Wíwo Ayé
Àwọn Ọmọ Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Fàájì
Ní ọdún 1999, fún ìgbà àkọ́kọ́, ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tí a lè mú gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ náwó tó pọ̀ lórí àwọn nǹkan àti ètò fàájì ju èyí tó ń ná lórí “oúnjẹ, ilé tàbí nǹkan mìíràn tí ìdílé ń náwó lé lórí lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀,” ìyẹn lohun tí ìwé ìròyìn London náà, Times, sọ. Lọ́dún 1968, ìpín mẹ́sàn-án péré nínú ọgọ́rùn-ún àròpọ̀ owó tí ìdílé ń ná ló ń lọ sórí fàájì, ṣùgbọ́n lónìí, ìpín mẹ́tàdínlógún nínú ọgọ́rùn-ún ni. Olùgbaninímọ̀ràn fún àwọn tó ń rajà, Martin Hayward, sọ pé: “Nítorí pé ní báyìí, a ti dọlọ́rọ̀ gidigidi ju ti nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn, àwọn nǹkan fàájì tó jẹ́ pé tí èèyàn bá rà wọ́n tẹ́lẹ̀, wọ́n á kà á sí pé nítorí afẹ́ ni, ti wá di nǹkan tí púpọ̀ jù lọ èèyàn kà sí ohun kò-ṣeé-mánìí báyìí. Ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn ló ti wá ka gbígba ọlidé sí ohun tí a ‘nílò’ kì í ṣe ohun tí a kàn ‘ń fẹ́.’ Àwọn kan tilẹ̀ gbà pé gbígba ọlidé lẹ́ẹ̀mẹ́ta lọ́dún jẹ́ ohun pàtàkì tí a nílò.” Àwọn agbo ìdílé wá ń ná ìlọ́po mẹ́rin owó sórí ohun èlò fídíò àti ti rédíò, tẹlifíṣọ̀n, àti àwọn kọ̀ǹpútà ju bí wọ́n ti ṣe lọ́dún 1968 lọ. Ní ti gidi, ọ̀kan nínú agboolé mẹ́wàá ló ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì, ọ̀kan nínú mẹ́ta ló sì ní kọ̀ǹpútà.
Rírẹjú Lọ́nà Tí Yóò Mú Kí Ara Èèyàn Nà
Ní ìbámu pẹ̀lú ìwé ìròyìn The New York Times, àṣà gbígbáralé mímu kaféènì kí èèyàn má bàa tòògbé ní ọwọ́ ọ̀sán lè má ṣàṣeyọrí ohun tí a ń fẹ́. Dókítà James Maas, tó jẹ́ ògbógi onímọ̀ nípa oorun ní Yunifásítì Cornell, wí pé: “Mímu kaféènì yóò mú kí gbogbo nǹkan súni. Àwọn oògùn tàbí ohun mímu tí èèyàn ṣe tí kì í jẹ́ kí oorun kun èèyàn kò lè dípò oorun tó yẹ kí o sùn.” Dípò tí èèyàn á fi ṣíwọ́ láti mu kọfí, Maas dábàá pé kí èèyàn rẹjú, ó sì sọ pé ìyẹn “yóò túbọ̀ fúnni lókun gidigidi láti pọkàn pọ̀ dáadáa láti ronú lórí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀, kí èèyàn sì ṣe ìpinnu tó bọ́gbọ́n mu.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Times ti sọ, rírẹjú díẹ̀ lọ́wọ́ ọ̀sán, fún àkókò tí kò tó ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, lè jẹ́ kí ara èèyàn tún le padà, kò ní ṣòro fún ẹni náà láti jí, kò sì ní ṣèdíwọ́ fún oorun àsùngbádùn lálẹ́. Maas sọ pé: “A ò gbọ́dọ̀ ta ko rírẹjú. Ohun tó yẹ kí èèyàn máa ṣe lójoojúmọ́ ni.”
Ṣé Ara Àgùntàn Ni Òwú Ti Ń Hù?
Ní ìbámu pẹ̀lú ìwádìí àìpẹ́ yìí tí Ẹgbẹ́ Àwọn Ọ̀dọ́ Àgbẹ̀ ní Ilẹ̀ Yúróòpù fi lọ́lẹ̀, àwọn ọmọ tí iye wọn jẹ́ “ìpín àádọ́ta nínú ọgọ́rùn-ún ní Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù ni kò mọ ibi tí ṣúgà ti ń wá, ìdá mẹ́ta nínú mẹ́rin . . . kò mọ ibi tí òwú ti ń wá, tí èyí tó ju ìdá kan nínú mẹ́rin sì gbà gbọ́ pé ara àgùntàn ló ti ń hù.” Láfikún sí i, ìpín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọ ọlọ́dún mẹ́sàn-án àti ọlọ́dún mẹ́wàá ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti ní Netherlands gbà gbọ́ pé orílẹ̀-èdè àwọn ni wọ́n ti ń gbin ọsàn àti ólífì. Lọ́pọ̀ ìgbà, kì í ṣe oko ni àwọn ọmọ ti ń rí àwọn irè oko sójú, bí kò ṣe ní ilé ìtajà, ilé ẹ̀kọ́ ni wọ́n sì ti sábà máa ń kọ́ nípa iṣẹ́ àgbẹ̀. Ìwọ̀nyí lè jẹ́ ara ìdí tí fífi iṣẹ́ àgbẹ̀ ṣiṣẹ́ ṣe kò fi ń fa ọ̀pọ̀ àwọn ọmọdé ní ilẹ̀ Yúróòpù mọ́ra lónìí. Ẹgbẹ́ náà sọ pé: “Ní ìpíndọ́gba, ìpín mẹ́wàá péré nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọ ní Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù ni ‘yóò fi gbogbo ara fẹ́’ láti di àgbẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.”
Ipò Ọ̀rẹ́ Ń Ko Ìṣòro
Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn The Wall Street Journal ti sọ, àwọn ọjọ́ iṣẹ́ tó túbọ̀ pọ̀ sí i, ìrìn àjò iṣẹ́ ajé tó túbọ̀ pọ̀ sí i, àti fífi àwọn ohun abánáṣiṣẹ́ ṣe eré ìnàjú “tó máa ń jẹ́ ká máa lo gbogbo nǹkan, ṣùgbọ́n tí kì í jẹ́ ká lájọṣe pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn” ti ń jin bíbá àwọn ẹlòmíràn dọ́rẹ̀ẹ́ lẹ́sẹ̀. Ìwé ìròyìn náà tún sọ pé: “A kò wò ó pé lílo àkókò pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ ṣe pàtàkì ṣùgbọ́n pé ṣe ló ń fi àkókò tó yẹ ká lò fún àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó kún fọ́fọ́ ṣòfò.” Ṣùgbọ́n àwọn tó pa bíbánidọ́rẹ̀ẹ́ tì lè rí i pé nígbà tí ọ̀ràn ìbìnújẹ́ bá ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé, “kò sẹ́ni tí wọ́n á rí,” gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ ìbágbépọ̀ ẹ̀dá, Jan Yager, ti sọ. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ó dà bíi pé àwọn ìwádìí fi hàn pé àwọn tó ní ọ̀rẹ́ rere kì í ní másùnmáwo púpọ̀, wọn kì í ṣàìsàn tó bẹ́ẹ̀, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n túbọ̀ pẹ́ láyé pàápàá. Ìwé ìròyìn Journal sọ pé: “Kókó ibẹ̀ ni pé kí o mọ̀ pé bíbá ọ̀rẹ́ ṣíṣe nìṣó ń gba àfikún ìsapá, gẹ́gẹ́ bó ṣe ń rí nígbà téèyàn bá ń ṣiṣẹ́, tó sì tún ń tọ́jú ìdílé.”
Àwọn Ọmọ Tó Tóbi Jù
Dókítà Chwang Leh-chii, tó jẹ́ olórí ẹgbẹ́ àwọn ògbóǹtagí onímọ̀ nípa oúnjẹ jíjẹ ní Taipei, Taiwan, kìlọ̀ pé: “Ìsanra jọ̀kọ̀tọ̀ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn àìlera tó burú jù lọ tó ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn èwe ní Éṣíà.” Ìwé ìròyìn Asiaweek ròyìn pé, àwọn ọmọ tó tóbi jù ti pọ̀ ní apá ibi púpọ̀ ní Éṣíà, pàápàá láàárín àwọn ọmọdékùnrin tó ń gbé ní ìgboro. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe láìpẹ́ yìí ní Beijing fi hàn pé ó ju ìpín ogún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti ilé ẹ̀kọ́ girama tí wọ́n tóbi jù. Ìròyìn náà sọ pé, ó dà bíi pé àwọn ọmọdé ní ilẹ̀ Éṣíà túbọ̀ ń lo àkókò púpọ̀ sí i láti fi wo tẹlifíṣọ̀n, kí wọ́n sì ṣe eré orí fídíò. Kí ni a lè ṣe? Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Asiaweek ti sọ, ojútùú rẹ̀ gan-an kì í ṣe pé kí wọ́n dín oúnjẹ tí àwọn ọmọ ń jẹ kù, ṣùgbọ́n kí wọ́n jẹ́ kí wọ́n máa ṣe eré ìdárayá déédéé, kí wọ́n sì máa jẹ oúnjẹ tí ń ṣara lóore—tó sábà máa ń ní àwọn èso àti ewébẹ̀ nínú dípò àwọn oúnjẹ tó kún fún ọ̀rá. Dókítà Chwang sọ síwájú sí i pé, jíjẹ́ kí àwọn iṣẹ́ tí a ń fara ṣe máa gbádùn mọ́ni ló lè mú kí èèyàn ṣàṣeyọrí. Ìròyìn náà sọ pé, àmọ́ bí àwọn ọmọ tó tóbi jù kò bá yí àṣà ìjẹun wọn padà, ìfúnpá wọ́n lè ga, ẹ̀dọ̀ wọn lè ní ìṣòro, wọ́n lè ní àrùn àtọ̀gbẹ, wọ́n sì lè ní ìṣòro ti ìrònú òun ìhùwà.
Sinimá àti Ṣọ́ọ̀ṣì
Ìwé ìròyìn The Independent, tí wọ́n ń ṣe ní London ròyìn pé: “Lójú àwọn ọ̀dọ́langba, àwọn fíìmù bíi Terminator 2, Titanic àti Star Wars fúnni ní ìrírí tó jinlẹ̀ ní ti ẹ̀sìn ju bí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ti ń ṣe.” Ọ̀mọ̀wé Lynn Clark, ti ibùdó ìwádìí nípa iṣẹ́ ìròyìn ní Yunifásítì Colorado, béèrè nípa fíìmù tó jọ ohun tí ẹ̀sìn wọn gbà gbọ́ jù lọ lọ́wọ́ àwọn ọ̀dọ́ tí iye wọn jẹ́ igba. Ọ̀pọ̀ ló dárúkọ Terminator 2, tó fi ìjàkadì tó ń bẹ láàárín ire àti ibi hàn, níbi tí òṣèré tó jẹ́ aṣíwájú nínú eré náà ti ń rìnrìn àjò padà láti lọ gba ọmọ kan tó dà bíi Mèsáyà là. Nígbà tí Ọ̀mọ̀wé Clark ń sọ̀rọ̀ níbi àpérò kan ní Edinburgh, Scotland, ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Òṣèré burúkú tó ń jẹ́ Darth Vader àti eré X Files làwọn ọ̀dọ́ wá ń wò báyìí gẹ́gẹ́ bí ohun tí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ láti bá wọn yanjú ìbéèrè nípa ohun tí ìwàláàyè dá lé lórí. Eré X Files ń fà wọ́n mọ́ra nítorí pé ó ń ṣàyẹ̀wò kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa agbára kan tí a kò mọ̀ tó ń ṣàkóso àgbáyé. Ó gbé ìbéèrè dìde pé àwọn nǹkan kan wà tí sáyẹ́ǹsì kò ṣàlàyé wọn. Ìbéèrè tó jẹ́ ti ìsìn ni, ṣùgbọ́n ìsìn kò dáhùn ìbéèrè náà bó ti yẹ.”
Sìgá Mímu Máa Ń Ké Ìwàláàyè Kúrú
Ìwé ìròyìn University of California Berkeley Wellness Letter sọ pé: “Ọ̀kọ̀ọ̀kan sìgá tí èèyàn bá mu ló máa ń dín ìṣẹ́jú mọ́kànlá kù nínú ọjọ́ ayé ẹni náà.” Nípa báyìí, bí ó bá mu páálí sìgá kan tán, ìyẹn yóò dín ọjọ́ kan ààbọ̀ kù nínú ọjọ́ ayé ẹni náà, lọ́dún kọ̀ọ̀kan tó bá sì fi ń mu páálí kan lójúmọ́, yóò dín ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó oṣù méjì kù nínú ọjọ́ ayé rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn olùwádìí ní Yunifásítì ti Bristol, ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti sọ. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì dórí ìdíwọ̀n yìí nípa fífi iye ọdún tí àwọn èèyàn tó ń mu sìgá ń lò láyé wé ti àwọn tí kì í mu sìgá. Àwọn olùwádìí náà sọ pé: “Ó fi ohun tí sìgá mímú ń náni hàn lọ́nà tó lè yé gbogbo èèyàn.”
Àwọn Erin “Ayàwòrán”
Ní Ottapalam, ní ilẹ̀ Íńdíà, wọ́n ń kọ́ àwọn ọmọ erin láti máa ya àwòrán nípa fífi ọwọ́ ìjà wọn mú búrọ́ọ̀ṣì ìyàwòrán. Àwọn alágbàwí ààbò ẹ̀dá ti dá Ilé Iṣẹ́ Tí Erin Ti Ń Ya Àwòrán Tí A Sì Ti Ń Pa Á Mọ́ sílẹ̀ láti kówó jọ nítorí àtidáàbò bo àwọn erin nípa títa àwòrán tí àwọn erin bá yà, ìyẹn ni ohun tí ìwé ìròyìn The Indian Express sọ. Ó dà bíi pé akọ erin ọlọ́dún mẹ́fà kan tó ń jẹ́ Ganesan fẹ́ràn iṣẹ́ “ìyàwòrán” tó ń ṣe gidigidi. Bí àwòrán bá ti ń wù ú yà, yóò gbọn etí rẹ̀ pepe, yóò sì gba búrọ́ọ̀ṣì ìyàwòrán lọ́wọ́ ẹni tó ń kọ́ ọ níṣẹ́. Bí Ganesan bá ti ń yàwòrán lọ́wọ́, kì í fẹ́ kí wọ́n dí òun lọ́wọ́, kódà kò ní fẹ́ kí ẹyẹ tàbí ọ̀kẹ́rẹ́ dí òun lọ́wọ́. Lẹ́yìn tí Ganesan bá ti yàwòrán tó lẹ́wà fún ìgbà díẹ̀, yóò dáwọ́ dúró, yóò sì ṣe bí ẹni pé ó ń ṣàyẹ̀wò iṣẹ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n, kì í ṣe gbogbo erin kéékèèké ló máa ń gbà pé kí wọ́n sọ àwọn di ẹranko “ayàwòrán.” Àwọn kan máa ń fi ìbínú wọn hàn nípa bíba búrọ́ọ̀ṣì ìyàwòrán jẹ́.
Ìbímọ Tí A Ṣètò
Ìwé ìròyìn Corriere della Sera tó jẹ́ ti Ítálì sọ pé: “Àwọn ọmọ ti mọ bí wọn yóò ṣe bí àwọn nígbà tí ilé ìwòsàn bá fẹ́.” Níbi àpérò kan nípa ìbímọ, èyí tí wọ́n ṣe láìpẹ́ yìí ní Florence, Ítálì, ọmọ Switzerland náà, Fred Paccaud, tó jẹ́ onímọ̀ nípa ìtọ́jú obìnrin sọ pé: “Láti ọ̀rúndún kọkàndínlógún, ní ìhà Ìwọ̀ Oòrùn ayé, àwọn tó ń bímọ ní ọjọ́ Sátidé àti Sunday ti fi ìpín márùnléláàádọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún dín kù. Ṣùgbọ́n kò tán síbẹ̀ o: A lè sọ pé ọ̀pọ̀ jù lọ ọmọ ni wọ́n máa ń bí ní àkókò tí àwọn òṣìṣẹ́ máa ń wà lẹ́nu iṣẹ́, ìyẹn ni pé ní àkókò tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn dókítà àti nọ́ọ̀sì máa ń wà níbi iṣẹ́.” Wọ́n lè lo egbòogi fún ìyá ọmọ náà kó lè bí i lákòókò náà tàbí kí wọ́n gbẹ̀bí rẹ̀ nípasẹ̀ iṣẹ́ abẹ. Angelo Scuderi, tó wá láti Florence, tó sì jẹ́ onímọ̀ nípa ìtọ́jú àwọn obìnrin, wí pé: “Ó wá di pé ká máa lo egbòogi fún wọn, ká sì máa ṣiṣẹ́ abẹ fún wọn kí wọ́n lè bí ọmọ. Gbígbẹ̀bí fáboyún nípasẹ̀ iṣẹ́ abẹ túbọ̀ wá ń yára pọ̀ sí i, èyí tí wọ́n ń lò fún ìpín ogún nínú ọgọ́rùn-ún [àwọn ọmọ tí wọ́n ń bí] nísinsìnyí.” Ṣùgbọ́n, Ọ̀jọ̀gbọ́n Carlo Romanini, tó jẹ́ ààrẹ Ẹgbẹ́ Onímọ̀ Nípa Ìtọ́jú Obìnrin àti Ìbímọ ní Ítálì, sọ pé, “‘ṣíṣètò’ ìgbà tí ẹnì kan yóò bímọ kì í ṣe ọ̀ràn yíyan ìgbà tí yóò rọni lọ́rùn” ṣùgbọ́n ó jẹ́ láti dáàbò bo àwọn ìyá àti ọmọ wọn jòjòló lọ́wọ́ àwọn ìṣòro tí a kò rí tẹ́lẹ̀. Ó wí pé: “Ó dára púpọ̀ pé kí wọ́n [bímọ] nígbà tí àwọn òṣìṣẹ́ bá pọ̀ ní ilé ìwòsàn, tí wọ́n sì lè fọwọ́ sọ̀yà pé àwọn yóò ṣe gbogbo ìtọ́jú tí àwọn bá lè ṣe.”