ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 1/15 ojú ìwé 5-9
  • Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọ́run Péjọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọ́run Péjọ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ‘Ẹni Tí Ń Kéde Àlàáfíà ti Dára Tó’
  • ‘Àlàáfíà Ọlọ́run Ta Gbogbo Ìrònú Yọ’
  • ‘Ẹ Máa Pa Ìṣọ̀kan Ṣoṣo Mọ́ Nínú Ìdè Asonipọ̀ Ṣọ̀kan Ti Àlàáfíà’
  • Ìwọ Kì Yóò Fẹ́ Láti Tàsé Rẹ̀!
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìwọ Yóò Ha Wà Níbẹ̀ Bí?
    Jí!—1996
  • “Àwọn Olùfi Ìtara Pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run” Péjọ Tayọ̀tayọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Ṣíṣiṣẹ́sìn Gẹ́gẹ́ Bí Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 1/15 ojú ìwé 5-9

Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọ́run Péjọ

KRISTẸNI alàgbà kan láti United States sọ pé: “A ti gbé wa ró nípasẹ̀ gbogbo àpéjọpọ̀ àgbègbè tí a ti lọ. Àmọ́, ti ọdún yìí kò ṣeé fẹnu sọ. Bí ilẹ̀ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ti ń ṣú ni a ń ṣe kàyéfì nípa bí ọjọ́ kejì yóò ṣe kọjá ohun tí a ń retí, a kò sì já wa kulẹ̀!”

Bí o bá lọ sí ọ̀kan nínú àwọn Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọ́run” kò sí iyè méjì pé, ìwọ yóò fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú onítara àyànṣaṣojú yìí. Ọjọ́ kọ̀ọ̀kan àpéjọpọ̀ náà darí àfiyèsí sórí apá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ti iṣẹ́ àṣẹ náà tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe gẹ́gẹ́ bí ońṣẹ́ Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ kí a ṣàtúnyẹ̀wò ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọlọ́jọ́ mẹ́ta náà.

‘Ẹni Tí Ń Kéde Àlàáfíà ti Dára Tó’

Èyí ni ẹṣin ọ̀rọ̀ ọjọ́ àkọ́kọ́ àpéjọpọ̀ náà. A gbé e ka Aísáyà 52:7. Ní àwọn àkókò líle koko wọ̀nyí, ọ̀pọ̀ ń ṣiṣẹ́ sin Jèhófà lábẹ́ àwọn àyíká ipò tí ń peni níjà. Ọ̀rọ̀ àsọyé náà, “Gbígbọ́rọ̀ Láti Ẹnu Àwọn Onítara Olùpòkìkí Àlàáfíà,” ní fífi ọ̀rọ̀ wá díẹ̀ lára àwọn wọ̀nyí tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ lẹ́nu wò nínú. Gbígbọ́ ọ̀rọ̀ láti ẹnu wọn fúnra wọn fúnni níṣìírí gidigidi, a sì tipa bẹ́ẹ̀ mú un dá àwọn tí o péjọ pọ̀ lójú pé, Jèhófà lè fún àwọn pẹ̀lú lókun, àní kí ó tilẹ̀ fún wọn ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lo ìfaradà.—Kọ́ríńtì Kejì 4:7.

Àwọn ohun tí Jèhófà ń béèrè kò nira. (Jòhánù Kíní 5:3) A mú èyí ṣe kedere nínú ọ̀rọ̀ àsọyé tí a sọ kẹ́yìn nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ òwúrọ̀, tí ó dé òtéńté rẹ̀ pẹ̀lú ìmújáde ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 náà, tí a pè ní, Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? Kò sí àní-àní pé àrànṣe tuntun fún ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó kún fún àwòrán rírẹwà yí yóò kó ipa pàtàkì nínú ríran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ láti kọ́ nípa ète Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ lórí bí a óò ṣe lo ìtẹ̀jáde tuntun yìí wà nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó kẹ́yìn nínú ìwé ìròyìn yìí àti ní ojú ìwé 16 àti 17.

Ọ̀rọ̀ àsọyé náà, “Lílo Ìfaradà Nínú Iṣẹ́ Rere,” tẹnu mọ́ ọn pé, Jèhófà mọ àwọn àdánwò wa dunjú. Láti lo ìfaradà túmọ̀ sí pé, kí a dúró sórí ẹsẹ̀ wa, kí a má sì sọ̀rètí nù. Jèhófà ti fún wa ní Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ẹ̀mí rẹ̀, àti ètò àjọ rẹ̀ láti ràn wá lọ́wọ́. Ó ń béèrè ìfaradà láti wàásù, síbẹ̀, ìwàásù ń ràn wá lọ́wọ́ láti lo ìfaradà, nítorí ó ń mú kí ìgbàgbọ́ wa wà láàyè. Níwọ̀n bí a ti ń sún mọ́ òpin eré ìje náà, kò yẹ kí a jẹ́ kí àwọn ìṣòro wa bomi paná ìtara wa, nítorí kìkì àwọn tí wọ́n bá fara dà á títí dé òpin ni a óò gbà là.—Mátíù 24:13.

Lájorí ọ̀rọ̀ àwíyé, “Ipa Iṣẹ́ Wa Gẹ́gẹ́ Bí Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọ́run,” darí àfiyèsí sí bí a ṣe dá àwọn Júù tí wọ́n wà nígbèkùn sílẹ̀ kúrò ní Bábílónì àti ìmúpadàbọ̀sípò ìjọsìn mímọ́ gaara ní Jerúsálẹ́mù ní ọdún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa. Olùbánisọ̀rọ̀ náà ṣàlàyé pé, ìṣẹ̀lẹ̀ yí, wulẹ̀ ń ṣàpèjúwe ohun tí Ìjọba Ọlọ́run yóò ṣàṣeparí rẹ̀ láìpẹ́ lọ́nà tí yóò kárí ayé. (Orín Dáfídì 72:7; Aísáyà 9:7) Iṣẹ́ àyànfúnni wa ti lọ́ọ́lọ́ọ́ jẹ́ láti wàásù ìhìn rere nípa Ìjọba yìí àti láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìhìn iṣẹ́ yẹn. Ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti aládùúgbò yẹ kí ó sún wa láti máa bá ṣíṣe iṣẹ́ yìí nìṣó láìdábọ̀.—Ìṣe 5:42.

Kókó pàtàkì nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ Friday ni àpínsọ ọ̀rọ̀ àsọyé náà, “Ṣọ́ra fún Àwọn Ìdẹkùn Fífara Sin Ti Eré Ìnàjú.” Orin, sinimá, fídíò, eré orí tẹlifíṣọ̀n, eré ìdárayá ti fídíò, ìwé, ìwé ìròyìn, àti ìwé àkàrẹ́rìn-ín ti ó wà lónìí sábà ń ṣàgbéyọ ìrònú ẹ̀mí Èṣù. Nítorí náà, ó yẹ kí a “fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ohun burúkú.” (Róòmù 12:9) Bẹ́ẹ̀ ni, a gbọ́dọ̀ ka eré ìnàjú tí ń sọni dìbàjẹ́ sí ohun ẹ̀gàn, kí a sì fà sẹ́yìn fún un, nígbà tí a óò sì máa ronú lórí àwọn ohun mímọ́níwà, ohun tí ó jẹ́ ìwà funfun, àti ohun tí ó yẹ fún ìyìn. (Fílípì 4:8) Àwọn ìtẹ̀jáde àti irin iṣẹ́ ìṣèwádìí tí ètò àjọ Jèhófà ń pèsè ń fi àwọn èrò tí ń gbéni ró ru ọkàn wa sókè, ó sì ń kọ́ wa láti lè dá ohun tí ó tọ́ mọ̀ yàtọ̀ sí ohun tí kò tọ́. (Hébérù 5:14) A ní láti rọ̀ mọ́ àwọn ìpèsè wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí a óò ṣe rọ̀ mọ́ àdìpọ̀ igi lójú òkun tí ń ru gùdù.

Ọ̀rọ̀ àsọyé náà, “Kọjú Ìjà sí Èṣù—Má Gba Ìbáradíje Láyè,” ni ó tẹ̀ lé e. Kété ṣáájú kí wọ́n tó wọ Ilẹ̀ Ìlérí, a fi ìwà pálapàla dẹkùn mú ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Fíníhásì kò fàyè gba bíbá ìjọsìn tòótọ́ díje. Ó gbé ìgbésẹ̀ onípinnu lòdì sí àwọn oníwà àìtọ́, ìfọkànsìn rẹ̀ tí ó yà sọ́tọ̀ gédégbé sì mú inú Jèhófà dùn. (Númérì 25:1-13) Góńgó Sátánì ni láti sọ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa di ẹni tí kò tóótun láti wọnú ayé tuntun ti Ọlọ́run. Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí Fíníhásì, a gbọ́dọ̀ kọjú ìjà sí àwọn ìsapá Èṣù láti sọ wá di ẹlẹ́gbin. Yálà a ti gbéyàwó tàbí a jẹ́ àpọ́n, a gbọ́dọ̀ “sá fún àgbèrè.”—Kọ́ríńtì Kíní 6:18.

“Fífi Ìdúróṣinṣin Gbé Ìjótìítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Lárugẹ” ni ọ̀rọ̀ àsọparí ọjọ́ àkọ́kọ́ àpéjọpọ̀ náà. Ọ̀pọ̀ olùtúmọ̀ ń yí àwọn apá kan nínú Ìwé Mímọ́ tàbí kí wọ́n fò ó. Fún àpẹẹrẹ, láti wá ojú àwọn alágbàwí ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin mọ́ra, àwọn olùtúmọ̀ Bíbélì The New Testament and Psalms: An Inclusive Version tọ́ka sí Ọlọ́run, kì í ṣe bíi Bàbá, ṣùgbọ́n bíi Bàbá òun Ìyá, wọ́n sì tọ́ka sí Jésù bí “Ẹ̀dá Ènìyàn” dípò “Ọmọkùnrin ènìyàn.” Ní ìyàtọ̀ pátápátá, Ìtumọ̀ Ayé Titun fi ìṣòtítọ́ rọ̀ mọ́ èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìwé náà, tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó ti ṣèrànwọ́ láti mú ìrònú wa ṣe kedere lórí àwọn ọ̀ràn mélòó kan tí ó jẹ mọ́ Ìwé Mímọ́. Fún àpẹẹrẹ, olùbánisọ̀rọ̀ náà wí pé: “Ìtumọ̀ pípéye inú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Titun ni ó pèsè ìpìlẹ̀ fún àtúntò àwọn ìjọ, nípa yíyan ẹgbẹ́ àwọn alàgbà sípò lọ́nà tí ó túbọ̀ bá àwòṣe ti ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní mu.” A ń fi ìdúróṣinṣin wa sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run hàn nípa kíkà á lójoojúmọ́ àti nípa fífi ìmọ̀ràn rẹ̀ sílò. Olùbánisọ̀rọ̀ náà sọ pẹ̀lú pé: “A ń fi hàn pé a jẹ́ adúróṣinṣin alágbàwí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, nípa fífi ìtara wàásù rẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn, àti nípa fífi ìṣọ́ra lò ó bí a ti ń kọ́ àwọn ẹlòmíràn, kí a má ṣe gbìyànjú láti mú un bá èrò tiwa mu, nípa lílọ́ ohun tí ó sọ lọ́rùn, tàbí nípa fífẹ̀ ẹ́ lójú ju bí ó ṣe yẹ lọ.”

‘Àlàáfíà Ọlọ́run Ta Gbogbo Ìrònú Yọ’

Ẹṣin ọ̀rọ̀ yí, tí a gbé ka Fílípì 4:7, fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ fún ọjọ́ kejì àpéjọpọ̀ náà. Ọ̀pọ̀ ìsọfúnni tí a gbé kalẹ̀ ní í ṣe pẹ̀lú ojú ìwòye tí ó tọ́ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́, ìdílé, ìyàsímímọ́, àti àwọn apá mìíràn nínú ìgbésí ayé ẹni ojoojúmọ́.

Lẹ́yìn ìjíròrò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ti ọjọ́ náà, a gbé àpínsọ ọ̀rọ̀ àsọyé kan kalẹ̀ tí a pe àkòrí rẹ̀ ní, “Àwọn Ońṣẹ́ Tí Ń Mú Ìhìn Rere Àlàáfíà Wá.” Ìhìn iṣẹ́ wa jẹ́ ti àlàáfíà, a sì gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹ pẹ̀lú ẹ̀mí àlàáfíà. (Éfésù 6:15) Olórí ète wa ni láti jèrè ọkàn, kì í ṣe láti borí nínú ìjiyàn. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ àti àwọn ìtẹ̀jáde tí a ń rí gbà láti ọ̀dọ̀ ètò àjọ Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. Kò yẹ kí a jẹ́ kí ẹ̀mí àìbìkítà tàbí ìdágunlá mú wa rẹ̀wẹ̀sì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí a máa bá a nìṣó láti ‘sa gbogbo ipá wa,’ ní níní ìtòlẹ́sẹẹsẹ gbígbámúṣé fún ìdákẹ́kọ̀ọ́, lílọ sí àwọn ìpàdé, àti lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù. (Tímótì Kejì 2:15) Ohun tí a kò ní láti gbójú fò dá ni ṣíṣe ohun rere fún àwọn ẹlòmíràn, ní pàtàkì, àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́. (Gálátíà 6:10) Àmọ́ ṣáá o, sísa gbogbo ipá wa kò túmọ̀ sí fífi iṣẹ́ pin ara wa lẹ́mìí. Jèhófà yóò tẹ́wọ́ gba ohun yòó wù tí ẹnikẹ́ni bá lè ṣe gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ ti mọ àti bí àyíká ipò rẹ̀ ti yọ̀ǹda.

Àwọn ènìyàn Ọlọ́run ń lo àkókò wọn, agbára wọn, àti ohun ìní wọn láti mú ire Ìjọba tẹ̀ síwájú. Ọ̀rọ̀ àsọyé náà, “Ìfúnni Ọlọ́yàyà Nínú Ètò Àjọ Jèhófà,” mú un jáde pé, bí àwọn ẹni bí àgùntàn tí ń pọ̀ sí i ti ń dáhùn pa dà sí ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà, a nílò àfikún ohun èèlò, ilé ìpàdé, àti ilé lílo ti ẹ̀ka. Ọrẹ wa ń mú kí ètò àjọ náà ní ohunkóhun tí ó bá nílò níkàáwọ́ láti ṣàṣeparí iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé. Ìfúnni ọlọ́làwọ́ tún ń bọlá fún Jèhófà, ó sì ń mú ìdùnnú wá fún ẹni tí ń fúnni. Nítorí náà, àwa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni kò gbọ́dọ̀ pa apá pàtàkì nínú ìjọsìn wa yìí tì.—Kọ́ríńtì Kejì 8:1-7.

Ọ̀rọ̀ ìbatisí ni ó mú àkókò ìjókòó òwúrọ̀ wá sí ìparí—ó sábà máa ń jẹ́ kókó pàtàkì ní àwọn àpéjọ ńlá ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ẹ wo bí ó ti dùn mọ́ni tó láti rí àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèyàsímímọ́ tí wọ́n ń tẹ̀ lé ipasẹ̀ Jésù nípa ṣíṣe ìrìbọmi! (Mátíù 3:13-17) Gbogbo àwọn tí wọ́n gbé ìgbésẹ̀ yí ni a ti dá lẹ́kọ̀ọ́ nínú orísun ọgbọ́n gíga jù lọ—Bíbélì. Ní àfikún sí i, wọ́n ti rí ojúlówó ète nínú ìgbésí ayé, a sì ti fi àlàáfíà tí ó ń wá láti inú mímọ̀ pé ohun tí wọ́n ń ṣe tọ̀nà bù kún wọn.—Oníwàásù 12:13.

Ọ̀rọ̀ àsọyé náà, “Jẹ́ Kí Ìfòyemọ̀ Dáàbò Bò Ọ́” fúnni ní ìmọ̀ràn pàtó. Ìfòyemọ̀ ṣe pàtàkì ní ìsopọ̀ pẹ̀lú okòwò. Kò yẹ kí a máa bá ìgbòkègbodò òwò ara ẹni kiri nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba, bẹ́ẹ̀ sì ni kò yẹ kí a máa kó àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ ẹni nífà nítorí èrè owó. (Fi wé Jòhánù 2:15, 16.) A tún nílò ìfòyemọ̀ nígbà tí a bá ń fi owó dókòwò tàbí nígbà tí a bá ń yáwó tàbí tí a bá ń yáni lówó. Olùbánisọ̀rọ̀ náà tẹnu mọ́ ọn pé: “Ìforíṣánpọ́n òwò láàárín àwọn Kristẹni ti yọrí sí ìjákulẹ̀ àti pàápàá sí pípàdánù ipò tẹ̀mí níhà ọ̀dọ̀ àwọn kan tí wọ́n kù gìrì wọnú òwò asọnidọlọ́rọ̀ òjijì, tí ó léwu.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò burú kí àwọn Kristẹni bá ara wọn dòwò pọ̀, ṣùgbọ́n ìṣọ́ra bọ́gbọ́n mu. Nígbà tí a bá sì ṣe àdéhùn okòwò láàárín ẹni méjì, a gbọ́dọ̀ kọ gbogbo ipò àfilélẹ̀ sílẹ̀.

A jíròrò ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọ́run fún ọkùnrin àti obìnrin nínú ọ̀rọ̀ àsọyé náà, “Akọ àti Abo Ni Ó Dá Wọn.” A ti yí ipa iṣẹ́ akọ àti abo po jálẹ̀ ìtàn. Olùbánisọ̀rọ̀ náà wí pé: “Ọ̀pọ̀ ń fi àṣìṣe ronú pé ànímọ́ ìwà ọkùnrin jẹ́ ohun kan náà pẹ̀lú ìjẹgàba oníwà ìkà, ìrorò, tàbí ìfagbára ọkùnrin hàn. . . . Nínú àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ kan, ó jẹ́ ohun tí ó ṣọ̀wọ́n, tí ó tilẹ̀ ń tini lójú pàápàá, fún ọkùnrin láti sunkún ní gbangba tàbí ní ìkọ̀kọ̀ pàápàá. Síbẹ̀, Jòhánù 11:35 ròyìn pé, níbẹ̀ láàárín ọ̀pọ̀ ènìyàn níwájú ibojì Lásárù, ‘Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í da omijé.’” Àwọn obìnrin ńkọ́? A sábà máa ń so jíjẹ́ obìnrin pọ̀ mọ́ ẹwà ti ara. Ṣùgbọ́n olùbánisọ̀rọ̀ náà sọ pé: “Bí obìnrin kan bá rẹwà, ṣùgbọ́n tí kò ní làákàyè, tí ó sì máa ń jiyàn, tí ó máa ń sọ̀rọ̀ àgálámàṣà, tàbí tí ó jẹ́ ọ̀yájú, a ha lè sọ pé ó rẹwà ní tòótọ́ bí, pé ó ní ànímọ́ ìwà obìnrin ní tòótọ́?” (Fi wé Òwe 11:22; 31:26.) Nínú ọ̀rọ̀, ìwà, àti ìmúra wọn, àwọn Kristẹni ọkùnrin àti obìnrin ń làkàkà láti tẹ̀ lé ọ̀pá ìdiwọ̀n Bíbélì. Olùbánisọ̀rọ̀ náà wí pé: “Ó rọrùn láti bọ̀wọ̀ fún ọkùnrin tí ń fi èso tẹ̀mí hàn, ó sì rọrùn láti nífẹ̀ẹ́ obìnrin tí ń ṣe bẹ́ẹ̀.”—Gálátíà 5:22, 23.

Àpínsọ ọ̀rọ̀ àsọyé náà, “Ọlọ́run Àlàáfíà Ń Bìkítà Fún Ọ,” ni ó tẹ̀ lé e. Ọ̀pọ̀ Kristẹni ní hílàhílo ìṣúnná owó. Síbẹ̀síbẹ̀, Jèhófà ṣèlérí pé: “Dájúdájú èmi kì yoo fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí ṣá ọ tì lọ́nàkọnà.” (Hébérù 13:5) Láìka ìnira ọrọ̀ ajé sí, àwọn kan ti fi ìgbọ́kànlé hàn nínú ìlérí yìí nípa wíwọnú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tàbí ti aṣáájú ọ̀nà déédéé. Àwọn mìíràn tí kò lè ṣe aṣáájú ọ̀nà nísinsìnyí ń fi ire Ìjọba sí ipò kíní nípa lílo gbogbo àǹfààní láti jẹ́rìí. (Mátíù 6:33) A gbọ́dọ̀ gbóríyìn fún gbogbo irú ìsapá bẹ́ẹ̀! Ètò àjọ Jèhófà ti pèsè ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìtẹ̀jáde láti ràn wá lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa àti láti ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro wa. Bí a bá fi ìmọrírì hàn fún àwọn ìpèsè tẹ̀mí tí Jèhófà ń pèsè, òun yóò fi àlàáfíà bù kún wa nínú àwọn àkókò onípákáǹleke ọrọ̀ ajé wọ̀nyí.—Orin Dáfídì 29:11.

Ní òpin ọ̀rọ̀ àsọparí ọjọ́ náà, “Máa Lépa Àlàáfíà Ọlọ́run Nínú Ìgbésí Ayé Ìdílé,” inú àwọn tí wọ́n péjọ pọ̀ dùn jọjọ láti rí ìwé tuntun náà, Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, gbà. Olùbánisọ̀rọ̀ náà rọni pé: “Fi aápọn kẹ́kọ̀ọ́ ìwé yìí fúnra rẹ àti gẹ́gẹ́ bí àwùjọ ìdílé. Sakun taratara láti lo àwọn ìmọ̀ràn rẹ̀ tí a gbé karí Bíbélì, ó sì dájú pé ìwọ yóò fi kún àlàáfíà àti ayọ̀ inú ìdílé rẹ.”

‘Ẹ Máa Pa Ìṣọ̀kan Ṣoṣo Mọ́ Nínú Ìdè Asonipọ̀ Ṣọ̀kan Ti Àlàáfíà’

Ní gbígbé e ka Éfésù 4:3, èyí jẹ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ yíyẹ wẹ́kú fún ọjọ́ tí ó kẹ́yìn àpéjọpọ̀ náà. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n wá láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè ayé, ni Ọlọ́run ti kọ́. Nítorí náà, wọ́n nífẹ̀ẹ́ àlàáfíà. Wọ́n ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, wọ́n sì ń sakun “láti máa pa ìṣọ̀kanṣoṣo ẹ̀mí mọ́ nínú ìdè asonipọ̀ṣọ̀kan ti àlàáfíà.”

Ọ̀rọ̀ àsọyé náà, “Dídá Àwọn Ońṣẹ́ Tòótọ́ Mọ̀ Yàtọ̀,” tẹnu mọ́ àlàáfíà tí ó gba inú ètò àjọ Ọlọ́run kan. Àwọn wòlíì èké wà ní Ísírẹ́lì ìgbàanì. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ońṣẹ́ tòótọ́ ti Ọlọ́run—irú àwọn wòlíì bí Aísáyà, Ìsíkẹ́ẹ̀lì, àti Jeremáyà—lọ́nà pípéye sàsọtẹ́lẹ̀ ìṣubú Jerúsálẹ́mù, sáà wíwà nígbèkùn, àti òmìnira àwọn ènìyàn Ọlọ́run nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Irú ipò kan náà ń bẹ lónìí. Àwọn èké ońṣẹ́ pọ̀ lọ jàra ní ilẹ̀ àkóso ìṣèlú àti ti ìsìn èké. Síbẹ̀, Jèhófà ti gbé Àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ dìde láti pòkìkí ète rẹ̀ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ètò ìgbékalẹ̀ nǹkan ìsinsìnyí. Ní pàtàkì, láti 1919, a ti lo àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà láti pòkìkí ìhìn iṣẹ́ Ọlọ́run. Ẹ wo bí wọ́n ti yàtọ̀ tó sí àwọn èké ońṣẹ́ ti Kirisẹ́ńdọ̀mù! Ǹjẹ́ kí a fi aápọn ṣe ipa tiwa nínú iṣẹ́ yìí títí di ìgbà tí Jèhófà bá sọ pé ó tó.

Ọ̀rọ̀ àsọyé náà, “Fetí Sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Kí O Sì Ṣègbọràn Sí I,” tẹnu mọ́ ọn pé Ìwé Mímọ́ ni orísun gíga lọ́lá jù lọ fún ìdarí, ìtùnú, àti ìrètí. (Aísáyà 30:20, 21; Róòmù 15:4) Ayé òde òní túbọ̀ ń gbọ̀jẹ̀gẹ́ sí i. Ju ti ìgbàkígbà rí lọ, a ní láti fetí sí ìmọ̀ràn tí ń wá láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti láti ọ̀dọ̀ ètò àjọ rẹ̀. Jèhófà mọ àìlera wa, ó sì ti la ọ̀nà tí yóò ṣe wá láǹfààní sílẹ̀ kedere nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Mímọ̀ pé Jèhófà ń tì wá lẹ́yìn, ń fún wa ní ìgbọ́kànlé láti tẹ̀ síwájú nínú ohunkóhun tí ó bá béèrè lọ́wọ́ wa.

Èyí múra àwùjọ sílẹ̀ fún àwòkẹ́kọ̀ọ́ onímùúra ti òde òní àti ti ìgbàanì tí ó tẹ̀ lé e. A pe àkòrí rẹ̀ ní, “Èé Ṣe Tí A Fi Ní Láti Bọ̀wọ̀ fún Ìṣètò Ìṣàkóso Ọlọ́run?” Ní lílo àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa Gídéónì gẹ́gẹ́ bí ìpìlẹ̀, ìgbékalẹ̀ yí gbé ìtẹnumọ́ lílágbára karí ẹ̀kọ́ pàtàkì kan—a gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ìtọ́ni Ọlọ́run, kí a má fi èrò tiwa dípò rẹ̀ tàbí kí a gbìyànjú láti kọ ìmọ̀ràn ìṣàkóso Ọlọ́run.

Ọ̀rọ̀ àwíyé fún gbogbo ènìyàn jẹ́ lórí kókó ẹ̀kọ́ náà, “Àlàáfíà Tòótọ́ Nígbẹ̀yìngbẹ́yín!—Láti Orísun Wo?” Àlàáfíà tí Ọlọ́run ṣèlérí ré kọjá ohunkóhun tí ayé yìí lè ronú nípa rẹ̀. Olùbánisọ̀rọ̀ náà wí pé: “Àlàáfíà tòótọ́ túmọ̀ sí àlàáfíà ojoojúmọ́. . . . Àlàáfíà Ọlọ́run túmọ̀ sí ayé kan láìsí àìsàn, ìrora, ìbànújẹ́, àti ikú.” Bíbélì sọ fún wa pé Jèhófà “mú ọ̀tẹ̀ tán dé òpin ayé.” (Orin Dáfídì 46:9) Báwo ni yóò ṣe ṣe èyí? Nípa mímú ẹni tí ń dá ogun sílẹ̀ kúrò, Sátánì Èṣù. (Ìṣípayá 20:1-3) Èyí yóò ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn ọlọ́kàn tútù láti ‘jogún ayé kí wọ́n sì rí inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.’—Orin Dáfídì 37:11.

Lẹ́yìn àkópọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ Ilé Ìṣọ́ fún ọ̀sẹ̀ náà, a gbé ọ̀rọ̀ àsọparí àpéjọpọ̀ náà kalẹ̀. Ẹṣin ọ̀rọ̀ náà ni, “Títẹ̀ Síwájú Gẹ́gẹ́ Bí Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọ́run,” àwíyé arùmọ̀lárasókè yí tẹnu mọ́ ọn pé iṣẹ́ ìwàásù wa jẹ́ aláìláfiwé, ó sì jẹ́ kánjúkánjú. Ìsinsìnyí kì í ṣe àkókò láti kẹ̀tẹ̀ǹfẹ̀, láti fi nǹkan falẹ̀, tàbí láti pa dà sí àwọn èrò òdì. A ní ohun tí a nílò—ìhìn iṣẹ́ Ọlọ́run, ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, àti ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìpèsè tí ń wá láti ọ̀dọ̀ ètò àjọ rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ tí Ọlọ́run ń ṣàkóso. Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà, ǹjẹ́ kí a máa tẹ̀ síwájú gẹ́gẹ́ bí ońṣẹ́ àlàáfíà Ọlọ́run!

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ìpèsè Onífẹ̀ẹ́ fún Ìdílé

Inú àwọn tí wọ́n pésẹ̀ sí ọjọ́ kejì Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọ́run” dùn láti rí ìtẹ̀jáde tuntun náà tí a pè ní Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé gbà. Ìwé yìí kún fún ìsọfúnni tí a gbé karí Ìwé Mímọ́ tí yóò ṣe gbogbo ìdílé tí ó bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run láǹfààní.

Alàgbà kan láti Connecticut, U.S.A., sọ pé: “Ní June 15, a rí ìwé Ayọ̀ Ìdílé wa gbà. Nígbà tí yóò fi di June 16, mo ti kà á dé ìlàjì. Ní ọjọ́ kẹtàdínlógún, a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wa àkọ́kọ́ nínú rẹ̀, a sì fún wa níṣìírí gidigidi! Ní ọjọ́ kan náà yẹn, mo parí kíka ìwé náà. Kò sí iyè méjì pé ìwé dáradára yìí yóò ṣeyebíye fún gbogbo àwọn tí wọ́n bá wá àyè láti kà á. Àìfọ̀rọ̀ bọpobọyọ̀ ìwé náà àti ìsọfúnni rẹ̀ tí ó bá ìgbà mu túbọ̀ jẹ́ ẹ̀rí pé ‘olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú’ ń pèsè ‘oúnjẹ ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu,’ ó sì mọ àìní wa ní àwọn àkókò tí ń dánni wò wọ̀nyí dunjú.”​—⁠Mátíù 24:​45-⁠47.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Tọmọdétàgbà fẹ́ mọ ohun tí Ọlọ́run ń béèrè

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́