ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 9/15 ojú ìwé 32
  • Ìwọ Kì Yóò Fẹ́ Láti Tàsé Rẹ̀!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwọ Kì Yóò Fẹ́ Láti Tàsé Rẹ̀!
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìwọ Yóò Ha Wà Níbẹ̀ Bí?
    Jí!—1996
  • O Kò Ní Fẹ́ Ṣàìlọ!
    Jí!—2000
  • Ṣó o Ti Ṣe Gbogbo Nǹkan Tó Yẹ Láti Lè Wà Ńbẹ̀?
    Jí!—2005
  • Wá sí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ìgbàgbọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run”!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 9/15 ojú ìwé 32

Ìwọ Kì Yóò Fẹ́ Láti Tàsé Rẹ̀!

Tàsé kí ni? Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọ́run” ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ń yára sún mọ́lé ni! Níbi púpọ̀ jù lọ, àpéjọpọ̀ náà yóò bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohùn orin ní agogo 9:30 òwúrọ̀ Friday. Lẹ́yìn títẹ́tí sí àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò afúngbàgbọ́lókun nínú apá náà, “Gbígbọ́rọ̀ Láti Ẹnu Àwọn Onítara Olùpòkìkí Àlàáfíà,” ìwọ yóò gbádùn àwíyé afúnniníṣìírí náà, “Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?”

Lájorí ọ̀rọ̀ àsọyé arùmọ̀lárasókè náà, “Ipa Iṣẹ́ Wa Gẹ́gẹ́ Bí Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọ́run,” ni kókó pàtàkì ọ̀sán Friday. Lẹ́yìn náà ni apá náà, “Ríran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Kẹ́kọ̀ọ́ Ohun Tí Ọlọ́run Ń Béèrè,” yóò fúnni ní àwọn àbá lórí kíkọ́ àwọn ẹni tuntun. Èyí ni àpínsọ ọ̀rọ̀ àsọyé tí ó bọ́ sákòókò náà yóò tẹ̀ lé, “Ṣọ́ra fún Àwọn Ìdẹkùn Fífarasin Ti Eré Ìnàjú.” Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ Friday yóò wá sí òpin pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ àwíyé náà, “Kọjú Ìjà sí Èṣù—Má Gba Ìbáradíje Láyè” àti “Fífi Ìdúróṣinṣin Gbé Ìjótìítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Lárugẹ.”

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ òwúrọ̀ ọjọ́ Saturday yóò tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn nínú àpínsọ ọ̀rọ̀ àsọyé alápá mẹ́ta náà, “Àwọn Ońṣẹ́ Tí Ń Mú Ìhìn Rere Àlàáfíà Wá.” Àkókò ìjókòó náà yóò wá sí òpin pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ àwíyé náà, “Ìfúnni Ọlọ́yàyà Nínú Ètò Àjọ Jèhófà” àti “Ìyè àti Àlàáfíà Nípasẹ̀ Ìyàsímímọ́ àti Batisí,” lẹ́yìn èyí tí àǹfààní yóò wà fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun láti ṣe batisí.

Ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ ọ̀sán Saturday “Gbé Ìrònú Jèhófà Lórí Àwọn Ọ̀ràn Yẹ̀ Wò” yóò dáhùn irú àwọn ìbéèrè bí ‘Àwọn Kristẹni ha ń nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìyàsọ́tọ̀ kan lónìí bí?’ àti ‘Kí ni ojú ìwòye Bíbélì nípa ìfìyà-ikú-jẹni?’ Ìwọ yóò tún gbádùn àpínsọ ọ̀rọ̀ àsọyé amọ́kànyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀, alápá méjì náà, “Ọlọ́run Àlàáfíà Ń Bìkítà fún Ọ,” àti ní pàtàkì ọ̀rọ̀ àsọparí náà, “Máa Lépa Àlàáfíà Ọlọ́run Nínú Ìgbésí Ayé Ìdílé.”

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ òwúrọ̀ Sunday yóò ní àpínsọ ọ̀rọ̀ àsọyé alápá mẹ́ta nínú, “Dídá Àwọn Ońṣẹ́ Tòótọ́ Mọ̀ Yàtọ̀,” àti ọ̀rọ̀ àsọyé náà, “Fetí Sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Kí O Sì Ṣègbọràn Sí I.” Ìtòlẹ́sẹẹsẹ òwúrọ̀ yóò parí pẹ̀lú àwòkẹ́kọ̀ọ́ onímùúra ti ìgbàanì àti ti òde òní, tí yóò fa àwọn ẹ̀kọ́ ṣíṣeyebíye yọ láti inú ìròyìn Bíbélì nípa Onídàájọ́ Gídéónì.

Àkókò ìjókòó tí ó kẹ́yìn nínú àpéjọpọ̀ náà ní ọ̀sán Sunday yóò ní nínú ọ̀rọ̀ àsọyé fún gbogbo ènìyàn, tí a pe àkòrí rẹ̀ ni “Àlàáfíà Tòótọ́ Nígbẹ̀yìn Gbẹ́yín!—Láti Orísun Wo?” Paríparí rẹ̀, ọ̀rọ̀ àsọyé arùmọ̀lárasókè náà, “Títẹ̀ Síwájú Gẹ́gẹ́ Bí Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọ́run,” yóò mú àpéjọpọ̀ náà wá sí òpin.

Wéwèé nísinsìnyí láti wà níbẹ̀. Láti rí ọ̀gangan tí ó sún mọ́ ilé rẹ jù lọ, kàn sí Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí kí o kọ̀wé sí àwọn tí ń ṣe ìwé ìròyìn yìí jáde. Ìtẹ̀jáde Jí! ti September 22 ti to gbogbo ọ̀gangan àpéjọpọ̀ ní Nàìjíríà lẹ́sẹẹsẹ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́