O Kò Ní Fẹ́ Ṣàìlọ!
ṢÀÌLỌ síbo? Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Olùṣe Ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Wí” ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni! Àwọn àpéjọpọ̀ wọ̀nyí, tí yóò bẹ̀rẹ̀ ní oṣù October ní Nàìjíríà, ni wọ́n ń ṣe ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìlú jákèjádò ayé. Ní ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ibi tí a óò ti ṣe é, a óò fi orin bẹ̀rẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ní agogo mẹ́sàn-án ààbọ̀ òwúrọ̀ ọjọ́ Friday.
Lẹ́yìn bíbẹ̀rẹ̀ ìpàdé náà pẹ̀lú fífún àwọn ará ní ìṣírí láti kọbi ara sí ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ, ìtòlẹ́sẹẹsẹ òwúrọ̀ yóò máa bá a nìṣó pẹ̀lú àsọyé náà, “Máa Tàn Yinrin Nítorí Oore Jèhófà” àti “Ẹ Máa Bá A Lọ Ní Fífẹsẹ̀múlẹ̀ Ṣinṣin Bí Ẹni Tí Ń Rí Ẹni Tí A Kò Lè Rí.” A óò sì parí ìtòlẹ́sẹẹsẹ òwúrọ̀ pẹ̀lú lájorí àsọyé àpéjọpọ̀ náà, “Ẹ Yin Jèhófà—Olùṣe Àwọn Ohun Àgbàyanu.”
Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ tí a óò sọ nígbà ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọ̀sán, ìyẹn, “Má Ṣe Jáwọ́ Nínú Ṣíṣe Ohun Tó Dára,” ni a óò sọ àpínsọ àsọyé alápá mẹ́ta kan tó dá lórí bí a ṣe lè yan ẹni tí a óò fẹ́, bí a óò ṣe ní ìdílé tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ nípa tẹ̀mí, àti bí a óò ṣe kọ́ àwọn ọmọ láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Àsọyé tí yóò kẹ́yìn lọ́jọ́ yẹn tí àkòrí rẹ̀ ń jẹ́, “Máa Bá Ètò Àjọ Jèhófà Rìn,” yóò sọ òye tí a ń ní ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé lóde òní nípa àwọn ète Ọlọ́run.
Èkejì lára àwọn àpínsọ àsọyé tó jẹ́ alápá mẹ́ta náà yóò wáyé nígbà ìtòlẹ́sẹẹsẹ òwúrọ̀ ọjọ́ Saturday, àkọlé rẹ̀ ni, “Àwọn Òjíṣẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” Èyí yóò dábàá nípa bí a ṣe lè máa ṣe iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. A óò tún gbọ́ àsọyé amúni-lọ́kàn-yọ̀ tí àkòrí rẹ̀ ń jẹ́, “Ṣíṣàìdójú Ti Ọlọ́run.” Lẹ́yìn náà ni a óò gbọ́ ọ̀rọ̀ lórí ìrìbọmi, a óò sì fún àwọn tí wọ́n bá tóótun ní àǹfààní láti ṣe ìbatisí.
Ìkẹta lára àwọn àpínsọ àsọyé tó jẹ́ alápá mẹ́ta ni a óò gbọ́ lọ́sàn-án, yóò sì dá lórí àkòrí náà, “Ẹ Ṣiṣẹ́ Kára Láti Jẹ́ Ènìyàn Tẹ̀mí,” nínú rẹ̀ ni a óò ti fún wa ní àwọn àbá tó gbéṣẹ́ nípa bí a ṣe lè jẹ́ ènìyàn tẹ̀mí. A óò mú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà wá sópin pẹ̀lú àsọyé tí ń lani lóye tí àkòrí rẹ̀ ń jẹ́, “Rírìn Nínú Ìmọ́lẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Tó Túbọ̀ Ń Mọ́lẹ̀ Sí I.” Yóò jíròrò ìwé Aísáyà orí kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n àti ìkẹrìndínlọ́gbọ̀n, yóò sì ṣàpèjúwe bí a ṣe lè lóye ìwé Bíbélì tí ń fani lọ́kàn mọ́ra yìí dáadáa.
Àpínsọ àsọyé alápá mẹ́ta tó kẹ́yìn yóò wáyé ní òwúrọ̀ ọjọ́ Sunday, àkọlé rẹ̀ ni, “Àsọtẹ́lẹ̀ Sefanáyà Tó Nítumọ̀ fún Àwọn Tí Ń Ṣèfẹ́ Ọlọ́run.” Yóò ṣàlàyé bí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣe ní ìmúṣẹ lórí orílẹ̀-èdè Júdà láyé ìgbàanì àti bó ṣe ń ní ìmúṣẹ lọ́jọ́ tiwa, ní pàtàkì bó ṣe kan àwọn ẹ̀sìn ayé yìí. Lẹ́yìn náà ni ẹ óò gbádùn àwòkẹ́kọ̀ọ́ ti ayé àtijọ́ tó ní àkọlé náà, “Àwọn Ohun Àríkọ́gbọ́n fún Wa Lónìí,” èyí tí yóò jíròrò nípa ìwà pálapàla tí àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì hù kété kí Ísírẹ́lì tó wọ Ilẹ̀ Ìlérí náà. Àsọyé fún gbogbo ènìyàn yóò jẹ́ apá kan ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọpọ̀ náà tó kẹ́yìn lọ́sàn-án ọjọ́ Sunday, àkọlé rẹ̀ ni “Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Ká Fiyè sí Àwọn Iṣẹ́ Àgbàyanu Ọlọ́run”
Ṣètò nísinsìnyí láti wà níbẹ̀ ní ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Láti mọ ibi tó sún mọ́ ibùgbé rẹ jù lọ, kàn sí Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ tàbí kí o kọ̀wé sí àwa tí a ṣe ìwé yìí. A to àwọn ibi tí a óò ti ṣe àpéjọpọ̀ yìí ní Nàìjíríà sínú ìkejì ìwé ìròyìn wa yìí, tó ń jẹ́ Ilé Ìṣọ́, nínú ìtẹ̀jáde rẹ̀ ti May 1, 2000.