Àlàáfíà Tòótọ́—Láti Orísun Wo?
“[Jèhófà] ń mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.”—ORIN DÁFÍDÌ 46:9, NW.
1. Ìlérí àgbàyanu wo nípa àlàáfíà ni a rí nínú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà?
“IṢẸ́ òdodo yóò sì jẹ́ àlàáfíà, àti èso òdodo yóò jẹ́ ìdákẹ́jẹ́ òun ààbò títí láé. Àwọn ènìyàn mi yóò sì máa gbé ibùgbé àlàáfíà, àti ní ibùgbé ìdánilójú, àti ní ibi ìsinmi ìparọ́rọ́.” (Aísáyà 32:17, 18) Ẹ wo irú ìlérí dídára ti èyí jẹ́! Ó jẹ́ ìlérí àlàáfíà tòótọ́, tí Ọlọ́run mú wá.
2, 3. Ṣàpèjúwe àlàáfíà tòótọ́.
2 Ṣùgbọ́n, kí ni àlàáfíà tòótọ́? Ó ha wulẹ̀ jẹ́ àìsí ogun bí? Àbí ó ha wulẹ̀ jẹ́ sáà kan tí àwọn orílẹ̀-èdè ń múra sílẹ̀ fún ogun mìíràn? Àlàáfíà tòótọ́ ha jẹ́ àlá lásán bí? A nílò ìdáhùn tí ó ṣeé gbára lé sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, àlàáfíà tòótọ́ ju àlá lásán lọ. Àlàáfíà tí Ọlọ́run ṣèlérí ré kọjá ohunkóhun tí ayé yìí lè ronú rẹ̀ lọ. (Aísáyà 64:4) Kì í ṣe àlàáfíà fún ìwọ̀nba ọdún díẹ̀ tàbí ẹ̀wádún díẹ̀. Yóò wà pẹ́ títí láé! Kì í sì í ṣe àlàáfíà fún àwọn kéréje tí wọ́n ní àǹfààní rẹ̀—ó ní ọ̀run àti ilẹ̀ ayé, àwọn áńgẹ́lì àti àwọn ẹ̀dá ènìyàn nínú. Ó nasẹ̀ dé ọ̀dọ̀ ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè, àwùjọ ẹ̀yà ìran, èdè, àti àwọ̀. Ààlà ilẹ̀, ohun ìdènà, ohun ìkùnà kì yóò fi àlàáfíà yẹn duni.—Orin Dáfídì 72:7, 8; Aísáyà 48:18.
3 Àlàáfíà tòótọ́ túmọ̀ sí àlàáfíà ojoojúmọ́. Ó túmọ̀ sí jíjí láràárọ̀ láìronú nípa ogun, láìṣàníyàn nípa ọjọ́ ọ̀la rẹ, ọjọ́ ọ̀la àwọn ọmọ rẹ, tàbí ọjọ́ ọ̀la àwọn ọmọ ọmọ rẹ pàápàá. Ó túmọ̀ sí ìbàlẹ̀ ọkàn pátápátá. (Kólósè 3:15) Ó túmọ̀ sí àìsí ìwà ọ̀daràn mọ́, àìsí ìwà ipá mọ́, àìsí ìdílé tí ń pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ mọ́, kò sí àwọn ènìyàn tí kò rílé gbé mọ́, kò sí àwọn tí ebi ń pa tàbí tí òtútù ń pa kú mọ́, kò sí àìsírètí àti ìjákulẹ̀ mọ́. Lọ́nà tí ó tún dára sí i, àlàáfíà Ọlọ́run túmọ̀ sí ayé kan láìsí àìsàn, ìrora, ìbànújẹ́, àti ikú mọ́. (Ìṣípayá 21:4) Ẹ wo irú ìrètí àgbàyanu tí a ní, láti gbádùn àlàáfíà tòótọ́ títí láé! Kì í ha ṣe irú àlàáfíà àti ayọ̀ yí ni gbogbo wa ń yán hànhàn fún bí? Kì í ha ṣe irú àlàáfíà yí ni ó yẹ kí a gbàdúrà fún, kí a sì ṣiṣẹ́ fún bí?
Ìsapá Ènìyàn Ti Já Sí Pàbó
4. Ìsapá wo ni àwọn orílẹ̀-èdè ti ṣe láti mú àlàáfíà wá, pẹ̀lú ìyọrísí wo sì ni?
4 Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè ti sọ̀rọ̀ nípa àlàáfíà, wọ́n ti jiyàn lórí àlàáfíà, wọ́n ti fọwọ́ sí ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìwé àdéhùn àlàáfíà. Kí sì ni ìyọrísí rẹ̀? Ní 80 ọdún tí ó ti kọjá, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí àkókò kan, tí orílẹ̀-èdè tàbí àwùjọ kan kò jagun. Ó ṣe kedere pé, àlàáfíà ti di àléèbá fún aráyé. Nítorí náà, ìbéèrè náà ni pé, Èé ṣe tí gbogbo ìsapá ènìyàn láti fìdí àlàáfíà kárí ayé múlẹ̀ fi já sí pàbó, èé sì ti ṣe tí ènìyàn kò fi lè mú àlàáfíà tòótọ́ tí yóò wà pẹ́ títí wá?
5. Èé ṣe tí ìsapá tí aráyé ti ṣe láti mú àlàáfíà wá fi já sí pàbó léraléra?
5 Ìdáhùn rírọrùn náà ni pé, aráyé kò tí ì yíjú sí orísun tí ó tọ́ fún àlàáfíà tòótọ́. Lábẹ́ agbára ìdarí Sátánì Èṣù, àwọn ènìyàn ti dá àwọn ètò àjọ tí àwọn àìlera àti àbùkù tiwọn fúnra wọn—ìwọra wọn àti ìlépa àṣeyọrí, ìfẹ́ tí wọ́n ní fún agbára àti òkìkí—ti nípa lé lórí, sílẹ̀. Wọ́n ti lọ sí àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga jù lọ, wọ́n sì ti dá àwọn àjọ àgbówókalẹ̀fún àti àjọ aṣèwádìí sílẹ̀, tí wọ́n ti wulẹ̀ túbọ̀ hùmọ̀ àwọn ọ̀nà ìninilára àti ìpanirun. Orísun wo ni a ti darí àwọn ẹ̀dá ènìyàn sí? Ibo ni wọ́n yíjú sí?
6, 7. (a) Ìtàn wo ni Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣe fún ara rẹ̀? (b) Ìtàn wo ni Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ti ṣe?
6 Nígbà náà lọ́hùn-ún, ní 1919, àwọn orílẹ̀-èdè gbẹ́kẹ̀ wọn lé Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, láti mú àlàáfíà pípẹ́ títí wá. Ìrètí wọ́n já sómi, nígbà tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Mussolini kógun ti Etiópíà ní 1935, àti nígbà tí ogun abẹ́lé bẹ́ sílẹ̀ ní Sípéènì, ní 1936. Ní 1939, nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ́ sílẹ̀, Ìmùlẹ̀ náà kò lè ta pútú mọ́. Àlàáfíà tí a fẹnu lásán pè bẹ́ẹ̀, kò tilẹ̀ pé 20 ọdún.
7 Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ńkọ́? Ó ha ti pèsè ojúlówó ìrètí fún àlàáfíà pípẹ́ títí kárí ayé bí? Rárá o. A ti ja ogun àti rògbòdìyàn olóhun-ìjà-ogun tí ó lé ní 150 láti ìgbà tí a ti dá a sílẹ̀ ní 1945! Abájọ tí Gwynne Dyer, akẹ́kọ̀ọ́ ogun àti ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Kánádà, ṣàpèjúwe àjọ UN gẹ́gẹ́ bí “ẹgbẹ́ àwọn apẹran láìgbàṣẹ tí wọ́n di olùtọ́jú ẹran, wọn kì í ṣe àwùjọ àwọn ẹni mímọ́,” wọ́n jẹ́ “àjọ tí kò lè ta pútú rárá, tí ń fìgbà gbogbo pariwo ẹnu.”—Fi wé Jeremáyà 6:14; 8:15.
8. Láìka ọ̀rọ̀ àsọọ̀sọtán wọn nípa àlàáfíà sí, kí ni àwọn orílẹ̀-èdè ti ń ṣe? (Aísáyà 59:8)
8 Láìka ọ̀rọ̀ àsọọ̀sọtán wọn nípa àlàáfíà sí, àwọn orílẹ̀-èdè ń bá a nìṣó ní híhùmọ̀ àwọn ohun ìjà ogun àti rírọ wọ́n. Àwọn orílẹ̀-èdè tí ń ṣonígbọ̀wọ́ àwọn ìpàdé àpérò àlàáfíà gan-an ni wọ́n tún sábà máa ń mú ipò iwájú nínú rírọ ohun ìjà ogun. Èrè gọbọi tí àwọn ilé iṣẹ́ okòwò ní àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ń jẹ, ń gbé rírọ àwọn ohun ìjà ogun aṣekúpani lárugẹ, títí kan àwọn bọ́ǹbù àrìmọ́lẹ̀, tí a fi ìwà ìkà gbé kalẹ̀, tí ń pa nǹkan bí 26,000 àwọn àgbàlagbà àti ọmọdé aráàlú lọ́dọọdún, tàbí kí ó sọ wọ́n di aláàbọ̀ ara. Ìwọra àti ìwà ìbàjẹ́ ni ipá tí ń sún wọn ṣiṣẹ́. Àbẹ̀tẹ́lẹ̀ àti owó ẹ̀yìn jẹ́ apá pàtàkì nínú ìṣòwò ohun ìjà ogun kárí ayé. Àwọn òṣèlú kan ti fi àbẹ̀tẹ́lẹ̀ àti owó ẹ̀yìn sọ ara wọn di ọlọ́rọ̀.
9, 10. Kí ni àwọn ògbóǹkangí inú ayé ti kíyè sí nípa ogun àti ìsapá ẹ̀dá ènìyàn?
9 Ní December 1995, Joseph Rotblat, ọmọ ilẹ̀ Poland, onímọ̀ físíìsì àti olùgba Ẹ̀bùn Ẹ̀yẹ Nobel Lórí Àlàáfíà, ké sí àwọn orílẹ̀-èdè láti fòpin sí ìfagagbága ní ti ohun ìjà ogun. Ó wí pé: “Ọ̀nà kan ṣoṣo láti dènà [ìfagagbága tuntun ní ti ohun ìjà ogun] ni láti fòpin sí ogun yán-ányán-án.” Ìwọ ha rò pé èyí lè ṣẹlẹ̀ bí? Láti 1928 wá, àwọn orílẹ̀-èdè 62 ti fọwọ́ sí Ìwé Àdéhùn Àlàáfíà Kellogg-Briand, nínú èyí tí wọ́n ti kọ ogun sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà àtiyanjú aáwọ̀. Ogun Àgbáyé Kejì fi hàn kedere pé, ìwé àdéhùn àlàáfíà náà kò ní láárí.
10 Ní kedere, ogun ni òkúta ìkọ̀sẹ̀ ìgbà gbogbo lójú ọ̀nà ìtàn aráyé. Gẹ́gẹ́ bí Gwynne Dyer ti kọ̀wé, “ogun jẹ́ àṣà pàtàkì nínú ọ̀làjú ẹ̀dá ènìyàn, ó sì ti wà láti ìgbà tí ọ̀làjú ti wà.” Bẹ́ẹ̀ ni, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ìpele ọ̀làjú àti ilẹ̀ ọba ni ó ní àwọn akọni ológun rẹ̀ tí ó ń bọlá fún, ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ tí ó wà ni sẹpẹ́, àwọn ìjà ogun rẹ̀ lílókìkí, àwọn ilé ẹ̀kọ́ṣẹ́ ogun mímọ́ rẹ̀, àti ìtòjọ pelemọ ohun ìjà ogun rẹ̀. Àmọ́, ọ̀rúndún wá ti jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ ní ti ogun ju ọ̀rúndún èyíkéyìí mìíràn lọ, ní ti ìpanirun àti ìṣòfò ẹ̀mí.
11. Lájorí kókó abájọ wo ni àwọn aṣáájú ayé ti gbójú fò dá nínú ìsapá wọn fún àlàáfíà?
11 Ó hàn gbangba gbàǹgbà pé, àwọn alákòóso ayé ti kọ lájorí ọgbọ́n tí ó wà nínú Jeremáyà 10:23 sílẹ̀, pé: “Olúwa, èmi mọ̀ pé, ọ̀nà ènìyàn kò sí ní ipa ara rẹ̀: kò sí ní ipa ènìyàn tí ń rìn, láti tọ́ ìṣísẹ̀ rẹ̀.” Bí a kò bá fi ti Ọlọ́run ṣe, kò lè sí àlàáfíà tòótọ́. Nígbà náà, gbogbo èyí ha túmọ̀ sí pé, ogun kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ nínú àwùjọ ọlọ́làjú bí? Ó ha túmọ̀ sí pé, àlàáfíà—àlàáfíà tòótọ́—jẹ́ àlá tí kò lè ṣẹ bí?
Mímọ Okùnfà Rẹ̀ Gan-an
12, 13. (a) Kí ni Bíbélì ṣípayá ní ti okùnfà gan-an, tí a kò rí nípa ogun? (b) Báwo ni Sátánì ṣe yí àfiyèsí aráyé pa dà kúrò nínú ojútùú gan-an sí àwọn ìṣòro ayé?
12 Láti dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn, a ní láti mọ okùnfà ogun. Bíbélì sọ ní kedere pé, áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ náà, Sátánì, ni “apànìyàn” ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà àti “òpùrọ́” àti pé, “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú naa.” (Jòhánù 8:44; 1 Jòhánù 5:19) Kí ni ó ti ṣe láti gbé àwọn ètekéte rẹ̀ lárugẹ? A kà ní Kọ́ríńtì Kejì 4:3, 4 pé: “Wàyí o, bí ìhìn rere tí àwa ń polongo bá wà lábẹ́ ìbòjú, ó wà lábẹ́ ìbòjú láàárín àwọn wọnnì tí ń ṣègbé, láàárín àwọn ẹni tí ọlọ́run ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí ti fọ́ èrò inú àwọn aláìgbàgbọ́ lójú, kí ìmọ́lẹ̀ títàn ìhìn rere ológo nípa Kristi, ẹni tí ó jẹ́ àwòrán Ọlọ́run, má baà mọ́lẹ̀ wọlé.” Sátánì ń ṣe gbogbo ohun tí ó lè ṣe láti yí àfiyèsí aráyé kúrò nínú Ìjọba Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ojútùú sí ìṣòro aráyé. Ó ń fi àwọn ọ̀ràn ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, ìṣèlú, àti ìsìn tí ń fa ìyapa, fọ́ àwọn ènìyàn lójú, ó sì ń fi wọ́n mú wọn ṣáko lọ, kí ìwọ̀nyí baà lè dà bí èyí tí ó ṣe pàtàkì ju ìṣàkóso Ọlọ́run lọ. Àpẹẹrẹ kan ni ti ẹ̀mí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni, tí ń peléke sí i kárí ayé, láìpẹ́ yìí.
13 Sátánì Èṣù ń gbé ẹ̀mí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni àti kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà lárugẹ, èrò ìgbàgbọ́ náà pé orílẹ̀-èdè kan, ẹ̀yà ìran kan, tàbí ẹ̀yà kan ló lọ́lá ju àwọn yòó kù lọ. Ìkórìíra jíjinlẹ̀ tí a ti bò mọ́lẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ni a tún ti hú jáde láti bu ẹ̀tù sí iná ogun àti rògbòdìyàn púpọ̀ sí i. Federico Mayor, olùdarí àgbà fún àjọ UNESCO, kìlọ̀ nípa ìtẹ̀sí yìí, ní sísọ pé: “Kódà ní àwọn ibi tí a ti sábà máa ń rára gba nǹkan sí nígbà kan rí, ìyípadà sí ẹ̀míi má-fojú-kàlejò ń di ohun tí ó hàn gbangba, lemọ́lemọ́ ni a sì ń gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ tàbí ọ̀rọ̀ ẹ̀yà ìran tèmi lọ̀gá tí a rò pé ó jẹ́ ohun àtijọ́.” Kí ni ó ti jẹ́ àbájáde rẹ̀? Ìpakúpa ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ ní Yugoslavia tẹ́lẹ̀ rí àti ti ìtàjẹ̀sílẹ̀ ẹlẹ́yà ìran ni Rwanda jẹ́ méjì péré lára irú ìdàgbàsókè bẹ́ẹ̀, tí ó ti di ìròyìn àgbáyé.
14. Báwo ni Ìṣípayá 6:4 ṣe ṣàpèjúwe ogun àti àwọn ipa tí ó ń ní ní àkókò wa?
14 Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé, ní àkókò òpin ètò ìgbékalẹ̀ yí, ẹṣin aláwọ̀ iná, tí ń ṣàpẹẹrẹ ogun, yóò bẹ́ gìjàgìjà jákèjádò ilẹ̀ ayé. A kà ní Ìṣípayá 6:4 pé: “Òmíràn sì jáde wá, ẹṣin aláwọ̀ iná; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni a sì yọ̀ǹda fún láti mú àlàáfíà kúrò ní ilẹ̀ ayé kí wọ́n lè máa fikú pa ara wọn lẹ́nì kíní kejì; a sì fún un ní idà ńlá kan.” Láti 1914, a ti ń rí i tí ẹṣin ìṣàpẹẹrẹ yìí ń “mú àlàáfíà kúrò,” tí àwọn orílẹ̀-èdè sì ti ń bá a lọ láti jagun àti láti gbógun.
15, 16. (a) Ipa wo ni ìsìn ti kó nínú ogun àti ìpànìyàn? (b) Ojú wo ni Jèhófà fi wo ohun tí ìsìn ti ṣe?
15 A kò gbọ́dọ̀ gbójú fo ipa tí ìsìn ń kó nínú àwọn ogun àti ìpànìyàn wọ̀nyí. Lọ́nà gíga, a lè sọ pé ipa ìdarí aṣinilọ́nà tí ìsìn èké ní, ni ó fa sábàbí ìtàn aráyé tí ẹ̀jẹ̀ ti rin gbingbin. Ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn Kátólíìkì náà, Hans Küng, kọ̀wé pé: “Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n pé, [àwọn ìsìn] ti ní ipa ìdarí ńláǹlà, tí ó burú, tí ó sì ń ṣekú pani lórí aráyé. Àwọn ni wọ́n jẹ̀bi gbọ́nmi-si-omi-ò-to, rògbòdìyàn afẹ̀jẹ̀wẹ̀, ‘àwọn ogun ìsìn’ ní ti gidi; . . . àti ogun àgbáyé méjèèjì pẹ̀lú.”
16 Ojú wo ni Jèhófà Ọlọ́run fi ń wo ipa tí ìsìn èké ń kó nínú ìpànìyàn àti ogun? A ṣàkọsílẹ̀ ẹ̀sùn tí Ọlọ́run fi kan ìsìn èkè sínú Ìṣípayá 18:5 pé: “Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ti wọ́jọ pọ̀ títí dé ọ̀run, Ọlọ́run sì ti pe àwọn ìṣe àìṣèdájọ́ òdodo rẹ̀ wá sí ìrántí.” Lílẹ̀ tí ìsìn èké lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn alákòóso ìṣèlú ayé yọrí sí irú ìjẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ bẹ́ẹ̀, irú ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ga gègèrègegere tó bẹ́ẹ̀, tí kò ṣeé ṣe fún Ọlọ́run láti gbójú fò ó dá. Láìpẹ́, òun yóò mú òkúta ìdìgbòlù yí kúrò pátápátá, nínú ìgbéṣẹ̀ rẹ̀ láti mú àlàáfíà tòótọ́ wá.—Ìṣípayá 18:21.
Ọ̀nà Àlàáfíà
17, 18. (a) Èé ṣe tí kì í fi í ṣe àlá tí kò lè ṣẹ lásán láti gbà gbọ́ pé, àlàáfíà títí láé ṣeé ṣe? (b) Kí ni Jèhófà ti ṣe, láti fẹ̀rí hàn pé àlàáfíà tòótọ́ yóò wà?
17 Bí àwọn ènìyàn kò bá lè tipasẹ̀ irú aṣojú bí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè mú àlàáfíà tòótọ́ tí yóò sì wà pẹ́ títí wá, orísun wo ni àlàáfíà tòótọ́ yóò ti wá, lọ́nà wo sì ni? Àbí ó ha wulẹ̀ jẹ́ àlá tí kò lè ṣẹ láti gbà gbọ́ pé àlàáfíà ayérayé ṣeé ṣe? Kò lè jẹ́ bẹ́ẹ̀, bí a bá yíjú sí orísun tí ó tọ́ fún àlàáfíà. Ta sì ni ẹni náà? Orin Dáfídì 46:9 (NW) dáhùn nípa sísọ fún wa pé, Jèhófà ‘ń mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé. Ó ṣẹ́ ọrun sí wẹ́wẹ́, ó sì ké ọ̀kọ̀ sí wẹ́wẹ́; ó sun àwọn kẹ̀kẹ́ nínú iná.’ Jèhófà sì ti bẹ̀rẹ̀ ọ̀nà tí yóò gbà mú ogun wá sí òpin, tí yóò sì gbà fìdí àlàáfíà tòótọ́ múlẹ̀. Lọ́nà wo? Nípa gbígbé Kristi Jésù gun orí ìtẹ́ Ìjọba rẹ̀ tí ó tọ́ sí i ní 1914, àti nípa ṣíṣonígbọ̀wọ́ ìgbétásì ètò ẹ̀kọ́ pípabanbarì jù lọ fún àlàáfíà nínú ìtàn aráyé. Ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ inú Aísáyà 54:13 mú un dá wa lójú pé: “A óò sì kọ́ gbogbo àwọn ọmọ rẹ láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá; àlàáfíà àwọn ọmọ rẹ yóò sì pọ̀.”
18 Àsọtẹ́lẹ̀ yí ṣàkàwé ìlànà okùnfà àti àbájáde—ìyẹn ni pé, gbogbo àbájáde ni ó ní okùnfà. Nínú ọ̀ràn yí, ẹ̀kọ́ Jèhófà—okùnfà—ń yí àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ arógunyọ̀ pa dà di olùfẹ́ àlàáfíà, tí wọ́n wà ní àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run. Ìyíkànpadà, tí ó sọ àwọn ènìyàn di olùfẹ́ àlàáfíà, ni àbájáde. Ẹ̀kọ́ yìí, tí ń yí ọkàn àyà àti èrò inú àwọn ènìyàn pa dà, ń tàn káàkiri àgbáyé nísinsìnyí pàápàá, bí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ “Ọmọ Aládé Àlàáfíà” náà, Jésù Kristi.—Aísáyà 9:6.
19. Kí ni Jésù fi kọ́ni nípa àlàáfíà tòótọ́?
19 Kí sì ni Jésù fi kọ́ni nípa àlàáfíà tòótọ́? Kì í ṣe àlàáfíà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè nìkan ni ó sọ nípa rẹ̀, bí kò ṣe àlàáfíà láàárín àwọn ènìyàn nínú àjọṣepọ̀ wọn àti àlàáfíà ti inú lọ́hùn-ún, tí ń wá láti inú ẹ̀rí ọkàn rere. Nínú Jòhánù 14:27, a kà nípa àwọn ọ̀rọ̀ Jésù sí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Mo fi àlàáfíà sílẹ̀ fún yín, mo fi àlàáfíà mi fún yín. Èmi kò fi í fún yín ní ọ̀nà tí ayé gbà ń fi í fúnni. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn àyà yín dààmú tàbí kí ó kó sókè nítorí ìbẹ̀rù.” Lọ́nà wo ni àlàáfíà Jésù gbà yàtọ̀ sí ti ayé?
20. Ọ̀nà wo ni Jésù yóò gbà mú àlàáfíà tòótọ́ wá?
20 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, àlàáfíà Jésù ní í ṣe gan-an pẹ̀lú ìhìn iṣẹ́ Ìjọba rẹ̀. Ó mọ̀ pé ìṣàkóso òdodo ní ọ̀run, tí ó ní Jésù àti 144,000 ajùmọ̀ṣàkóso nínú, yóò rẹ́yìn ogun àti àwọn arógunyọ̀. (Ìṣípayá 14:1, 3) Ó mọ̀ pé yóò mú ipò Párádísè pípa rọ́rọ́, tí ó ṣèlérí fún olubi tí ó kú lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, wá. Jésù kò ṣèlérí ibì kan nínú Ìjọba ọ̀run fún un, ṣùgbọ́n ó wí pé: “Ní òótọ́ ni mo sọ fún ọ lónìí, Ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.”—Lúùkù 23:43.
21, 22. (a) Ìrètí àgbàyanu gbígbéniró wo ni àlàáfíà tòótọ́ ní nínú? (b) Kí ni a ní láti ṣe kí ìbùkún yẹn baà lè ṣojú wa?
21 Bákan náà, Jésù mọ̀ pé Ìjọba òun yóò mú ìtùnú wá fún gbogbo àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, tí wọ́n lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. Àlàáfíà rẹ̀ ní ìrètí àgbàyanu àjíǹde, tí ń gbéni ró nínú. Rántí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ń gbéni ró, tí a rí nínú Jòhánù 5:28, 29 pé: “Kí ẹnu má ṣe yà yín sí èyí, nítorí pé wákàtí náà ń bọ̀ nínú èyí tí gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n wà nínú àwọn ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀ wọn yóò sì jáde wá, àwọn wọnnì tí wọ́n ṣe ohun rere sí àjíǹde ìyè, àwọn wọnnì tí wọ́n sọ ohun bíburú jáì dàṣà sí àjíǹde ìdájọ́.”
22 Ìwọ ha ń wọ̀nà fún àkókò yẹn bí? O ha ti pàdánù àwọn olólùfẹ́ rẹ nínú ikú bí? O ha ń yán hànhàn láti rí wọn lẹ́ẹ̀kan sí i bí? Nígbà náà, tẹ́wọ́ gba àlàáfíà tí Jésù ń nawọ́ rẹ̀ síni. Ní ìgbàgbọ́ bíi ti Màtá, arábìnrin Lásárù, tí ó sọ fún Jésù pé: “Mo mọ̀ pé yóò dìde nínú àjíǹde ní ìkẹyìn ọjọ́.” Ṣùgbọ́n, ṣàkíyèsí èsì tí ń tuni lọ́kàn tí Jésù fún Màtá pé: “Èmi ni àjíǹde àti ìyè. Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè; àti olúkúlùkù ẹni tí ń bẹ láàyè tí ó sì ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi kì yóò kú rárá láé. Ìwọ ha gba èyí gbọ́ bí?”—Jòhánù 11:24-26.
23. Èé ṣe tí ìmọ̀ pípéye nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi ṣe kókó nínú jíjèrè àlàáfíà tòótọ́?
23 Ìwọ pẹ̀lú lè gba ìlérí yẹn gbọ́, kí o sì jàǹfààní nínú rẹ̀. Lọ́nà wo? Nípa jíjèrè ìmọ̀ pípéye ti Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kíyè sí i bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì ìmọ̀ pípéye pé: “Àwa kò ṣíwọ́ gbígbàdúrà fún yín àti bíbéèrè pé kí ẹ lè kún fún ìmọ̀ pípéye nípa ìfẹ́ inú rẹ̀ nínú ọgbọ́n gbogbo àti ìfinúmòye ti ẹ̀mí, kí ẹ lè máa rìn lọ́nà tí ó yẹ Jèhófà fún ète wíwù ú ní kíkún bí ẹ ti ń bá a lọ ní síso èso nínú iṣẹ́ rere gbogbo tí ẹ sì ń pọ̀ sí i nínú ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run.” (Kólósè 1:9, 10) Ìmọ̀ pípéye yìí yóò mú ọ gbà gbọ́ dájú pé Jèhófà Ọlọ́run ni orísun àlàáfíà tòótọ́. Yóò tún sọ ohun tí o gbọ́dọ̀ ṣe nísinsìnyí fún ọ, kí o baà lè dara pọ̀ mọ́ onísáàmù náà ní sísọ pé: “Èmi óò dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ní àlàáfíà, èmi óò sì sùn; nítorí ìwọ, Olúwa, nìkan ṣoṣo ni o ń mú mi jókòó ní àìléwu.”—Orin Dáfídì 4:8.
Ìwọ Ha Lè Ṣàlàyé Bí?
◻ Èé ṣe tí ìsapá tí ẹ̀dá ènìyàn ti ṣe láti mú àlàáfíà wá fi já sí pàbó léraléra?
◻ Kí ni okùnfà ogun gan-an?
◻ Èé ṣe tí àlàáfíà pípẹ́ títí kì í fi í ṣe àlá tí kò lè ṣẹ?
◻ Kí ni orísun àlàáfíà tòótọ́?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Àlàáfíà tòótọ́ kì í ṣe àlá lásán. Ìlérí Ọlọ́run ni
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Láti 1914, ẹlẹ́ṣin aláwọ̀ iná ìṣàpẹẹrẹ náà ti mú àlàáfíà kúrò nínú ayé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Ìsìn àti àjọ UN ha lè mú àlàáfíà wá bí?
[CreditLine]
Fọ́tò àjọ UN