Ṣíṣiṣẹ́sìn Gẹ́gẹ́ Bí Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọ́run
“Ẹsẹ̀ ẹni tí ó . . . ń kéde àlàáfíà ti dára tó lórí àwọn òkè.”—AÍSÁYÀ 52:7, NW.
1, 2. (a) Gẹ́gẹ́ bí Aísáyà 52:7 ti sọ tẹ́lẹ̀, ìhìn rere wo ni a óò kéde rẹ̀? (b) Kí ni àwọn ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ Aísáyà túmọ̀ sí nínú ọ̀ràn Ísírẹ́lì ìgbàanì?
ÌHÌN rere ń bẹ tí a ní láti polongo! Ó jẹ́ ìhìn àlàáfíà—ojúlówó àlàáfíà. Ó jẹ́ ìhìn iṣẹ́ ìgbàlà tí ó ní í ṣe pẹ̀lú Ìjọba Ọlọ́run. Ní ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn, wòlíì Aísáyà kọ̀wé nípa rẹ̀, a sì pa ohun tí ó kọ sílẹ̀ mọ́ fún wa nínú Aísáyà 52:7, níbi tí a ti kà pé: “Ẹsẹ̀ ẹni tí ó mú ìhìn rere wá ti dára tó lórí àwọn òkè, tí ń kéde àlàáfíà; tí ń mú ìhìn rere ohun rere wá, tí ń kéde ìgbàlà; tí ó wí fún Síónì pé, Ọlọ́run rẹ ń jọba!”
2 Jèhófà mí sí wòlíì rẹ̀ Aísáyà láti kọ ìhìn iṣẹ́ yẹn fún àǹfààní Ísírẹ́lì ìgbàanì àti fún àǹfààní wa lónìí. Kí ni ó túmọ̀ sí? Ní àkókò tí Aísáyà kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn, ó ṣeé ṣe kí àwọn ará Asíríà ti kó ìjọba àríwá Ísírẹ́lì lọ sí ìgbèkùn. Lẹ́yìn náà, a óò kó àwọn olùgbé Júdà, ìjọba gúúsù, nígbèkùn lọ sí Bábílónì. Àwọn ọjọ́ ìrora ọkàn àti ìrọ́kẹ̀kẹ̀ nìwọ̀nyẹn ní orílẹ̀-èdè náà, nítorí pé, àwọn ènìyàn náà kò ṣègbọràn sí Jèhófà, wọn kò sì tipa bẹ́ẹ̀ wà ní àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti sọ fún wọn, ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn ń fa ìpínyà láàárín àwọn àti Ọlọ́run wọn. (Aísáyà 42:24; 59:2-4) Ṣùgbọ́n nípasẹ̀ Aísáyà, Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ pé, nígbà tí àkókò náà bá tó, a óò ṣí àwọn ẹnubodè Bábílónì sílẹ̀ gbayawu. Àwọn ènìyàn Ọlọ́run yóò lómìnira láti pa dà sí ilẹ̀ wọn, láti pa dà lọ tún tẹ́ńpìlì Jèhófà kọ́. A óò mú Síónì pa dà bọ̀ sípò, a óò sì tún máa bá ìjọsìn Ọlọ́run tòótọ́ lọ ní pẹrẹu ní Jerúsálẹ́mù.—Aísáyà 44:28; 52:1, 2.
3. Báwo ni ìlérí ìmúpadàbọ̀sípò fún Ísírẹ́lì tún ṣe jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ àlàáfíà?
3 Ìlérí ìdáǹdè yí tún jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ àlàáfíà. Dídá tí a óò dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa dà sí ilẹ̀ náà tí Jèhófà ti fún wọn jẹ́ ẹ̀rí àánú Ọlọ́run àti ìrònúpìwàdà wọn. Yóò fi hàn pé wọ́n wà ní àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run.—Aísáyà 14:1; 48:17, 18.
“Ọlọ́run Rẹ Ń Jọba!”
4. (a) Lọ́nà wo ni a fi lè sọ ní ọdún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa pé ‘Jèhófà ti di Ọba’? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe fọgbọ́n darí ọ̀ràn nítorí àwọn ènìyàn rẹ̀ ní àwọn ọdún tí ó tẹ̀ lé e?
4 Nígbà tí Jèhófà ṣe ìdáǹdè yí ní ọdún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, a lè kéde fún Síónì lọ́nà tí ó bá a mu wẹ́kú pé: “Ọlọ́run rẹ ń jọba!” Lóòótọ́, Jèhófà ni “Ọba ayérayé.” (Ìṣípayá 15:3) Ṣùgbọ́n ìdáǹdè àwọn ènìyàn rẹ̀ yìí jẹ́ ìfihàn ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ lákọ̀tun. Ó fi hàn lọ́nà tí ń múni ta gìrì, bí agbára rẹ̀ ṣe ga lọ́lá fíìfíì ju ti ilẹ̀ ọba ẹ̀dá ènìyàn tí ó lágbára jù lọ títí di àkókò yẹn. (Jeremáyà 51:56, 57) Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí ìṣiṣẹ́ ẹ̀mí Jèhófà, a ké àwọn ọ̀tẹ̀ míràn tí a ṣe sí àwọn ènìyàn rẹ̀ nígbèrí. (Ẹ́sítérì 9:24, 25) Léraléra, Jèhófà dá sí i ní onírúurú ọ̀nà láti mú kí àwọn ọba Mídíà òun Páṣíà fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú mímú ìfẹ́ inú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ṣẹ. (Sekaráyà 4:6) A ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àgbàyanu tí ó ṣẹlẹ̀ ní àwọn ọjọ́ wọnnì fún wa nínú àwọn ìwé Bíbélì ti Ẹ́sírà, Nehemáyà, Ẹ́sítérì, Hágáì, àti Sekaráyà. Ẹ sì wo bí ó ṣe jẹ́ afúngbàgbọ́lókun tó láti ṣàtúnyẹ̀wò wọn!
5. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì wo ni a tọ́ka sí nínú Aísáyà 52:13–53:12?
5 Àmọ́, ìbẹ̀rẹ̀ lásán ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọdún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa àti lẹ́yìn náà jẹ́. Kété lẹ́yìn àsọtẹ́lẹ̀ ìmúpadàbọ̀sípò nínú orí 52, Aísáyà kọ̀wé nípa wíwáa Mèsáyà. (Aísáyà 52:13–53:12) Nípasẹ̀ Mèsáyà náà, ẹni tí í ṣe Jésù Kristi, Jèhófà yóò pèsè ìhìn iṣẹ́ ìdáǹdè àti àlàáfíà tí ó tún ní ìjẹ́pàtàkì títóbi ju ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọdún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa lọ.
Ońṣẹ́ Àlàáfíà Títóbi Lọ́lá Jù Lọ fún Jèhófà
6. Ta ni ońṣẹ́ àlàáfíà títóbi lọ́lá jù lọ fún Jèhófà, iṣẹ́ àṣẹ wo ni ó sì fi hàn pé òun mú ṣẹ?
6 Jésù Kristi ni ońṣẹ́ àlàáfíà títóbi lọ́lá jù lọ fún Jèhófà. Òun ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Agbọ̀rọ̀sọ Jèhófà fúnra rẹ̀. (Jòhánù 1:14) Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, nígbà kan, lẹ́yìn tí a batisí rẹ̀ ní Odò Jọ́dánì, Jésù wọnú sínágọ́gù lọ ní Násárétì, ó dìde dúró, ó sì ka iṣẹ́ àṣẹ rẹ̀ sókè láti inú ìwé Aísáyà orí 61. Iṣẹ́ àṣẹ yẹn mú kí ó ṣe kedere pé, ohun tí a rán an láti wàásù ní “ìtúsílẹ̀” àti “ìjèrèpadà” nínú, àti àǹfààní rírí ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà. Ṣùgbọ́n, Jésù ṣe ju wíwulẹ̀ pòkìkí ìhìn iṣẹ́ àlàáfíà lọ. Ọlọ́run tún rán an láti pèsè ìpìlẹ̀ fún àlàáfíà pípẹ́ títí.—Lúùkù 4:16-21.
7. Kí ni ó jẹ́ ìyọrísí àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run tí a mú ṣeé ṣe nípasẹ̀ Jésù Kristi?
7 Ní àkókò ìbí Jésù, àwọn áńgẹ́lì fara han àwọn olùṣọ́ àgùntàn nítòsí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, wọ́n ń yin Ọlọ́run, wọ́n sì ń sọ pé: “Ògo fún Ọlọ́run ní àwọn ibi gíga lókè, àti lórí ilẹ̀ ayé àlàáfíà láàárín àwọn ènìyàn ìfẹ́ rere.” (Lúùkù 2:8, 13, 14) Bẹ́ẹ̀ ni, àlàáfíà yóò wà fún àwọn tí Ọlọ́run fi ìfẹ́ rere hàn sí nítorí pé wọ́n lo ìgbàgbọ́ nínú ìpèsè náà tí òun tipasẹ̀ Ọmọkùnrin rẹ̀ ṣe. Kí ni ìyẹn yóò túmọ̀ sí? Yóò túmọ̀ sí pé, bí a tilẹ̀ bí àwọn ẹ̀dá ènìyàn sínú ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n lè ní ìdúró mímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, ipò ìbátan tí ó ṣètẹ́wọ́gbà pẹ̀lú rẹ̀. (Róòmù 5:1) Wọ́n lè gbádùn ìparọ́rọ́ ti inú lọ́hùn-ún, àlàáfíà, èyí tí kò ṣeé ṣe ní ọ̀nà èyíkéyìí mìíràn. Nígbà tí ó bá tó àkókò lójú Ọlọ́run, a óò rí òmìnira gbà kúrò lọ́wọ́ gbogbo ipa ìdarí ẹ̀ṣẹ̀ tí a jogún láti ọ̀dọ̀ Ádámù, títí kan òmìnira kúrò lọ́wọ́ àìsàn àti ikú. Àwọn ènìyàn kì yóò fọ́jú, yadi tàbí yarọ mọ́. A óò mú àìlera tí ń wóni mọ́lẹ̀ àti ìṣiṣẹ́gbòdì ọpọlọ tí ń fa ìdààmú ọkàn kúrò pátápátá. Yóò ṣeé ṣe láti gbádùn ìwàláàyè nínú ìjẹ́pípé títí láé.—Aísáyà 33:24; Mátíù 9:35; Jòhánù 3:16.
8. Àwọn wo ni a nawọ́ àlàáfíà Ọlọ́run sí?
8 Àwọn wo ni a nawọ́ àlàáfíà yẹn sí? A nawọ́ rẹ̀ sí gbogbo àwọn tí wọ́n lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé ‘Ọlọ́run rí i pé ó dára láti tipasẹ̀ Kristi mú gbogbo àwọn ohun mìíràn pa dà rẹ́ pẹ̀lú ara rẹ̀ nípa mímú àlàáfíà wá nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ tí Jésù ta sílẹ̀ lórí òpó igi oró.’ Àpọ́sítélì náà fi kún un pé, ìmúpadàrẹ́ yìí yóò ní “àwọn ohun tí ń bẹ ní àwọn ọ̀run” nínú—ìyẹn ni, àwọn tí yóò jẹ́ àjùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi ní ọ̀run. Yóò tún ní “àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé” nínú—ìyẹn ni, àwọn tí a óò fi àǹfààní wíwà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé ṣojú rere sí, nígbà tí a bá mú un wá sí ipò Párádísè kíkún rẹ́rẹ́. (Kólósè 1:19, 20) Nítorí mímú ara wọn jàǹfààní nínú ìtóye ẹbọ Jésù àti nítorí ṣíṣègbọràn sí Ọlọ́run láti inú ọkàn àyà wọn, gbogbo àwọn wọ̀nyí lè gbádùn ìbárẹ́ onífẹ̀ẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run.—Fi wé Jákọ́bù 2:22, 23.
9. (a) Ipò ìbátan mìíràn wo ni àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run ń nípa lé lórí? (b) Pẹ̀lú èrò àlàáfíà pípẹ́ títí níbi gbogbo, ọlá àṣẹ wo ni Jèhófà fi lé Ọmọkùnrin rẹ̀ lọ́wọ́?
9 Ẹ wo bí irú àlàáfíà yẹn pẹ̀lú Ọlọ́run ti ṣe kókó tó! Bí kò bá sí àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run, kò lè sí àlàáfíà pípẹ́ títí tàbí tí ó nítumọ̀ nínú ipò ìbátan èyíkéyìí mìíràn. Àlàáfíà pẹ̀lú Jèhófà ni ìpìlẹ̀ àlàáfíà tòótọ́ lórí ilẹ̀ ayé. (Aísáyà 57:19-21) Lọ́nà yíyẹ, Jésù Kristi ni Ọmọ Aládé Àlàáfíà. (Aísáyà 9:6) Jèhófà ti fún ẹni yìí tí àwọn ẹ̀dá ènìyàn lè tipasẹ̀ rẹ̀ pa dà rẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run ní ọlá àṣẹ ìṣàkóso. (Dáníẹ́lì 7:13, 14) Nípa ìyọrísí ìṣàkóso aládé Jésù lórí aráyé, Jèhófà ṣèlérí pé: “Àlàáfíà kì yóò ní ìpẹ̀kun.”—Aísáyà 9:7; Orin Dáfídì 72:7.
10. Báwo ni Jésù ṣe fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ nínú kíkéde ìhìn iṣẹ́ àlàáfíà Ọlọ́run?
10 Gbogbo ìran aráyé ni ó nílò ìhìn iṣẹ́ àlàáfíà Ọlọ́run. Jésù fúnra rẹ̀ fi àpẹẹrẹ jíjẹ́ onítara nínú wíwàásù rẹ̀ lélẹ̀. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ ní àgbègbè tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù, lórí òkè, lójú ọ̀nà, nígbà tí ó ń bá obìnrin ará Samáríà kan sọ̀rọ̀ létí kànga, àti nínú ilé àwọn ènìyàn. Níbikíbi tí àwọn ènìyàn bá wà, Jésù lo àǹfààní láti wàásù nípa àlàáfíà àti nípa Ìjọba Ọlọ́run.—Mátíù 4:18, 19; 5:1, 2; 9:9; 26:55; Máàkù 6:34; Lúùkù 19:1-10; Jòhánù 4:5-26.
A Kọ́ Wọn Láti Tẹ̀ Lé Ipasẹ̀ Kristi
11. Iṣẹ́ wo ni Jésù dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ fún?
11 Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti wàásù ìhìn iṣẹ́ àlàáfíà ti Ọlọ́run. Gan-an gẹ́gẹ́ bí Jésù ti jẹ́ “ẹlẹ́rìí aṣeégbíyèlé àti olóòótọ́” fún Jèhófà, wọ́n mọ̀ pé àwọn pẹ̀lú ní ẹrù iṣẹ́ láti jẹ́rìí. (Ìṣípayá 3:14; Aísáyà 43:10-12) Wọ́n wo Kristi gẹ́gẹ́ bí Aṣáájú wọn.
12. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi ìjẹ́pàtàkì ìgbòkègbodò ìwàásù hàn?
12 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ronú lórí ìjẹ́pàtàkì ìgbòkègbodò ìwàásù, ní sísọ pé: “Ìwé Mímọ́ wí pé: ‘Kò sí ẹnì kankan tí ń gbé ìgbàgbọ́ rẹ̀ lé e tí a óò já kulẹ̀.’” Ìyẹn ni pé, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó bá lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bí Olórí Aṣojú Jèhófà fún ìgbàlà tí a óò já kulẹ̀. Ipò àtilẹ̀wá ti ẹ̀yà ìran ẹnì kan kì í sì í ṣe kókó abájọ tí ó lè mú kí ó ṣàìtóótun, nítorí Pọ́ọ̀lù fi kún un pé: “Kò sí ààlà ìyàtọ̀ láàárín Júù àti Gíríìkì, nítorí Olúwa kan náà ní ń bẹ lórí gbogbo wọn, ẹni tí ó jẹ́ ọlọ́rọ̀ sí gbogbo àwọn wọnnì tí ń ké pè é. Nítorí ‘olúkúlùkù ẹni tí ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a óò gbà là.’” (Róòmù 10:11-13) Ṣùgbọ́n, báwo ni àwọn ènìyàn yóò ṣe mọ̀ nípa àǹfààní yẹn?
13. Kí ni a nílò bí àwọn ènìyàn yóò bá gbọ́ ìhìn rere náà, báwo sì ni àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ṣe dáhùn pa dà sí àìní yẹn?
13 Pọ́ọ̀lù kojú àìní yẹn nípa bíbéèrè àwọn ìbéèrè tí ìránṣẹ́ Jèhófà kọ̀ọ̀kan yóò ronú lé lórí. Àpọ́sítélì náà béèrè pé: “Báwo ni wọn yóò ṣe ké pe ẹni tí wọn kò lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀? Báwo, ẹ̀wẹ̀, ni wọn yóò ṣe lo ìgbàgbọ́ nínú ẹni tí wọn kò gbọ́ nípa rẹ̀? Báwo, ẹ̀wẹ̀, ni wọn yóò ṣe gbọ́ láìsí ẹnì kan láti wàásù? Báwo, ẹ̀wẹ̀, ni wọn yóò ṣe wàásù láìjẹ́ pé a ti rán wọn jáde?” (Róòmù 10:14, 15) Àkọsílẹ̀ ìsìn Kristẹni ìjímìjí jẹ́ ẹ̀rí kedere pé, tọkùnrin tobìnrin, tọmọdétàgbà, dáhùn pa dà sí àpẹẹrẹ tí Kristi àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ fi lélẹ̀. Wọ́n di onítara olùpòkìkí ìhìn rere náà. Ní fífarawé Jésù, wọ́n wàásù fún àwọn ènìyàn níbikíbi tí wọ́n bá ti lè rí wọn. Pẹ̀lú ìfẹ́ ọkàn láti má ṣe fo ẹnikẹ́ni, wọ́n ń bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà lọ ní gbangba àti láti ilé dé ilé.—Ìṣe 17:17; 20:20.
14. Báwo ni ó ṣe já sí òtítọ́ pé “ẹsẹ̀” àwọn tí ń polongo ìhìn rere náà dára “rèǹtè-rente”?
14 Àmọ́ ṣáá o, kì í ṣe ènìyàn gbogbo ni ó gba àwọn Kristẹni tí ń wàásù tọwọ́tẹsẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, àyọlò Pọ́ọ̀lù láti inú Aísáyà 52:7 já sí òtítọ́. Lẹ́yìn tí ó béèrè ìbéèrè náà pé, ‘Báwo ni wọn yóò ṣe wàásù láìjẹ́ pé a ti rán wọn jáde?’ ó fi kún un pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Ẹsẹ̀ àwọn wọnnì tí ń polongo ìhìn rere àwọn ohun rere ti dára rèǹtè-rente tó!’” Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wa ni kò mọ̀ pé ẹsẹ̀ wa dára rèǹtè-rente, tàbí pé ó rẹwà. Nítorí náà, kí ni èyí túmọ̀ sí? Ní ti gidi, ẹsẹ̀ ni ènìyàn fi ń rìn káàkiri bí ó ti ń wàásù fún àwọn ẹlòmíràn. Láìsí tàbí-tàbí, irú ẹsẹ̀ bẹ́ẹ̀ dúró fún ẹni náà gan-an. Ó sì lè dá wa lójú pé, lójú ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n gbọ́ ìhìn rere náà lẹ́nu àwọn àpọ́sítélì àti lẹ́nu àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn Kristẹni ìjímìjí wọ̀nyí rẹwà gidigidi ní tòótọ́. (Ìṣe 16:13-15) Ju ìyẹn lọ, wọ́n ṣeyebíye lójú Ọlọ́run.
15, 16. (a) Báwo ni àwọn Kristẹni ìjímìjí ṣe fi hàn pé ní tòótọ́ ni àwọn jẹ́ ońṣẹ́ àlàáfíà? (b) Kí ni ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lọ lọ́nà kan náà tí àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní gbà ṣe é?
15 Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ní ìhìn iṣẹ́ àlàáfíà, wọ́n sì gbé e kalẹ̀ lọ́nà àlàáfíà. Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ìtọ́ni wọ̀nyí pé: “Ní ibi yòó wù tí ẹ bá ti wọ inú ilé kan ẹ kọ́kọ́ wí pé, ‘Àlàáfíà fún ilé yìí o.’ Bí ọ̀rẹ́ àlàáfíà bá sì wà níbẹ̀, àlàáfíà yín yóò bà lé e. Ṣùgbọ́n bí kò bá sí, yóò pa dà sọ́dọ̀ yín.” (Lúùkù 10:5, 6) Sha·lohmʹ, tàbí “àlàáfíà,” jẹ́ ọ̀nà tí àwọn Júù máa ń gbà kíni. Ṣùgbọ́n, ìtọ́ni Jésù ní ohun púpọ̀ nínú ju èyí lọ. Gẹ́gẹ́ bí “ikọ̀ tí ń dípò fún Kristi,” àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ẹni àmì òróró rọ àwọn ènìyàn pé: “Ẹ pa dà bá Ọlọ́run rẹ́.” (Kọ́ríńtì Kejì 5:20) Ní ìbámu pẹ̀lú ìtọ́ni Jésù, wọ́n bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run àti ohun tí ó lè túmọ̀ sí fún wọn gẹ́gẹ́ bí ẹnì kọ̀ọ̀kan. Àwọn tí wọ́n fetí sílẹ̀, rí ìbùkún gbà; àwọn tí wọ́n kọ ìhìn iṣẹ́ náà pàdánù.
16 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn lọ lọ́nà kan náà lónìí. Ìhìn rere tí wọ́n ń mú tọ àwọn ènìyàn lọ kì í ṣe tiwọn; Ẹni tí ó rán wọn ni ó ni ín. Iṣẹ́ tí a fi lé wọn lọ́wọ́ ni láti jẹ́ ẹ. Bí àwọn ènìyàn bá tẹ́wọ́ gbà á, wọ́n fi hàn pé àwọn ń fẹ́ àwọn ìbùkún àgbàyanu. Bí wọ́n bá kọ̀ ọ́, wọ́n ń kọ àlàáfíà pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọkùnrin rẹ̀, Jésù Kristi.—Lúùkù 10:16.
Jíjẹ́ Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà Nínú Ayé Onírúkèrúdò
17. Kódà nígbà tí àwọn ẹlẹ́ẹ̀kẹ́ èébú bá dojú kọ wá, báwo ni ó ṣe yẹ kí a hùwà pa dà, èé sì ti ṣe?
17 Ohun yòó wù tí ìhùwàpadà àwọn ènìyàn lè jẹ́, ó ṣe pàtàkì fún àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà láti fi í sọ́kàn pé, ońṣẹ́ àlàáfíà Ọlọ́run ni àwọn jẹ́. Àwọn ènìyàn ayé lè kó wọnú àríyànjiyàn gbígbóná janjan, kí wọ́n sì fi ìbínú hàn nípa sísọ àwọn ọ̀rọ̀ burúkú tàbí nípa rírọ̀jò èébú sórí àwọn tí wọ́n mú wọn bínú. Ó ṣeé ṣe kí díẹ̀ nínú wa ti ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà kan rí. Ṣùgbọ́n, bí a bá ti gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, tí a kò sì jẹ́ apá kan ayé mọ́ nísinsìnyí, a kò ní fara wé àwọn ọ̀nà wọn. (Éfésù 4:23, 24, 31; Jákọ́bù 1:19, 20) Láìka bí àwọn ẹlòmíràn ṣe hùwà sí, a óò fi ìmọ̀ràn náà sílò pé: “Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.”—Róòmù 12:18.
18. Báwo ni ó ṣe yẹ kí a hùwà pa dà bí ọ̀gá kan lẹ́nu iṣẹ́ ọba bá le koko mọ́ wa, èé sì ti ṣe?
18 Iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa nígbà míràn lè mú wa dé iwájú àwọn lọ́gàá-lọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ọba. Ní lílo ọlá àṣẹ wọn, wọ́n lè ‘fi dandan béèrè pé’ kí a ṣàlàyé ìdí tí a fi ń ṣe àwọn ohun kan tàbí ìdí tí a fi ń fà sẹ́yìn kúrò nínú lílọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò kan pàtó. Wọ́n lè fẹ́ láti mọ ìdí tí a fi ń wàásù ìhìn iṣẹ́ náà tí a ń ṣe—èyí tí ń tú ìsìn èké fó, tí ó sì ń sọ nípa òpin ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Ọ̀wọ̀ tí a ní fún àpẹẹrẹ tí Kristi fi lélẹ̀ yóò sún wa láti fi ìwà tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ hàn. (Pétérù Kíní 2:23; 3:15) Lọ́pọ̀ ìgbà, àwùjọ àlùfáà tàbí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ àwọn ọ̀gá wọn alára ni ó ń fúngun mọ́ irú àwọn lọ́gàá-lọ́gàá bẹ́ẹ̀. Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ lè ṣèrànwọ́ láti jẹ́ kí wọ́n lóye pé ìgbòkègbodò wa kì í ṣe ewu fún wọn tàbí fún àlàáfíà àwùjọ. Irú èsì bẹ́ẹ̀ ń mú kí ẹ̀mí ọ̀wọ̀, ìfọwọ́sowọ́pọ̀, àti àlàáfíà wà nínú àwọn tí wọ́n bá tẹ́wọ́ gbà á.—Títù 3:1, 2.
19. Àwọn ìgbòkègbodò wo ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò lọ́wọ́ nínú rẹ̀ rí?
19 A mọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn tí kì í lọ́wọ́ nínú gbọ́nmisi-omi-ò-to ti ayé. Wọn kì í lọ́wọ́ nínú ìforígbárí ayé nítorí ẹ̀yà ìran, ìsìn, tàbí ìṣèlú. (Jòhánù 17:14) Nítorí pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run darí wa láti “wà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga,” a kì yóò tilẹ̀ ronú kíkópa nínú dídá rúgúdù sílẹ̀, láti fẹ̀hónú hàn sí àwọn ìlànà ìjọba. (Róòmù 13:1) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ èyíkéyìí rí tí ó fẹ́ dojú ìjọba bolẹ̀. Lójú ìwòye ọ̀pá ìdiwọ̀n tí Jèhófà gbé kalẹ̀ fún àwọn Kristẹni ìránṣẹ́ rẹ̀, yóò jẹ́ ohun tí kò bọ́gbọ́n mu rárá láti lọ́wọ́ nínú ìtàjẹ̀sílẹ̀ tàbí ìwà ipá èyíkéyìí! Kì í ṣe pé àwọn Kristẹni tòótọ́ wulẹ̀ ń sọ̀rọ̀ nípa àlàáfíà nìkan ni; wọ́n ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí wọ́n ń wàásù rẹ̀.
20. Ní ti àlàáfíà, irú àkọsílẹ̀ wo ni Bábílónì Ńlá ti ní?
20 Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí àwọn Kristẹni tòótọ́, àwọn aṣojú ètò ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù kò tí ì fi hàn pé àwọn jẹ́ ońṣẹ́ àlàáfíà. Àwọn ìsìn Bábílónì Ńlá—àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù àti àwọn tí kì í ṣe ti Kristẹni—ti fàyè gba ogun, wọ́n ti kọ́wọ́ tì í, wọ́n sì ti mú ipò iwájú nínú ogun àwọn orílẹ̀-èdè. Wọ́n tún ti súnná sí inúnibíni tí a ṣe sí àwọn olùṣòtítọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà àti pípa wọ́n pàápàá. Nítorí náà, nípa Bábílónì Ńlá, Ìṣípayá 18:24 polongo pé: “Nínú rẹ̀ ni a ti rí ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì àti ti àwọn ẹni mímọ́ àti ti gbogbo àwọn wọnnì tí a ti fikú pa lórí ilẹ̀ ayé.”
21. Báwo ni ọ̀pọ̀ olóòótọ́ ọkàn ti ṣe hùwà pa dà nígbà tí wọ́n rí ìyàtọ̀ tí ó wà nínú ìwà àwọn ènìyàn Jèhófà àti ti àwọn onísìn èké?
21 Láìdà bí àwọn ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù àti bí ìyókù Bábílónì Ńlá, ìsìn tòótọ́ jẹ́ ipa rere, tí ń múni ṣọ̀kan. Jésù Kristi sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tòótọ́ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:35) Ìyẹ́n jẹ́ ìfẹ́ kan tí ó ré kọjá ààlà orílẹ̀-èdè, ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, ọrọ̀ ajé, àti ẹ̀yà ìran tí ó pín ìyókù ìran ènìyàn sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ nísinsìnyí. Ní ṣíṣàkíyèsí èyí, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn káàkiri ayé ń sọ fún àwọn ẹni àmì òróró ìránṣẹ́ Jèhófà pé: “A óò bá ọ lọ, nítorí àwa ti gbọ́ pé, Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ.”—Sekaráyà 8:23.
22. Ojú wo ni a fi ń wo iṣẹ́ ìjẹ́rìí tí ó yẹ kí a ṣe?
22 Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Jèhófà, inú wá dùn púpọ̀ fún ohun tí a ti ṣàṣeparí, ṣùgbọ́n iṣẹ́ náà kò tí ì tán. Lẹ́yìn gbígbin irúgbìn àti rírolẹ̀, àgbẹ̀ kan kì í fi iṣẹ́ sílẹ̀ títí di ìgbà ìkórè. Yóò máa ṣiṣẹ́ nígbà gbogbo, ní pàtàkì nígbà tí a bá ti wọnú ìgbà ìkórè. Ìgbà ìkórè ń béèrè fún ìsapá tí kò dáwọ́ dúró, tí ó sì jẹ́ aláápọn. Nísinsìnyí, a ti ń ṣàkójọ ìkórè ńláǹlà ti àwọn olùjọsìn Ọlọ́run tòótọ́ náà ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Àkókò ìdùnnú ni èyí jẹ́. (Aísáyà 9:3) Lóòótọ́, a ń dojú kọ àtakò àti ìdágunlá. Lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, a lè máa sakun láti kojú àìsàn líle koko, ipò ìdílé tí ó ṣòro, tàbí ìnira ọrọ̀ ajé. Ṣùgbọ́n ìfẹ́ fún Jèhófà ń sún wa láti fara dà á. Ìhìn iṣẹ́ tí Ọlọ́run ti gbé lé wa lọ́wọ́ jẹ́ ohun kan tí àwọn ènìyàn ní láti gbọ́. Ó jẹ́ ìhìn iṣẹ́ àlàáfíà. Ní tòótọ́, ó jẹ́ ìhìn iṣẹ́ tí Jésù fúnra rẹ̀ wàásù—ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.
Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?
◻ Ìmúṣẹ wo ni Aísáyà 52:7 ní lórí Ísírẹ́lì ìgbàanì?
◻ Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun ni ońṣẹ́ àlàáfíà títóbi lọ́lá jù lọ?
◻ Báwo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe so Aísáyà 52:7 pọ̀ mọ́ iṣẹ́ tí àwọn Kristẹni ń nípìn-ín nínú rẹ̀?
◻ Kí ni jíjẹ́ ońṣẹ́ àlàáfíà ní nínú ní ọjọ́ wa?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Gẹ́gẹ́ bíi Jésù, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ ońṣẹ́ àlàáfíà Ọlọ́run
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń bá a nìṣó láti jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà láìka bí àwọn ènìyàn ṣe lè dáhùn pa dà sí ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà sí