ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 4/15 ojú ìwé 5-7
  • Nigba Wo ni Alaafia Pipẹtiti Yoo De Niti Gidi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Nigba Wo ni Alaafia Pipẹtiti Yoo De Niti Gidi?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹni Naa Ti O Le Mu Alaafia Wa
  • Awọn Iṣẹlẹ ti Nṣamọna si Alaafia Pipẹtiti
  • Àmì Ikẹhin
  • Àlàáfíà Tòótọ́—Láti Orísun Wo?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ẹ Jẹ Ki “Alaafia Ọlọrun” Maa Daabobo Ọkan-aya Yin
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Máa Wá Àlàáfíà Tòótọ́, Kí O Sì Máa Lépa Rẹ̀!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • “Ìgbà Àlàáfíà” Ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Dé!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 4/15 ojú ìwé 5-7

Nigba Wo ni Alaafia Pipẹtiti Yoo De Niti Gidi?

“OGUN jẹ ọkan lara awọn iṣẹlẹ ti nwaye nigba gbogbo ninu itan, kò si tii dinku nitori ọ̀làjú tabi ijọba àdìbòyàn,” ni Will ati Ariel Durant kọwe ninu iwe wọn The Lessons of History. “Alaafia jẹ ipo iwọn deedee kan ti kò duro sojukan, eyi ti a lè tọjupamọ kiki nipa ipò ajulọ kan ti a mọ daju tabi agbara ti o baradọgba.”

Nitootọ, laika awọn isapa kikankikan sí, alaafia pipẹtiti ti fò araye ru jinnajinna. Eeṣe? Idi ni pe awọn okunfa ogun ta gbongbo jinlẹ ju ìjàgùdù ti oṣelu, ti ipinlẹ, tabi ti ẹgbẹ oun ọgba ti a ri loju ode lọ. Awọn Durant ṣakiyesi pe: “Awọn okunfa ogun jẹ ohun kan naa pẹlu awọn okunfa ìfagagbága laaarin awọn ẹni kọọkan: ẹmi oju kòkòrò, ẹmi aríjàgbá, ati ẹmi igberaga; ifẹ fun ounjẹ, ilẹ, awọn ohun ìní, epo, ijẹgaba.”

Bi o ti wu ki o ri, Bibeli ni pataki fi gbongbo okunfa rògbòdìyàn ati ogun laaarin awọn ẹni kọọkan ati laaarin ọpọlọpọ han. A kà pe: “Nibo ni ogun ti wá, nibo ni ìjà sì ti wá laaarin yin? Lati inu eyi ha kọ́? Lati inu ifẹkufẹẹ ara yin, ti njagun ninu awọn ẹ̀yà ara yin? Ẹyin nṣe ifẹkufẹẹ, ẹ kò sì ni: ẹyin npa, ẹ sì nṣe ilara, ẹ kò sì lè ni: ẹyin ńjà, ẹyin sì njagun.”—Jakọbu 4:1, 2.

Nigba naa, ariyanjiyan naa da lori eyi: Fun alaafia tootọ lati dé, a gbọdọ mu kii ṣe kiki awọn ami apẹẹrẹ—awọn ogun, irukerudo, fifi ipá gbà ijọba, iyipada tegbòtigaga—ṣugbọn gbòǹgbò awọn okunfa pẹlu—ifura, iwọra, ikoriira, iṣọta—kuro ninu gbogbo eniyan. Iwọnyi ni a gbọdọ rọpo pẹlu awọn ìṣe ti o ṣọkan delẹ pẹlu iru awọn animọ alaimọtara ẹni nikan bii ifẹ, inurere, igbẹkẹle, ati ìwà ọ̀làwọ́. Ẹnikan ha wà ti o lè ṣaṣepari eyi bi? Bi o ba sinmi lori awọn alaipe olugbe aye ẹni kiku, idahun naa ìbá ti jẹ bẹẹkọ. Ṣugbọn ẹnikan wà ti eyi kò ṣoro ju fun. Ẹni yii ni o ní idahun si ibeere naa: Nigba wo ni alaafia yoo de niti gidi?

Ẹni Naa Ti O Le Mu Alaafia Wa

Ni nǹkan bi ọrundun mejidinlọgbọn sẹhin, a misi wolii Aisaya lati polongo pe: “Nitori ọmọ kan ti wà ti a bi fun wa, ọmọkunrin kan ti wà ti a fifun wa; iṣakoso ọmọ alade yoo sì wà ni ejika rẹ̀. Orukọ rẹ̀ ni a o sì pe ni Agbayanu Olugbaninimọran, Ọlọrun Alagbara Nla, Baba Ayeraye, Ọmọ Alade Alaafia. Opin kì yoo sì si fun iṣakoso ọmọ alade naa ati ọpọ yanturu alaafia.”—Aisaya 9:6, 7, New World Translation.

Idamọ ẹni yii ti yoo mu alaafia ti kò ni opin wa ni a ṣipaya lẹhin naa pe kii ṣe ẹnikẹni miiran bikoṣe Jesu Kristi, “Ọmọ Ọga Ogo.” (Luuku 1:30-33; Matiu 1:18-23) Ṣugbọn eeṣe ti ẹni yii yoo fi ṣaṣeyọrisi rere nibi ti gbogbo awọn ọmọ alade ati awọn oluṣakoso miiran ti kùnà? A nilati ṣakiyesi, lakọọkọ, pe “ọmọ” ti a ṣeleri naa kò ni wà ni ọmọ ọwọ́ alaile ran araarẹ lọwọ titi lae, gẹgẹ bi awọn kan ti lè yaworan rẹ̀. Kaka bẹẹ, oun nilati lo “iṣakoso ọmọ alade” gẹgẹ bi “Ọmọ Alade Alaafia,” si ibukun ayeraye ti araye.

Ṣugbọn pupọ sii ni o wà si iṣakoso Jesu. Gẹgẹ bi “Agbayanu Olugbaninimọran,” ti o ni òye àrà ọ̀tọ̀ nipa iwa ẹda eniyan ati ibi ti agbara rẹ̀ mọ, oun yoo lè ri òkodoro ọ̀ràn títakókó ki o sì tipa bayii yanju awọn iṣoro adanilaamu ti o dojukọ ti o sì pin awọn oluṣakoso aye lonii lẹmii. (Matiu 7:28, 29; Maaku 12:13-17; Luuku 11:14-20) Lẹhin naa, gẹgẹ bi “Ọlọrun Alagbara,” ẹni bi Ọlọrun ti a ji dide naa, Jesu Kristi, ti a gbeka ori itẹ nisinsinyi ni ọrun gẹgẹ bi Ọba ti Mesaya, yoo ṣiṣẹ fun alaafia nipa ṣiṣatunṣe ohun ti oun ṣe nigba ti o wà lori ilẹ-aye ni iwọn gbigbooro—mimu awọn wọnni ti wọn ni aisan ti ko ṣee wò larada, pipese jíjẹ ati mímu fun ògìdìgbó awọn eniyan, ani ṣiṣekawọ oju ọjọ́ paapaa. (Matiu 14:14-21; Maaku 4:36-39; Luuku 17:11-14; Johanu 2:1-11) Gẹgẹ bi “Baba Ayeraye,” Jesu ni agbara lati mú awọn wọnni ti wọn ti ṣègbé ninu iku pada wá si iye ki o sì fi iye ayeraye fun wọn. Oun funraarẹ yoo walaaye titilae, ni titipa bayii mú un daju pe iṣakoso rẹ̀ ati alaafia ki yoo ni opin.—Matiu 20:28; Johanu 11:25, 26; Roomu 6:9.

Jesu Kristi, ti a ti tipa bayii murasilẹ ni o han kedere pe oun ni ẹni naa ti o lagbara lati dojukọ awọn okunfa ogun ati rogbodiyan ti o ti ta gbòǹgbò jinlẹ. Oun ki yoo wulẹ wewee adehun alaafia kan tabi ṣe iwewee fun ijumọgbepọ alalaafia fun awọn orilẹ-ede ti a fi ẹnu lasan pè bẹẹ, kiki lati fọ́ ọ yángá nipasẹ ogun miiran. Kaka bẹẹ, oun yoo mu gbogbo aidọgba ti oṣelu, ipinlẹ, ẹgbẹ-oun-ọgba, ati ti iṣowo kuro nipa mimu gbogbo araye wá sabẹ iṣakoso kan, iyẹn ti Ijọba Mesaya. Nipa didari gbogbo eniyan ninu ijọsin Ọlọrun otitọ kanṣoṣo, Jehofa, oun yoo mu ohun ti o jẹ ipilẹ okunfa ogun kuro—isin eke. Ko si iyemeji pe, Jesu Kristi, Ọmọ Alade Alaafia, yoo ṣaṣepari gbogbo eyi. Ibeere naa ni pe, Nigba wo?

Awọn Iṣẹlẹ ti Nṣamọna si Alaafia Pipẹtiti

Lẹhin ajinde ati igoke re ọrun rẹ̀ ni 33 C.E., Jesu nilati duro di akoko ti a yàn fún un lati gbe igbesẹ. Eyi wà ni ibamu pẹlu àṣẹ Jehofa: “Iwọ jokoo ni ọwọ́ ọtun mi, titi emi yoo fi sọ awọn ọta rẹ di apoti itisẹ rẹ. Oluwa [“Jehofa,” NW] yoo na ọ̀pá agbara rẹ̀ lati Sioni wá: iwọ jọba laaarin awọn ọta rẹ.” (Saamu 110:1, 2; Luuku 22:69; Efesu 1:20; Heberu 10:12, 13) Nigba wo ni iyẹn ṣẹlẹ? Fun ohun ti o ju 70 ọdun, awọn Ẹlẹrii Jehofa ti npokiki yika aye ihinrere naa pe Jesu Kristi ti bẹrẹsii ṣakoso ninu Ijọba Ọlọrun ni ọrun ni ọdun 1914.a

Ṣugbọn iwọ lè wi pe, ‘Ko tii si alaafia lati 1914. Ni idakeji, ipo awọn nǹkan nburu gidigidi sii lati igba naa wa.’ Otitọ gan-an ni iwọ sọ. Niti gidi eyi fi ẹri han pe awọn iṣẹlẹ nṣẹlẹ gan-an gẹgẹ bi a ti sọ ọ tẹlẹ. Bibeli sọ fun wa pe gan-an ni akoko ti “ijọba aye di ti Oluwa wa, ati ti Kristi rẹ̀; . . . inu sì bi awọn orilẹ-ede.” (Iṣipaya 11:15, 18) Dipo jijuwọ silẹ fun iṣakoso Jehofa Ọlọrun ati Ọmọ Alade Alaafia rẹ̀, awọn orilẹ-ede kó wọnu ijakadi onísìn-ínwín fun ìjẹgàba lori aye wọ́n sì fi ibinu han jade lodisi awọn Kristian ti wọn njẹrii si Ijọba Ọlọrun ti a fidi rẹ̀ mulẹ.

Iwe Iṣipaya tun ṣipaya pe ni gbàrà ti Jesu Kristi bọ sinu agbara Ijọba, oun gbe igbesẹ lati mu Satani ati awọn ẹmi eṣu rẹ̀ kuro ni ọrun: “Nigba yii ni igbala de, ati agbara, ati ijọba Ọlọrun wa, ati ọla ti Kristi rẹ̀; nitori a ti le olùfisùn awọn arakunrin wa jade, ti o nfi wọn sùn niwaju Ọlọrun wa lọsan ati loru.” Ki ni iyọrisi rẹ̀? Akọsilẹ naa nbaa lọ pe: “Nitori naa ẹ maa yọ̀, ẹyin ọ̀run, ati ẹyin ti ngbe inu wọn. Ègbé ni fun aye ati fun òkun! nitori Eṣu sọkalẹ tọ̀ yin wá ni ibinu nla, nitori o mọ̀ pe ìgbà kukuru ṣaa ni oun ni.”—Iṣipaya 12:10, 12.

Àmì Ikẹhin

Eyi fun wa ni ijinlẹ oye lati mọ idi ti awọn orilẹ-ede kò fi tii mu alaafia wa laika gbogbo awọn isapa wọn si. Ibinu nla Eṣu, ti a fihan ninu ibinu awọn orilẹ-ede funraawọn, ti mu ki aye wà ninu ìrugùdù ati ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ju ti igbakigba ri lọ ninu itan ẹda eniyan. Nigba wo ni gbogbo eyi yoo wá si opin? Bibeli pese ojutuu pataki kan: “Nigba ti wọn ba nwi pe, alaafia ati ailewu; nigba naa ni iparun ojiji yoo dé sori wọn.”—1 Tẹsalonika 5:3.

Iwọ ha mọriri ijẹpataki ikilọ yii bi? Awọn iṣẹlẹ aye iru bii awọn wọnni ti a sọ ni kulẹkulẹ ninu ọrọ ẹkọ iṣaaju fihan pe ọpọlọpọ awọn oluṣakoso ati awọn eniyan ti bẹrẹ sii sọrọ alaafia ti wọn sì ńnàgà fun un ju ti igbakigba ri lọ. Awọn kan nimọlara pe pẹlu opin Ogun Tutu, ihalẹ ipakupa àgbá atọmiiki jẹ ohun atijọ. Bẹẹni, awọn orilẹ-ede ti nsọ ọ̀rọ̀ pupọ nipa Alaafia ati ailewu. Ṣugbọn ipo aye niti tootọ ha forile ìhà yẹn bi? Ranti pe, Jesu sọ nipa awọn wọnni ti wọn ngbe laaarin awọn ọjọ ikẹhin yii, bẹrẹ ni 1914 pe: “Loootọ ni mo wi fun yin, iran yii ki yoo rekọja, titi gbogbo nǹkan wọnyi yoo fi ṣẹ.” (Matiu 24:34) Bẹẹni, alaafia yoo de niti gidi ninu iran yii ṣugbọn kii ṣe nipasẹ isapa awọn orilẹ-ede. Alaafia ti a fidi rẹ̀ mulẹ gbọnyingbọnyin, ti o ba idajọ ododo mu, ti o sì jẹ ododo ti a ṣeleri nipasẹ Jehofa Ọlọrun le de kiki nipasẹ iṣakoso ti Ọmọ Alade Alaafia rẹ̀, Jesu Kristi ti nsunmọtosi.—Aisaya 9:7.

Bi iwọ ba ṣafẹri ọjọ naa nigba ti alaafia yoo de niti gidi ati lati ni iriri rẹ̀ pẹlu awọn ololufẹ rẹ, nigba naa gbarale Ọmọ Alade Alaafia ki o sì fi awọn ọ̀rọ̀ atunininu rẹ̀ sọkan daradara pe: “Njẹ ki ẹ maa ṣọna, ki ẹ sì maa gbadura nigba gbogbo, ki ẹ baa le la gbogbo nǹkan wọnyi ti ńbọ̀wá ṣẹ, ki ẹ sì lè duro niwaju Ọmọ-eniyan.”—Luuku 21:36.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fun kulẹkulẹ lori kika akoko Bibeli ati imuṣẹ awọn asọtẹlẹ Bibeli, wo ori 12 si 14 ninu iwe naa “Let Your Kingdom Come” (Gẹẹsi), ti a tẹjade lati ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

A TUMỌ ALAAFIA

Lonii ọpọ julọ awọn eniyan ronu alaafia gẹgẹ bi aisi ogun tabi rògbòdìyàn. Bi o ti wu ki o ri, eyi jẹ itumọ ti kò kún tó nipa ọrọ naa.

Ni awọn akoko Bibeli ẹyọ ọrọ naa “alaafia” (Heberu, sha·lohmʹ) tabi apapọ ọrọ naa “Alaafia fun ọ!” ni a ńlò gẹgẹ bi ọna ìkíni kan. (Onidaajọ 19:20; Daniẹli 10:19; Johanu 20:19, 21, 26) Ni kedere, kò wulẹ tọkasi aisi ogun. Kiyesi ohun ti iwe naa The Concept of Peace sọ lori koko yii:

“Nigba ti a ba lo ọ̀rọ̀ naa shalom fun alaafia, ohun ti awọn wọnni ti wọn lò ó ni ipilẹṣẹ ni lọkan ni ipo ayé tabi ti awujọ eniyan ninu eyi ti ìpé pérépéré, iṣọkan, ijẹpipe, ẹkunrẹrẹ wà. . . . Nibi ti alaafia ba wà, ati odidi ati awọn apá rẹ̀ ti o ni ninu ti de ipele iwalaaye giga julọ ti o sì dara julọ.”

Nigba ti Ọlọrun ba mu alaafia wa, kii ṣe kiki pe awọn eniyan ki yoo “kọ́ ogun jija mọ” nikan ni ṣugbọn “wọn o jokoo olukuluku labẹ ajara rẹ̀ ati labẹ igi ọpọtọ rẹ̀.”—Mika 4:3, 4.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Aisi alaafia ni a ti nimọlara rẹ̀ lọna mimuna lati akoko Ogun Agbaye Kìn-ínní

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́