ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 3/1 ojú ìwé 15-19
  • Ẹ Jẹ Ki “Alaafia Ọlọrun” Maa Daabobo Ọkan-aya Yin

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Jẹ Ki “Alaafia Ọlọrun” Maa Daabobo Ọkan-aya Yin
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Alaafia Pẹlu Ọlọrun —Bi A Ti Padanu Rẹ̀
  • Wiwa ni Alaafia ninu Aye Alainifẹẹ
  • Ipilẹ Didara Ju Kan fun Alaafia
  • Majẹmu Kan ti Alaafia
  • Àlàáfíà Tòótọ́—Láti Orísun Wo?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ẹ Wa Alaafia Ki Ẹ Si Maa Lepa rẹ̀”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Àlàáfíà​—Báwo Lo Ṣe Lè Ní In?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 3/1 ojú ìwé 15-19

Ẹ Jẹ Ki “Alaafia Ọlọrun” Maa Daabobo Ọkan-aya Yin

“Njẹ ki Jehofa gbe oju rẹ̀ si iha ọdọ yin ki o sì rán alaafia si yin.”—NUMERI 6:26, NW.

1. Ni kete ṣaaju iku rẹ̀, ki ni Pọọlu kọ si Timoti, ti o nṣipaya ki ni?

NI ỌDUN 65 C.E., apọsteli Pọọlu jẹ ẹlẹwọn ni Roomu. Bi o tilẹ jẹ pe laipẹ oun yoo ku iku oniwa-ipa ni ọwọ olufiya iku jẹni ara Roomu kan, Pọọlu wà ni alaafia. Eyi ṣe kedere lati inu awọn ọ̀rọ̀ ti o kọ si ọ̀rẹ́ rẹ kekere Timoti, nigba ti oun wipe: “Emi ti ja ija rere, emi ti pari ere-ije mi, emi ti pa igbagbọ mọ: lati isinsinyi lọ a fi adé ododo lelẹ fun mi, ti Oluwa, onidaajọ ododo, yoo fi fun mi ni ọjọ naa.”—2 Timoti 4:7, 8.

2. Ki ni o ti ṣọ́ ọkan-aya Pọọlu jalẹ igbesi aye rẹ ti o kun fun awọn iṣẹlẹ manigbagbe, titi di igba iku rẹ̀?

2 Bawo ni Pọọlu ṣe le parọrọ tobẹẹ ni oju iku? O jẹ nitori pe “alaafia Ọlọrun, ti o ju imọran gbogbo lọ” nṣọ ọkan-aya rẹ̀. (Filipi 4:7) Alaafia yii kannaa ti daabobo o la gbogbo awọn ọdun ti o kun fun akitiyan lati ìgbà iyilọkanpada rẹ̀ ibẹrẹ si isin-Kristian kọja. O ti tì í lẹhin la awujọ awọn eniyankeniyan, ifisẹwọn, ìnàlọ́rẹ́, ati ìsọlókùúta kọja. O ti fun un lokun gẹgẹ bi oun ti bá awọn agbara idari ipẹhinda ati igbagbọ Juu jà. O sì ran an lọwọ lati wọ ijakadi pẹlu awọn ọmọ ogun ẹmi eṣu alaiṣeefojuri. Lọna hihan gbangba, o fun un lokun titi de opin.—2 Kọrinti 10:4, 5; 11:21-27; Efesu 6:11, 12.

3. Awọn ibeere wo ni a gbe dide nipa alaafia Ọlọrun?

3 Ẹ wo ipa alagbara ti Pọọlu rii pe alaafia yii jẹ! Awa lonii ha lè mọ ohun ti o jẹ bi? Yoo ha ran wa lọwọ lati ṣọ awọn ọkan-aya wa ki o sì fun wa lokun gẹgẹ bi a ti ‘nja ija rere ti igbagbọ’ laaarin “igba elewu” ti o ṣoro wọnyi?—1 Timoti 6:12; 2 Timoti 3:1.

Alaafia Pẹlu Ọlọrun —Bi A Ti Padanu Rẹ̀

4. Ki ni diẹ lara awọn itumọ ọ̀rọ̀ naa “alaafia” ninu Bibeli?

4 Ninu Bibeli ọ̀rọ̀ naa “alaafia” ni ọpọlọpọ itumọ. Diẹ niwọnyi, gẹgẹ bi a ti tò ó lẹsẹẹsẹ ninu The New International Dictionary of New Testament Theology: “Lati ibẹrẹ de opin M[ajẹmu] L[aelae], [sha·lohmʹ] (alaafia) ni-ninu wiwa ni ipo alaafia ni itumọ gbigbooro julọ ti ọ̀rọ̀ naa (Ondj. 19:20); ire aasiki (Saamu 73:3, NW), ani ni titọka si awọn alaiwa bi Ọlọrun paapaa; ilera ara (Aisa. 57:18[, 19]; Saamu 38:3); ẹmi itẹlọrun . . . (Jẹn. 15:15 ati bẹẹ bẹẹ lọ); ibatan rere laaarin awọn orilẹ ede ati eniyan ( . . . Ondj. 4:17; 1 Kron. 12:17, 18); igbala ( . . . Jer. 29:11; fiwe Jer. 14:13).” Pataki julọ ni ibatan alalaafia pẹlu Jehofa, eyi ti o jẹ pe bí kò bá sí, ani labẹ ipo didara julọ paapaa, alaafia miiran eyikeyii wulẹ jẹ onigba diẹ ti o sì ni aala.—2 Kọrinti 13:11.

5. Bawo ni a ṣe dí alaafia iṣẹda Ọlọrun lọwọ ni ipilẹṣẹ?

5 Ni ipilẹṣẹ, gbogbo iṣẹda wà ni alaafia kikun pẹlu Jehofa. Pẹlu idi rere, Ọlọrun kede pe gbogbo awọn iṣẹ iṣẹda rẹ̀ ni o dara gan-an. Nitootọ, awọn angẹli ọrun hó ìhó ayọ ni rírí wọn. (Jẹnẹsisi 1:31; Joobu 38:4-7) Ṣugbọn, lọna ti o banininujẹ, alaafia agbaye yẹn kò tọ́jọ́. A ba a jẹ nigba ti ẹda ẹmi naa ti a mọ nisinsinyi si Satani tan ẹni titun julọ lara awọn ẹda ọlọgbọnloye Ọlọrun, Efa, kuro ninu igbọran si Ọlọrun. Ọkọ Efa, Adamu, tẹle e, ati pẹlu awọn ọlọtẹ mẹta ti wọn wà laini akoso, aiṣọkan wà lagbaaye.—Jẹnẹsisi 3:1-6.

6. Ki ni ipadanu alaafia Ọlọrun yọrisi fun araye?

6 Pipadanu alaafia pẹlu Ọlọrun jẹ àjálù fun Adamu ati Efa, awọn ẹni ti ara wọn bẹrẹ sii jagọ̀ diẹdiẹ nisinsinyi ti o si yọrisi iku wọn nikẹhin. Dipo gbigbadun alaafia ninu Paradise, Adamu nilati jijakadi pẹlu ilẹ ti a ko rò lẹhin ode Edeni lati bọ́ idile rẹ̀ ti npọ sii. Dipo jíjẹ́ iya fun iran ẹda eniyan pipe pẹlu itẹlọrun, Efa mu awọn ọmọ alaipe jade ninu irora ati ijiya. Pipadanu alaafia pẹlu Ọlọrun ṣamọna si owú ati iwa ipa laaarin awọn ẹda eniyan. Keeni pa arakunrin rẹ̀ Abẹli, ati ni akoko Ikun Omi, gbogbo ilẹ aye ni o kun fun ìwà-ipá. (Jẹnẹsisi 3:7–4:16; 5:5; 6:11, 12) Nigba ti awọn òbí wa akọkọ kú, dajudaju wọn kò lọ sinu iboji wọn pẹlu itẹlọrun, “ni alaafia,” gẹgẹ bi Abrahamu ti ṣe ni ọpọlọpọ ọgọrun-un ọdun lẹhin naa.—Jẹnẹsisi 15:15.

7. (a) Asọtẹlẹ wo ni Ọlọrun sọ jade ti o tọkasi imupadabọsipo alaafia kikun? (b) Bawo ni ọta Ọlọrun Satani ṣe ní agbara idari tó?

7 Lẹhin ti Adamu ati Efa padanu alaafia, a mẹnukan iṣọta akọkọ ninu Bibeli. Ọlọrun ba Satani sọrọ o si wi fun un pe: “Emi yoo sì fi ọta saaarin iwọ ati obinrin naa, ati saaarin iru ọmọ rẹ ati iru ọmọ rẹ̀: oun yoo fọ́ ọ ni ori, iwọ yoo sì pa á ní gìgísẹ̀.” (Jẹnẹsisi 3:15) Gẹgẹ bi akoko ti nlọ, agbara idari Satani pọ̀ debi ti apọsteli Johanu fi lè wipe: “Gbogbo aye ni o wà labẹ agbara ẹni buburu nì.” (1 Johanu 5:19) Dajudaju aye kan ti o wa labẹ Satani kò wa ni alaafia pẹlu Ọlọrun. Lọna ti o ba a mu, nigba naa, ọmọ-ẹhin naa Jakọbu kilọ fun awọn Kristian: “Ẹ kò mọ pe ibarẹ aye iṣọta Ọlọrun ni?”—Jakọbu 4:4.

Wiwa ni Alaafia ninu Aye Alainifẹẹ

8, 9. Lẹhin ti Adamu dẹṣẹ, bawo ni awọn ẹda eniyan ṣe lè wa ni alaafia pẹlu Ọlọrun?

8 Pada sẹhin ni Edeni, nigba ti Ọlọrun kọkọ mẹnukan ọ̀rọ̀ naa “iṣọta,” oun tun sọ asọtẹlẹ bi a o ṣe mu alaafia pipe perepere padabọsipo fun iṣẹda. Iru ọmọ obinrin Ọlọrun ti a ṣeleri yoo fọ ori oluba alaafia jẹ ipilẹṣẹ naa. Lati Edeni lọ, awọn wọnni ti wọn mu igbagbọ lò ninu Ileri yẹn gbadun ibatan alalaafia pẹlu Ọlọrun. Fun Abrahamu, eyi dagba di ipo ọ̀rẹ́.—2 Kironika 20:7; Jakọbu 2:23.

9 Ni akoko Mose, Jehofa sọ awọn ọmọ Israẹli, ọmọ ọmọ Abrahamu, di orilẹ ede kan. O nawọ alaafia rẹ̀ sí orilẹ ede yii, gẹgẹ bi a ti ri i ninu ibukun ti Aaroni, alufaa agba, kede pe yo jẹ tiwọn: “Njẹ ki Jehofa bukun yin ki o sì tọju yin. Njẹ ki Jehofa mu ki oju rẹ̀ tàn siha ọ̀dọ̀ yin, njẹ ki oun sì fi ojurere wò yin. Njẹ ki Jehofa gbe oju rẹ̀ siha ọ̀dọ̀ yin ki o si ran alaafia si yin.” (Numeri 6:24-26, NW) Alaafia Jehofa yoo mu awọn èrè wá lọna jìngbìnnì, ṣugbọn a nawọ rẹ̀ jade pẹlu awọn ipo kan ti a filelẹ.

10, 11. Fun Israẹli, lori ki ni alaafia pẹlu Ọlọrun sinmi lé, ki ni yoo sì yọrisi?

10 Jehofa sọ fun orilẹ ede naa pe: “Bi ẹyin ba nrin ninu ilana mi, ti ẹ sì npa ofin mi mọ, ti ẹ sì nṣe wọn; nigba naa ni emi yoo fun yin ni òjò ni akoko rẹ̀, ilẹ̀ yoo sì maa mu ibisi rẹ̀ wa, igi oko yoo sì maa so eso wọn. Emi yoo sì fi alaafia si ilẹ naa, ẹyin yoo sì dubulẹ, ko si si ẹni ti yoo dẹruba yin: emi yoo sì mu ki ẹranko buburu ki o dásẹ̀ kuro ni ilẹ naa, bẹẹ ni idà ki yoo la ilẹ yin ja. Emi yoo sì maa rìn laaarin yin, emi yoo sì maa ṣe Ọlọrun yin, ẹyin yoo sì maa ṣe eniyan mi.” (Lefitiku 26:3, 4, 6, 12) Israẹli le gbadun alaafia niti pe wọn ni aabo kuro lọwọ awọn ọta wọn, ọpọ rẹpẹtẹ ohun ti ara, ati ipo ibatan timọtimọ pẹlu Jehofa. Ṣugbọn eyi yoo sinmi lori rírọ̀ ti wọn bá rọ̀ mọ́ Ofin Jehofa.—Saamu 119:165.

11 Lati ibẹrẹ de opin itan orilẹ ede naa, awọn ọmọ Israẹli ti wọn fi pẹlu iṣotitọ gbiyanju lati pa ofin Jehofa mọ́ gbadun alaafia pẹlu rẹ̀, iyẹn sì maa nmu ọpọlọpọ ibukun miiran wa. Ni awọn ọdun ibẹrẹ ijọba Solomoni, alaafia pẹlu Ọlọrun mu aasiki ohun ti ara wa ati pẹlu isinmi kuro lọwọ ogun pẹlu awọn aladuugbo Israẹli. Ni ṣiṣapejuwe akoko naa, Bibeli wipe: “Juda ati Israẹli ngbe ni alaafia, olukuluku labẹ ajara rẹ̀ ati labẹ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, lati Daani titi de Beaṣeba, ni gbogbo ọjọ Solomoni.” (1 Ọba 4:25) Ani nigba ti ìkóguntini ṣẹlẹ pẹlu awọn ilẹ̀ ti o wa nitosi, awọn ọmọ Israẹli oluṣotitọ ṣi ni alaafia ti o ṣepataki niti gidi, alaafia pẹlu Ọlọrun. Nipa bayii, Ọba Dafidi, jagunjagun ti a mọ dunju kan, kọwe pe: “Emi yoo dubulẹ pẹlu ni alaafia emi yoo sì sùn; nitori iwọ, Oluwa [“Jehofa,” NW], nikanṣoṣo ni ó mu mi jokoo ni ailewu.”—Saamu 4:8.

Ipilẹ Didara Ju Kan fun Alaafia

12. Bawo ni Israẹli ṣe kọ alaafia Ọlọrun silẹ nikẹhin?

12 Asẹhinwa asẹhinbọ, Iru-ọmọ naa ti yoo mu alaafia pipe perepere pada farahan ẹni ti njẹ Jesu, ati ní igba ibi rẹ̀ awọn angẹli kọrin pe: “Ogo ni fun Ọlọrun loke ọrun, ati ni aye alaafia, ifẹ inurere si eniyan.” (Luuku 2:14) Jesu farahan ni Israẹli, ṣugbọn laika wiwa labẹ majẹmu Ọlọrun si, orilẹ ede yẹn lodidi kọ ọ silẹ wọn sì fa a le awọn ara Roomu lọwọ lati pa a. Ni kete ṣaaju iku rẹ̀, Jesu sọkun nitori Jerusalẹmu, ni wiwipe: “Ibaṣepe iwọ mọ̀, lonii yii, ani iwọ, ohun ti nṣe ti alaafia rẹ! Ṣugbọn nisinsinyi wọn pamọ kuro ni oju rẹ.” (Luuku 19:42; Johanu 1:11) Nitori kikọ Jesu silẹ, Israẹli padanu alaafia rẹ̀ pẹlu Ọlọrun patapata.

13. Ọna titun wo ni Jehofa fidi rẹ̀ mulẹ fun ẹda eniyan lati wá alaafia pẹlu Rẹ̀?

13 Laika eyiini si, awọn ète Ọlọrun ni a kò ké nígbèrí. Jesu ni a jinde kuro ninu oku, ti o sì fi itoye iwalaaye pipe rẹ̀ rubọ si Jehofa gẹgẹ bi irapada kan fun awọn ẹda eniyan ọlọkan rere. (Heberu 9:11-14) Ẹbọ Jesu di ọna titun ti o si dara ju fun awọn ẹda eniyan—fun awọn ọmọ Israẹli ti ara ati awọn Keferi—lati wa alaafia pẹlu Ọlọrun. Pọọlu wi ninu lẹta rẹ̀ si awọn Kristian ni Roomu pe: “Nigba ti awa wà ni ọta, a mu wa ba Ọlọrun laja nipa iku ọmọ [“Ọmọkunrin,” NW] rẹ̀.” (Roomu 5:10) Ni ọgọrun-un ọdun kìn-ínní, awọn wọnni ti wọn wa alaafia ni ọna yii ni a fi àmì ororo yan pẹlu ẹmi mimọ lati jẹ awọn ọmọkunrin àgbàṣọmọ Ọlọrun ati mẹmba orilẹ ede tẹmi titun kan ti a npe ni “Israẹli Ọlọrun.”—Galatia 6:16; Johanu 1:12, 13; 2 Kọrinti 1:21, 22; 1 Peteru 2:9.

14, 15. Ṣapejuwe alaafia Ọlọrun, ki o si ṣalaye bi o ṣe daabobo awọn Kristian ani nigba ti wọn ba jẹ ayanṣoju ìkóguntini niha ọ̀dọ̀ Satani.

14 Awọn ọmọ Israẹli tẹmi titun wọnyi yoo jẹ awọn ti Satani ati ayé rẹ̀ fojusun fun ìkóguntì. (Johanu 17:14) Bi o ti wu ki o ri, wọn yoo ni “alaafia lati ọdọ Ọlọrun Baba wa ati Kristi Jesu Oluwa wa.” (2 Timoti 1:2) Jesu sọ fun wọn pe: “Nnkan wọnyi ni mo ti sọ fun yin tẹlẹ, ki ẹyin ki o le ni alaafia ninu mi. Ninu aye, ẹyin yoo ni ipọnju; ṣugbọn ẹ tujuka; mo ti ṣẹgun aye.”—Johanu 16:33.

15 Eyi ni alaafia naa ti o ran Pọọlu ati awọn Kristian alabaakẹgbẹ rẹ̀ lọwọ lati farada laika gbogbo inira ti wọn dojukọ si. Wọn fi ipo ibatan alalaafia, oniṣọkan pẹlu Ọlọrun ti a mu ki o ṣeeṣe nipasẹ ẹbọ Jesu han. O nfun ẹni ti o bá ní in ni alaafia ero-inu didakẹrọrọ bi ó bá ti nmọ nipa idaniyan Jehofa. Ọmọ kan ti baba onifẹẹ gbe ní jẹlẹnkẹ sọwọ rẹ ní imọlara alaafia iru kan naa, idaniloju alainiyemeji pe a daabobo oun lati ọwọ ẹnikan ti o bikita fun oun. Pọọlu gba Awọn ara Filipi ni iyanju pe: “Ẹ maṣe aniyan ohunkohun; ṣugbọn ninu ohun gbogbo, nipa adura ati ẹ̀bẹ̀ pẹlu idupẹ, ẹ maa fi ibeere yin hàn fun Ọlọrun. Ati alaafia Ọlọrun, ti o ju imọran gbogbo lọ, yoo ṣọ́ ọkan ati èrò yin ninu Kristi Jesu.”—Filipi 4:6, 7.

16. Bawo ni alaafia pẹlu Ọlọrun ṣe nipa lori ipo ibatan awọn Kristian ọgọrun-un ọdun kìn-ínní pẹlu araawọn ẹnikinni keji?

16 Iyọrisi kan tí ó wá lati inu pipadanu ti eniyan padanu alaafia pẹlu Ọlọrun ni ikoriira ati aiṣọkan. Fun awọn Kristian ọgọrun-un ọdun kìn-ínní, riri alaafia pẹlu Ọlọrun yọrisi idakeji gan-an: alaafia ati iṣọkan laaarin araawọn, ohun ti Pọọlu pe ni “ìdè alaafia ti ńsonipọ̀ ṣọ̀kan.” (Efesu 4:3, NW) Wọn ‘ronu ni ifohunṣọkan wọn sì gbe pẹlu alaafia, Ọlọrun ifẹ ati alaafia sì wa pẹlu wọn.’ Ju bẹẹ lọ, wọn waasu “ihinrere alaafia,” eyi ti o jẹ ihinrere igbala ni pataki fun ‘awọn ọ̀rẹ́ alaafia,’ awọn wọnni ti wọn dahunpada si ihinrere naa.—2 Kọrinti 13:11; Iṣe 10:36; Luuku 10:5, 6.

Majẹmu Kan ti Alaafia

17. Ki ni Ọlọrun ti ṣe pẹlu awọn eniyan rẹ̀ ni ọjọ wa?

17 Njẹ a le ri iru alaafia bẹẹ lonii bi? Bẹẹni, a lè ri i. Lati igba ifidimulẹ Ijọba Ọlọrun labẹ Jesu Kristi ti a ti ṣelogo ni 1914, Jehofa ti ko iyoku awọn Israẹli Ọlọrun jọ lati inu aye yii o si da majẹmu alaafia pẹlu wọn. Oun tipa bayii mu ileri rẹ̀ ti oun ṣe nipasẹ wolii Esekiẹli ṣẹ pe: “Emi yoo ba wọn da majẹmu alaafia; yoo si jẹ majẹmu ayeraye pẹlu wọn: emi yoo sì gbe wọn kalẹ, emi yoo sì mu wọn rẹ̀, emi yoo sì gbe ibi mimọ mi si aarin wọn titi aye.” (Esekiẹli 37:26) Jehofa da majẹmu yii pẹlu awọn Kristian ẹni ami ororo ti wọn, mu igbagbọ lò ninu ẹbọ Jesu gẹgẹ bi awọn arakunrin wọn ni ọgọrun-un ọdun kìn-ínní. Bi a ti wẹ̀ wọn mọ kuro ninu èérí tẹmi, wọn ti ya araawọn si mimọ fun Baba wọn ọrun wọn sì lakaka lati tẹle awọn aṣẹ rẹ̀, paapaa julọ nipa mimu ipo iwaju ninu wiwaasu ihinrere Ijọba Ọlọrun ti a ti fidi rẹ̀ mulẹ yika aye.—Matiu 24:14.

18. Bawo ni awọn kan laaarin awọn orilẹ ede ṣe dahunpada nigba ti wọn loye pe orukọ Ọlọrun wa lara Israẹli Ọlọrun?

18 Asọtẹlẹ naa nbaa lọ pe: “Agọ mi yoo wà pẹlu wọn: nitootọ, emi yoo sì jẹ Ọlọrun wọn, wọn yoo sì jẹ eniyan mi, awọn Keferi [“awọn orilẹ-ede,” NW] yoo sì mọ pe, emi Oluwa [“Jehofa,” NW] ni o ti sọ Israẹli di mimọ.” (Esekiẹli 37:27, 28) Ni ibamu pẹlu eyi, ọgọrọọrun lọna ẹgbẹẹgbẹrun, bẹẹni, araadọta ọkẹ, lati inu awọn “orilẹ ede” ti mọ daju pe orukọ Jehofa wà lara Israẹli Ọlọrun. (Sẹkaraya 8:23) Lati inu gbogbo orilẹ ede, wọn ti dà gìrìgìrì wá lati ṣiṣẹsin Jehofa pẹlu orilẹ ede tẹmi yẹn ni didi “ogunlọgọ nla” ti a rí tẹlẹ ninu Iṣipaya. Lẹhin ti “wọn . . . ti fọ aṣọ igunwa ti wọn sì sọ wọn di funfun ninu ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́-àgùtàn naa,” wọn yoo la ipọnju nla ja sinu aye titun alalaafia kan.—Iṣipaya 7:9, 14.

19. Alaafia wo ni awọn eniyan Ọlọrun ngbadun lonii?

19 Lapapọ, Israẹli Ọlọrun ati ogunlọgọ nla ngbadun alaafia tẹmi ti o ṣeefiwera pẹlu alaafia ti Israẹli gbadun labẹ Ijọba Ọba Solomoni. Nipa wọn, Mika sọtẹlẹ pe: “Wọn yoo fi idà wọn rọ ohun eelo ìtúlẹ̀, wọn yoo sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé: orilẹ-ede ki yoo gbe idà soke si orilẹ-ede, bẹẹ ni wọn ki yoo kọ́ ogun jija mọ́. Ṣugbọn wọn yoo jokoo olukuluku labẹ àjàrà rẹ̀ ati labẹ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀; ẹnikan ki yoo si dáyàfò wọn.” (Mika 4:3, 4; Aisaya 2:2-4) Ni ibamu pẹlu eyi, wọn ti kọ ẹhin wọn si ogun ati rògbòdìyàn, wọn nfi idà wọn rọ ohun eelo itulẹ ati ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé lọna afiṣapẹẹrẹ. Nipa bayii, wọn gbadun ẹgbẹ́ ará alalaafia jakejado awujọ wọn lagbaye, laika orilẹ-ede, èdè, ẹya iran, ipilẹ ẹgbẹ oun ọgba ti wọn jẹ si. Wọn sì ni inudidun ninu idaniloju itọju alaabo Jehofa lori wọn. ‘Ẹnikẹni kò dáyàfò wọn.’ Nitootọ, ‘Jehofa funraarẹ ti fi okun fun awọn eniyan rẹ̀ nitootọ. Jehofa funraarẹ ti bukun awọn eniyan rẹ̀ pẹlu alaafia.’—Saamu 29:11, NW.

20, 21. (a) Eeṣe ti a fi gbọdọ ṣiṣẹ lori pipa alaafia wa pẹlu Ọlọrun mọ́? (b) Ki ni a lè sọ nipa awọn isapa Satani lati ba alaafia awọn eniyan Ọlọrun jẹ patapata?

20 Bi o ti wu ki o ri, gẹgẹ bi o ti ri ni ọgọrun-un ọdun kìn-ínní C.E., alaafia awọn iranṣẹ Ọlọrun ti ru ìkóguntì lati ọ̀dọ̀ Satani soke. Ni lile e jade kuro ni ọrun lẹhin ifidimulẹ Ijọba Ọlọrun ni 1914, lati igba naa Satani ti ba “iyoku ninu iru-ọmọ [obinrin naa]” jagun. (Iṣipaya 12:17, NW) Ani ni ọjọ rẹ̀ paapaa, Pọọlu kilọ pe: “Nitori pe kii ṣe ẹ̀jẹ̀ ati ẹran ara ni awa nba jijakadi, ṣugbọn . . . awọn ẹmi buburu ni oju ọrun.” (Efesu 6:12) Pẹlu Satani ti a ti hámọ́ agbegbe ilẹ aye nisinsinyi, ikilọ yii jẹ kanjukanju.

21 Satani ti lo gbogbo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ ti o wà ni ikawọ rẹ̀ ninu isapa rẹ̀ lati ba alaafia awọn eniyan Ọlọrun jẹ, ṣugbọn oun ti kùnà. Padasẹhin ni 1919 lọhun-un, iye awọn ti wọn lakaka lati ṣiṣẹsin Ọlọrun pẹlu iṣotitọ kò tilẹ tó 10,000. Lonii, iye ti o ju aadọta ọkẹ lọna mẹrin ni nbẹ ti wọn nṣẹgun aye nipasẹ igbagbọ wọn. (1 Johanu 5:4) Fun awọn wọnyi, alaafia pẹlu Ọlọrun ati alaafia pẹlu araawọn jẹ otitọ gidi, ani gẹgẹ bi wọn ti nfarada ìkóguntì lati ọdọ Satani ati iru ọmọ rẹ̀. Ṣugbọn ni oju iwoye ìkóguntì yii ati ni rironu nipa aipe tiwa funraawa ati “ìgbà ewu” ti a ngbe ninu rẹ̀, awa nilati ṣiṣẹ taapọntaapọn lati pa alaafia wa mọ. (2 Timoti 3:1) Ninu ọ̀rọ̀ ẹkọ ti o tẹle e, awa yoo ri ohun ti eyi ni ninu.

Njẹ Iwọ Le Ṣalaye Bi?

◻ Eeṣe ti eniyan fi padanu alaafia rẹ̀ pẹlu Ọlọrun ni ipilẹṣẹ?

◻ Fun Israẹli, lori ki ni alaafia pẹlu Ọlọrun sinmi lé?

◻ Lori ki ni a gbe alaafia pẹlu Ọlọrun kà lonii?

◻ Ki ni “alaafia Ọlọrun” ti nṣọ ọkan aya wa?

◻ Awọn ibukun siwaju sii wo ni a ngbadun ti a ba ni alaafia Ọlọrun?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́