Wá sí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ìgbàgbọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run”!
ÀRÀÁDỌ́TA ọ̀kẹ́ yóò pésẹ̀ sí ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọ̀gangan àpéjọpọ̀ jákèjádò ayé. Ní Nàìjíríà nìkan, a ṣètò 110 àpéjọpọ̀. Àkọ́kọ́ yóò jẹ́ ní October 10 sí 12, 1997, èyí tí ó kẹ́yìn yóò sì jẹ́ ní January 16 sí 18, 1998. Ó ṣeé ṣe kí ọ̀kan nínú àwọn àpéjọ ọlọ́jọ́ mẹ́ta wọ̀nyí—Friday sí Sunday—wáyé ní ìlú kan tí kò jìnnà sí ilé rẹ.
Ìwọ yóò jàǹfààní láti inú ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìtọ́ni Bíbélì gbígbéṣẹ́. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà yóò bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú orin ní òwúrọ̀ Friday, ní agogo 9:20. Ní Saturday àti Sunday, ìtòlẹ́sẹẹsẹ yóò bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú orin lóròòwúrọ̀ ní agogo 9:00. Fífọ̀rọ̀ wá àwọn ènìyàn tí ìgbàgbọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti ní ipa jíjinlẹ̀ lórí ìgbésí ayé wọn lẹ́nu wò yóò wáyé fún ìṣẹ́jú 25 ní òwúrọ̀ Friday. Àkókò ìjókòó àkọ́kọ́ yẹn yóò parí pẹ̀lú lájorí ọ̀rọ̀ àsọyé náà, “Nípa Ìgbàgbọ́ Ni A Ń Rìn, Kì í Ṣe Nípa Ohun Tí A Rí.”
Ọ̀rọ̀ àsọyé àkọ́kọ́ ní ọ̀sán Friday yóò gbé ipa pàtàkì tí àwọn èwe ń kó nínú ìjọ Kristẹni yẹ̀ wò. Àpínsọ àsọyé alápá mẹ́ta tí ó tẹ̀ lé e yóò jíròrò bí ọ̀pá ìdiwọ̀n Bíbélì ṣe kan ọ̀nà tí ó yẹ kí Kristẹni gbà hùwà, sọ̀rọ̀, àti bí ìmúra rẹ̀ ṣe yẹ kí ó rí. Ọ̀rọ̀ àsọyé tí ó tẹ̀ lé e, “Ẹ Ṣọ́ra fún Àìní Ìgbàgbọ́” àti “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Wà Láàyè” yóò darí àfiyèsí sí ìṣílétí rere tí ń bẹ nínú Hébérù orí 3 àti 4. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Friday yóò wá sí ìparí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àwíyé náà, “Ìwé Kan fún Gbogbo Ènìyàn.”
“Ìgbàgbọ́ Láìsí Iṣẹ́ Jẹ́ Òkú” ni ọ̀rọ̀ àsọyé àkọ́kọ́ ní òwúrọ̀ Saturday. Ọ̀rọ̀ àwíyé pàtàkì míràn ní òwúrọ̀ ọjọ́ yẹn, “Ẹ Ta Gbòǹgbò Kí Ẹ sì Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Nínú Òtítọ́,” yóò ṣàlàyé bí a ṣe lè dàgbà sókè nípa tẹ̀mí. Àkókò ìjókòó náà yóò parí pẹ̀lú ohun tí ó sábà máa ń wáyé ní àpéjọpọ̀, “Ìgbàgbọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Ṣamọ̀nà sí Batisí,” lẹ́yìn èyí tí ètò yóò wà fún àwọn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọmọ ẹ̀yìn láti ṣe batisí.
Ọ̀rọ̀ ìṣípàdé ní ọ̀sán Saturday, “Ẹ Máa Ja Ìjà Líle fún Ìgbàgbọ́,” yóò ṣàlàyé ìṣílétí ìwé Bíbélì náà, Júúdà. Àpínsọ ọ̀rọ̀ àsọyé oníwákàtí kan tí a pe àkòrí rẹ̀ ní “Ẹ Jẹ́ Kí A Lọ sí Ilé Jèhófà” yóò gbé àwọn àǹfààní ìpàdé Kristẹni yẹ̀ wò. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ yóò wá sí ìparí ní ọjọ́ náà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àwíyé náà, “Ìjójúlówó Ìgbàgbọ́ Rẹ—A Ń Dán An Wò Nísinsìnyí.”
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ òwúrọ̀ Sunday yóò ní àpínsọ ọ̀rọ̀ àsọyé alápá mẹ́ta kan tí yóò ṣàlàyé ìwé Bíbélì náà, Jóẹ́lì, títí kan bí ó ṣe kàn wá ní ọjọ́ wa. Lẹ́yìn náà ni àwòkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tí a pe àkòrí rẹ̀ ní “Ẹ Jẹ́ Kí Ojú Yín Mú Ọ̀nà Kan” yóò tẹ̀ lé e. Kókó pàtàkì àpéjọpọ̀ náà ni ọ̀rọ̀ àwíyé fún gbogbo ènìyàn ní ọ̀sán, “Ìgbàgbọ́ àti Ọjọ́ Ọ̀la Rẹ.”
Dájúdájú, wíwà níbẹ̀ rẹ yóò mú kí a bù kún ọ nípa tẹ̀mí. A óò fi tayọ̀tayọ̀ kí ọ káàbọ̀ sí àkókò ìjókòó kọ̀ọ̀kan. Ṣètò nísinsìnyí láti wà níbẹ̀. Láti mọ ọ̀gangan tí ó sún mọ́ ilé rẹ jù lọ, kàn sí Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ó wà ládùúgbò rẹ tàbí kí o kọ̀wé sí àwọn tí ń ṣe ìwé ìròyìn yí jáde. O tún lè rí àdírẹ́sì àwọn ọ̀gangan àpéjọpọ̀ ní Nàìjíríà nínú ìtẹ̀jáde Jí! June 8.