ìwé Ayọ̀ Ìdílé yóò ran gbogbo ìdílé tí ó bá fi í sílò lọ́wọ́ láti rí àlàáfíà Ọlọ́run. Ya àkókò sọ́tọ̀ láti fara balẹ̀ ka ìwé tuntun náà, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé. Dojúlùmọ̀ àwọn apá fífani mọ́ra rẹ̀ dáradára kí o baà lè múra sílẹ̀ láti lò ó lọ́nà gbígbéṣẹ́ nígbà tí a bá ń fi lọni ní gbangba fún ìgbà àkọ́kọ́, ní March.
3 Ìwé pẹlẹbẹ tuntun náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?, dé ní àkókò tí ó tọ́ láti ṣèrànwọ́ láti mú kí iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn tí a ń ṣe yára kánkán. Nígbà tí ó jẹ́ pé a lè lò ó ní pàtàkì láti ran àwọn ènìyàn tí kò lè kàwé dáradára lọ́wọ́, ọ̀pọ̀ àwọn àgbà àti ọ̀dọ́mọdé tí wọ́n mọ̀ọ́kọmọ̀ọ́kà yóò jàǹfààní láti inú àlàyé rírọrùn tí ó ṣe nípa àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì pẹ̀lú. Ó lè jẹ́ ohun tí a nílò gan-an láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ kan gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀gùn sínú ìwé Ìmọ̀. Ó dájú pé ìpèsè yí yóò ran púpọ̀ sí i lọ́wọ́ láti mọrírì bí a ṣe lè bù kún wọn ní jìngbìnnì tó nípa ṣíṣe ohun tí Ọlọ́run ń béèrè.
4 Dáfídì sọ ìmọ̀lára wa jáde lọ́nà pípé nígbà tí ó polongo pé, ‘òun kò ṣe aláìní ohunkóhun, a tu ọkàn òun lára, ife òun sì kún àkúnwọ́sílẹ̀!’ (Orin Dá. 23:1, 3, 5) A fi ìdùnnú wọ̀nà fún mímú àgbàyanu ìrànwọ́ tẹ̀mí yìí lọ fún ọ̀pọ̀ ẹlòmíràn tí wọ́n ní ìfẹ́ ọkàn aláìlábòsí láti mọ Ọlọ́run tòótọ́ náà, Jèhófà, kí wọ́n sì ṣiṣẹ́ sìn ín.