ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g01 6/8 ojú ìwé 30-31
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—2001
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Pípààrọ̀ Ẹ̀sìn ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì
  • Báa Ṣe Ń Gbé Ìgbésí Ayé àti Àrùn Jẹjẹrẹ
  • Lo Ọpọlọ Rẹ
  • Àwọn Erin “Kì Í Gbàgbé Ọ̀rẹ́ Wọn”
  • Àwọn Onífàyàwọ́ Oògùn Líle Tó Ń Lo Ọgbọ́n Iṣẹ́ Ẹ̀rọ Gíga
  • Ọkàn Àwọn Ẹranko Balẹ̀ ní DMZ
  • Kò Rọrùn Láti Ṣíwọ́ fún Oúnjẹ Ọ̀sán
  • Tábà Mímu Di Bára Kú Ní Mẹ́síkò
  • Ṣé Ìyẹn Ni Ojútùú sí Àìní Tẹ̀mí?
  • Eyín Erin—Báwo Ló Ṣe Níye Lórí Tó?
    Jí!—1998
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1997
  • Sìgá—O Ha Máa Ń Kọ̀ Ọ́ Bí?
    Jí!—1996
  • Wíwo Ayé
    Jí!—2000
Àwọn Míì
Jí!—2001
g01 6/8 ojú ìwé 30-31

Wíwo Ayé

Pípààrọ̀ Ẹ̀sìn ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì

Ìwé ìròyìn The Sunday Telegraph sọ pé, ìṣọwọ́ pààrọ̀ ẹ̀sìn àwọn ará Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti wá kúrò ní kèrémí, pẹ̀lú nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan tó ń tinú ẹ̀sìn kan bọ́ sí òmíràn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ó ní: “Àwọn Áńgílíkà ń di Kátólíìkì, bẹ́ẹ̀ làwọn Kátólíìkì ń di Áńgílíkà, àwọn Júù ń di ẹlẹ́sìn Búdà, Mùsùlùmí ń di Áńgílíkà, àwọn Kátólíìkì sì ń di Júù.” Ẹ̀sìn Ìsìláàmù, Búdà, àwọn Gba-Ohun-Tó Wù-Ẹ́-Gbọ́, àtàwọn abọgibọ̀pẹ̀ ló ń lọ́mọ ẹ̀yìn jù lọ. Ọ̀mọ̀wé Ahmed Andrews ti Yunifásítì Derby ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tóun náà pààrọ̀ ẹ̀sìn sọ pé: “Àwọn aláwọ̀ funfun tó di Mùsùlùmí lórílẹ̀-èdè yìí ń lọ sí ẹgbẹ̀rún márùn ún sí mẹ́wàá, èyí tó sì pọ̀ jù lọ nínú àwọn tí mo mọ̀ ló jẹ́ pé Kátólíìkì ni wọ́n tẹ́lẹ̀.” Nínú àwọn tó yí padà sí ìsìn Búdà, ìpín mẹ́wàá sí ìpín ọgbọ̀n nínú ọgọ́rùn ún ló jẹ́ Júù. Báwọn Áńgílíkà ṣe ń yí padà sí ẹ̀sìn Kátólíìkì tún lọ sókè sí i lẹ́yìn tí Ṣọ́ọ̀ṣì Ilẹ̀ England pinnu láti máa fi àwọn obìnrin joyè. Gẹ́gẹ́ bí Jonathan Romain tó jẹ́ Rábì ti sọ, “àwọn èèyàn rí i pé àwọn kò mọ nǹkan kan nípa tẹ̀mí, ìyẹn ló jẹ́ kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í yẹ àwọn ìsìn mìíràn tó yàtọ̀ séyìí tí wọ́n bí wọn sínú rẹ̀ wò.”

Báa Ṣe Ń Gbé Ìgbésí Ayé àti Àrùn Jẹjẹrẹ

Ìwé ìròyìn The Guardian ti London sọ pé: “Ìwádìí tí wọ́n ṣe fún àwọn ìbejì tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọ̀kẹ́ mẹ́rin ààbọ̀ [90,000] ti fi hàn pé ohun tó tóbi jù lọ tó ń fa àrùn jẹjẹrẹ ni ibi tóo wà, ohun tí o ń ṣe, àti ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé rẹ dípò tí ì bá fi jẹ́ pé irú ẹni tóo jẹ́ ló fà á.” Dókítà Paul Lichtenstein ti Ilé Ẹ̀kọ́ Sweden’s Karolinska ló ṣáájú àwùjọ tó ṣe ìwádìí yìí. Ó sọ pé: “Àwọn kókó tó ní í ṣe pẹ̀lú àyíká wa ló ṣe pàtàkì ju ti àwọn àbùdá wa lọ.” Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì gbà pé sìgá mímu ló ń ṣokùnfà ìpín márùndínlógójì nínú ọgọ́rùn-ún àrùn jẹjẹrẹ, tó sì jọ pé irú oúnjẹ táa ń jẹ ló ń fa ìpín ọgbọ̀n. Àwọn ohun tí àbùdá ń fà náà ní ipa tí wọ́n ń kó nínú àrùn jẹjẹrẹ ẹ̀yà ara tí ń sun omi jáde lókè àpò-ìtọ̀ (prostate), ti ìfun ńlá àti ti ọmú, àmọ́ Dókítà Tim Key tó ń bójú tó Owó Dídá fún Ìwádìí Àrùn Jẹjẹrẹ ti Ìjọba ní Oxford, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kìlọ̀ pé: “Ká tiẹ̀ ní o wá . . . láti ìdílé kan tẹ́ni tó [lárùn jẹjẹrẹ] wà, bóo ṣe ń lo ìgbésí ayé rẹ loun tó ṣì ṣe pàtàkì jù lọ. O kò gbọ́dọ̀ mu sìgá, o gbọ́dọ̀ ṣọ́ nǹkan tí o ń jẹ. Àwọn ohun wọ̀nyẹn lè dín ewu níní àrùn jẹjẹrẹ kù.”

Lo Ọpọlọ Rẹ

Ìwé ìròyìn Vancouver Sun sọ pé: “Agbára ọpọlọ lè wà láìyingin jálẹ̀ gbogbo ìgbésí ayé wa, níwọ̀n ìgbà tá ò bá ti dáwọ́ lílò ó dúró.” Dókítà Amir Soas ti Ilé Ẹ̀kọ́ṣẹ́ Oògùn ní Yunifásítì Case Western Reserve ní Ohio, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Máa kàwé, máa kàwé, máa kàwé.” Bóo bá fẹ́ kí agbára ọpọlọ rẹ ṣì wà digbí bóo ti ń dàgbà, yan ìgbòkègbodò àfipawọ́ tó máa jẹ́ kóo lo ọpọlọ rẹ dáadáa, kọ́ èdè tuntun, kọ́ bí wọ́n ṣe ń lo ohun èlò ìkọrin kan, tàbí kóo máa lọ́wọ́ nínú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó ń runi sókè. Dókítà Soas sọ pé: “Ohunkóhun tó bá ṣáà ti lè ru ọpọlọ sókè láti ronú.” Ó tún fúnni níṣìírí láti dín tẹlifíṣọ̀n wíwò kù. Ó sọ pé: “Nígbà tóo bá ń wo tẹlifíṣọ̀n lọ́wọ́, ńṣe ni ọpọlọ rẹ máa jókòó tẹtẹrẹ.” Ìwé ìròyìn Sun fi kún un pé ọpọlọ tó jí pépé tún nílò afẹ́fẹ́ ọ́síjìn tí òpójẹ̀ tó jíire ń gbé wá sínú rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, eré ìmárale àti oúnjẹ tó jíire, àwọn ohun kan náà tó ń dènà àrùn ọkàn àti àtọ̀gbẹ, tún máa ń ran ọpọlọ lọ́wọ́.

Àwọn Erin “Kì Í Gbàgbé Ọ̀rẹ́ Wọn”

Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé: “Àwọn erin kò gbàgbé àwọn ọ̀rẹ́ wọn rí tàbí ká kúkú sọ pé wọn kì í gbàgbé.” Dókítà Karen McComb ti Yunifásítì Sussex, ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì gba ìró ohùn jẹ́jẹ́ tí àwọn abo erin ilẹ̀ Áfíríkà fi máa “ń pe ara wọn” sílẹ̀ ní Ọgbà Ẹranko Amboseli ní Kẹ́ńyà, ó sì kíyè sí àwọn erin tó máa ń pàdé pọ̀ déédéé àtàwọn tó jẹ́ àjèjì ara wọn. Lẹ́yìn náà ló wá fi kásẹ́ẹ̀tì tó gba ìpè wọn sí sínú rédíò fún àwọn ìdílé erin mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n láti gbọ́ àti láti wo bí wọ́n ṣe máa ṣe. Táwọn ẹranko náà bá mọ ẹni tó pè wọ́n dáadáa, kíá ni wọ́n máa dáhùn padà. Tó bá jẹ́ pé wọn kò fi bẹ́ẹ̀ mọ ẹni tó pè wọ́n, wọ́n á tẹ́tí sílẹ̀ àmọ́ wọn ò ní dáhùn, ohùn tí wọn ò bá mọ̀ rárá máa ń kó ṣìbáṣìbo bá wọn tí wọ́n á sì múra láti jà. Àpilẹ̀kọ náà sọ pé: “Wọ́n lè fi ohùn dá àwọn mẹ́ńbà ìdílé erin mẹ́rìnlá míì ó kéré tán mọ̀, èyí tó ń fi hàn pé erin kan lè rántí nǹkan bí ọgọ́rùn-ún erin tó ti dàgbà.” Àwọn erin tún lè rántí àwọn èèyàn pẹ̀lú. John Partridge, tó jẹ́ alábòójútó àwọn ẹranko afọ́mọlọ́mú ní Ọgbà Ẹranko Bristol ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé, erin kan tó wá láti ilẹ̀ Éṣíà tóun bá ṣiṣẹ́ fún ọdún méjìdínlógún ṣì dá òun mọ̀ nígbà tóun padà dé lẹ́yìn tóun ti lọ fún ọdún mẹ́ta.

Àwọn Onífàyàwọ́ Oògùn Líle Tó Ń Lo Ọgbọ́n Iṣẹ́ Ẹ̀rọ Gíga

Láyé ọjọ́un, inú ọkọ̀ òfuurufú àti inú ọkọ̀ òkun akérò làwọn onífàyàwọ́ ní Kòlóńbíà máa ń kó oògùn líle pamọ́ sí. Àmọ́, lẹ́nu àìpẹ́ yìí, háà ṣe àwọn aláṣẹ láti rí i pé àwọn onífàyàwọ́ ń ṣe ọkọ̀ kan tó lè rìn lábẹ́ òkun tí ọgbọ́n iṣẹ́ ẹ̀rọ rẹ̀ díjú, tí ohun tí wọ́n sì lò fún ara rẹ̀ jẹ́ ìlọ́po méjì, ó gùn ju mítà mẹ́ta lọ ní ìbú ó sì lè kó nǹkan bí igba tọ́ọ̀nù oògùn kokéènì. Àwọn aládùúgbò tó fura ló mú àwọn ọlọ́pàá lọ sí “ilé ẹrù kan lóde ìlú Bogotá, tó jẹ́ ẹ̀ẹ́dégbèjìlá [2,300] mítà sí òkè Andes, tó sì fi ọ̀ọ́dúnrún kìlómítà jìnnà sí èbúté èyíkéyìí,” gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn The New York Times ti sọ. “Ńṣe ni ọkọ̀ tó gùn ní ọgbọ̀n mítà náà ì bá kàn gba orí okun kan kọjá, tí ì bá pẹ́ Miami tàbí àwọn ìlú míì tó wà létíkun sílẹ̀, táa sì lọ já ẹrù oògùn líle tó gbé láìjẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ò ká ẹnì kankan mọ́bẹ̀ tàbí rí ẹnikẹ́ni gbá mú, wọ́n ronú pé ó ní láti jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ọ̀daràn ilẹ̀ Rọ́ṣíà àti ti Amẹ́ríkà, pẹ̀lú ẹnjiníà kan tó jáfáfá nínú ìmọ̀ ẹ̀rọ ọkọ̀ abẹ́ òkun. Àwọn aláṣẹ sọ pé, ó ní láti jẹ́ ọkọ̀ kan tó dà bí tírélà ló gbé ọkọ̀ abẹ́ òkun náà wá sí etíkun ní ìpín mẹ́ta. Ó yà wọ́n lẹ́nu láti rí itú tàwọn onífàyàwọ́ oògùn líle ń pa láti lè kó ọjà wọn kọjá.

Ọkàn Àwọn Ẹranko Balẹ̀ ní DMZ

Ìwé ìròyìn The Wall Street Journal sọ pé: “Látìgbà tí wọ́n ti dá DMZ [Àyíká Tógun Ò Gbọ́dọ̀ Jà] sílẹ̀ lẹ́yìn tí Ogun Kòríà parí ní 1953, àwọn ìgbésẹ̀ ààbò tí wọ́n gbé ti mú kí àyíká àdánidá yìí àtàwọn àgbègbè tó yí i ká wà láìsí ìyọnu. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdàgbàsókè ọrọ̀ ajé ti ba èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ilẹ̀ tó wà níbòmíràn ní ilẹ̀ Kòríà méjèèjì jẹ́, ẹnubodè yìí ti di ibi ààbò tó ṣe pàtàkì jù lọ ní orílẹ̀-èdè náà fún àwọn ẹranko.” Ó ti di ilé àwọn ẹyẹ àtàwọn ẹranko tó ṣọ̀wọ́n àtàwọn tí a ń wu léwu. Ó tún dà bíi pé àwọn ẹkùn àti àmọ̀tẹ́kùn wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Àwọn onímọ̀ nípa àyíká ti wá ń ṣàníyàn báyìí nípa akitiyan àlàáfíà tó ń lọ lọ́wọ́ láàárín Àríwá àti Gúúsù Kòríà pé ó lè pa DMZ tó jẹ́ ibi ààbò fún àwọn ẹranko náà run. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n ti ní kí wọ́n fún wọn ní “ọgbà ẹranko kan tí wọn ò gbọ́dọ̀ pa ẹran ibẹ̀” láti lè dáàbò bo àwọn ẹran ìgbẹ́ ibẹ̀ kí wọ́n sì fún àwọn ẹran ìhà méjèèjì láyè láti jọ máa gùn. Ìwé ìròyìn Journal náà sọ pé: “Ohun tó dá àwọn onímọ̀ nípa àyíká náà lọ́kàn le ni ìgbàgbọ́ pé tí àlááfíà bá wà, ó lè ṣèrànwọ́ láti mú ìṣọ̀kan wà láàárín àwọn ẹranko yìí lọ́nà kan náà tí wíwà ní àlááfíà fi mú àwọn mẹ́ńbà ìdílé tó ti pínyà tipẹ́ tún wà papọ̀.”

Kò Rọrùn Láti Ṣíwọ́ fún Oúnjẹ Ọ̀sán

Ìwé ìròyìn Financial Times ti London sọ pé: “Àwọn ahẹrẹpẹ èèyàn ló ń ráyè fún oúnjẹ ọ̀sán ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tí kò gba gbẹ̀rẹ́, bí àwọn òṣìṣẹ́ tó ń ṣe àṣekúdórógbó iṣẹ́ ti ń pa oúnjẹ ọ̀sán tì tí wọ́n sì ń fi jíjẹ ìpápánu nídìí iṣẹ́ rọ́pò rẹ̀.” Ìwádìí àìpẹ́ yìí fi hàn pé ìṣẹ́jú mẹ́rìndínlógójì péré lọ̀pọ̀ ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ń lò báyìí fún “wákàtí oúnjẹ ọ̀sán.” Àwọn ògbógi oníṣègùn sọ pé ìsinmi ọ̀sán máa ń dín másùnmáwo kù. Àmọ́ àkókò oúnjẹ ọ̀sán làwọn agbanisíṣẹ́ kan máa ń fi ìpàdé sí, tí kò sì ní sí ìsinmi rárá fáwọn òṣìṣẹ́. Àjọ aṣèwádìí tó kó ìròyìn náà jọ sọ pé: “Bí ọ̀pọ̀ ti bára wọn nínú àwùjọ kan tó ń fẹ́ káwọn òṣìṣẹ́ sáà máa ṣiṣẹ́ ṣáá tó sì ka àkókò sí nǹkan iyebíye, wọ́n ti wá ń fojú wo ṣíṣíwọ́ fún oúnjẹ ọ̀sán bí ohun kan tí kò rọrùn.” Sarah Nunny tó ń ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ ìwádìí náà fi kún un pé: “A ń bára wa díje ní ọjà àgbáyé. Kò tún ṣeé ṣe mọ́ láti sọ pé, ‘màá ṣe é tó bá yá.’ Mo gbọ́dọ̀ ṣe é nísinsìnyí ló kù.”

Tábà Mímu Di Bára Kú Ní Mẹ́síkò

Gẹ́gẹ́ bí apá kan ìtòlẹ́sẹẹsẹ láti ṣèdíwọ́ fún sísọ tábà mímu di bára kú ní Mẹ́síkò àti kíkápá rẹ̀, José Antonio González Fernández tó jẹ́ Akọ̀wé Ìjọba fún Ètò Ìlera nígbà kan sọ pé, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín méjìdínlọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ará Mẹ́síkò tó ń mu sìgá. Ohun tó wá jẹ́ olórí àníyàn wọn ni pé, iye tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn amusìgá yìí ló jẹ́ àwọn tó wà lọ́jọ́ orí ọdún méjìlá sí mẹ́tàdínlógún. Ọ̀gbẹ́ni González sọ pé ikú méjìlélọ́gọ́fà tí wọ́n fojú díwọ̀n pé ó ń ṣẹlẹ̀ lójúmọ́ ní Mẹ́síkò tan mọ́ tábà mímu. Ó dárò “iye ribiribi tí eléyìí dúró fún nínú ìdàgbàsókè ètò ọrọ̀ ajé orílẹ̀-èdè náà, ìyẹn pípàdánù àwọn ọdún tó yẹ kí ẹ̀dá fi ṣe nǹkan nínú ìgbésí ayé, . . . àti ewu táwọn tó ń mu sìgá láyìíká wa kó wa sí.”

Ṣé Ìyẹn Ni Ojútùú sí Àìní Tẹ̀mí?

Ìwé ìròyìn Globe and Mail ti Kánádà sọ pé, “wẹ́kú lèrò àwùjọ kan tó ti pa ètò ẹ̀sìn tì” ri pẹ̀lú gbígbilẹ̀ táwọn tó ń gbé níní ìgbọ́kànlé nínú ara ẹni lárugẹ, mímọ báa ti ń ronú lọ́nà tó tọ́ àti àṣeyọrí ara ẹni túbọ̀ ń gbilẹ̀ sí i. “Ó wu àwọn èèyàn gan an láti jẹ́ ẹni tẹ̀mí, àmọ́ ńṣe ni ìfẹ́ wọn nínú ibi tí wọ́n mọ̀ pé àwọ́n ti lè rí i túbọ̀ ń dín kù sí i.” Ìwádìí fi hàn pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìpín ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ará Kánádà ló sọ pé àwọn gba Ọlọ́run gbọ́, ìpín méjìlélógún nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó pera wọn ní Kristẹni lo ka ohun táwọn fúnra wọn gbà gbọ́ sí pàtàkì ju ohun tí ṣọ́ọ̀ṣì èyíkéyìí lè fi kọ́ni lọ. Ìwé ìròyìn Globe pe ipò tẹ̀mí ti àwọn tí wọ́n sọ pé èèyàn lè ran ara rẹ̀ lọ́wọ́ ní “ohun kan tó máa túbọ̀ fún ẹ níṣìírí láti máa bá a lọ ní lílépa àṣeyọrí ara ẹni kiri.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́