Ìwọ Yóò Ha Wà Níbẹ̀ Bí?
Ní ọdún tó kọjá, ó lé ní 8,700,000 ènìyàn jákèjádò ayé tí wọ́n lọ sí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Onídùnnú-Ayọ̀ Olùyìn” ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìwọ yóò ha wà nibi ọ̀kan lára àwọn Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọ́run” bí? A fi tìfẹ́tìfẹ́ ké sí ọ.
Ní ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ọ̀gangan àpéjọpọ̀, a óò bẹ̀rẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọpọ̀ náà ní agogo 9:30 òwúrọ̀ Friday pẹ̀lú orin. Àkókò ìjókòó ìgbà ìṣípàdé náà yóò ní ọ̀rọ̀ afúnniníṣìírí náà “Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?” Èyí yóò ní nínú, ìsọfúnni tí a lè lò láti ran àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ṣe ohun tí Ọlọ́run ń béèrè.
Ọ̀rọ̀ àsọyé ti ọ̀sán náà “Ríran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Kẹ́kọ̀ọ́ Ohun Tí Ọlọ́run Ń Béèrè” yóò mú àwọn onípàdè gbara dì láti ṣàjọpín nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn lọ́nà tí ó túbọ̀ gbéṣẹ́. Lẹ́yìn náà, àpínsọ ọ̀rọ̀ àsọyé alápá méjì náà “Ṣọ́ra fún Àwọn Ìdẹkùn Fífarasin ti Eré Ìnàjú” yóò kìlọ̀ nípa àwọn ìdẹkùn ẹlẹ́mìí èṣù tí ó yẹ láti yẹra fún. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Friday yóò wá sópin pẹ̀lú ọ̀rọ̀ pàtàkì náà “Fífi Ìdúróṣinṣin Gbé Ìjótìítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Lárugẹ.”
Àkókò ìjókòó ti ọ̀sán Saturday yóò tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì sísọni di ọmọ ẹ̀yìn nínú àpínsọ ọ̀rọ̀ àsọyé alápá mẹ́ta náà “Àwọn Ońṣẹ́ Tí Ń Mú Ìhìn Iṣẹ́ Rere Àlàáfíà Wá.” Ọ̀rọ̀ tó kẹ́yìn àkókò ìjókòó náà yóò jẹ́ lórí ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi, a óò sì ṣe ìrìbọmi fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun lẹ́yìn náà.
Ọ̀rọ̀ àsọyé ti ọ̀sán Saturday náà “Gbé Ìrònú Jèhófà Lórí Àwọn Ọ̀ràn Yẹ̀ Wò” yóò dáhùn àwọn ìbéèrè tí ọ̀pọ̀ ti ní lórí àwọn kókó ọ̀rọ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́. Ìwọ yóò gbádùn àpínsọ ọ̀rọ̀ àsọyé alápá méjì tí ń tu ọkàn lára náà “Ọlọ́run Àlàáfíà Ń Bìkítà fún Ọ.” Lẹ́yìn náà, a óò gbádùn ohun pàtàkì kan nígbà ọ̀rọ̀ àsọyé tí ó kẹ́yìn àkókò ìjókòó náà “Lépa Àlàáfíà Ọlọ́run Nínú Ìgbésí Ayé Ìdílé.”
Àpínsọ ọ̀rọ̀ àsọyé alápá mẹ́ta ti òwúrọ̀ Sunday náà, “Dídá Àwọn Ońṣẹ́ Tòótọ́ Mọ̀ Yàtọ̀,” yóò tẹnu mọ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ àpéjọpọ̀ náà nípa fífa àpẹẹrẹ àwọn wòlíì inú Bíbélì yọ. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ òwúrọ̀ yóò wá sópin pẹ̀lú àwòkẹ́kọ̀ọ́ ìgba láéláé tí yóò fa àwọn ẹ̀kọ́ ṣíṣeyebíye yọ láti inú àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa Onídàájọ́ Gídíónì.—Onídàájọ́ 6:11–8:28.
Àkókò ìjókòó tí ó kẹ́yìn àpéjọpọ̀ náà ní ọ̀sán Sunday yóò ní nínú, àwíyé fún gbogbo ènìyàn, èyí tí ó ní àkọlé náà “Àlàáfíà Tòótọ́ Nígbẹ̀yìngbẹ́yín!—Láti Orísun Wo?” Ní paríparí rẹ̀, ọ̀rọ̀ arunisókè náà “Títẹ̀ Síwájú Gẹ́gẹ́ Bí Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọ́run” yóò mú àpéjọpọ̀ náà wá sópin.
Níwọ̀n bí a ti ṣètò àpéjọpọ̀ 104 ní Nàìjíríà nìkan, ó ṣeé ṣe kí a ṣe ọ̀kan nítòsí ibi tí o ń gbé. Béèrè àkókò àti ibi àpéjọpọ̀ tí ó sún mọ́ ọ jù lọ lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n wà ládùúgbò. Ìtẹ̀jáde Jí!, September 22 pẹ̀lú yóò ní àkọsílẹ̀ àwọn àdírẹ́sì gbogbo ibi ọ̀gangan àpéjọpọ̀ ní Nàìjíríà.