Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́” ti 1998 sí 1999 Ti Sún Mọ́lé!
NÍ NÀÌJÍRÍÀ nìkan, 108 àpéjọpọ̀ ni a ṣètò pé yóò wáyé ní October 1998 sí January 1999. Ó ṣeé ṣe kí a ṣe ọ̀kan nínú àwọn àpéjọ ọlọ́jọ́ mẹ́ta wọ̀nyí ní ìlú kan tí kò jìnnà sí ilé rẹ. Ní ibi tí ó pọ̀ jù lọ, ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà yóò bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú orin lọ́jọ́ Friday ní agogo 9:30 òwúrọ̀. Lọ́jọ́ Saturday àti Sunday, agogo 9:00 òwúrọ̀ gééré ni ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà yóò bẹ̀rẹ̀.
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ òwúrọ̀ Friday yóò gbé ìròyìn nípa ìtẹ̀síwájú ìwàásù Ìjọba náà ní onírúurú ibi lágbàáyé jáde. Lájorí ọ̀rọ̀ àwíyé yóò sì tẹnu mọ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ àpéjọpọ̀ náà, “Ìràpadà Kristi—Ọ̀nà Ọlọ́run fún Ìgbàlà.”
Lọ́sàn-án, àpínsọ ọ̀rọ̀ àsọyé náà, “Ẹ̀yin Òbí—Ẹ Gbin Ọ̀nà Ọlọ́run Sínú Àwọn Ọmọ Yín,” yóò pèsè ìmọ̀ràn lórí bí a ṣe lè ru àwọn èwe sókè láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kí wọ́n sì sìn ín. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọ̀sán yóò parí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àsọyé náà, “Ìwàláàyè Ha Wà Lẹ́yìn Ikú Bí?”
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ òwúrọ̀ Saturday yóò sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe, ní apá mẹ́ta oníṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé, “Ríran Àwọn Ènìyàn Lọ́wọ́ Láti Rin Ọ̀nà Ìyè,” “Ìpèníjà Dídé Ọ̀dọ̀ Àwọn Ènìyàn,” àti “Kíkọ́ Àwọn Ọmọ Ẹ̀yìn Ní Gbogbo Ohun Tí Kristi Pa Láṣẹ.” Nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ òwúrọ̀ bá parí, ètò yóò wà fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun láti ṣe batisí.
Ọ̀rọ̀ àsọyé àkọ́kọ́ lọ́sàn-án Saturday, “Sísìn Pẹ̀lú Ìyè Àìlópin Lọ́kàn,” yóò fún gbígbàdúrà nípa ìdí tí a fi ń sin Ọlọ́run níṣìírí. Àwọn ọ̀rọ̀ àsọyé náà, “Mímọyì Àwọn Ẹ̀bùn Nínú Ènìyàn Tí Ń Kọ́ni Ní Ọ̀nà Ọlọ́run” àti “Àkópọ̀ Ìwà—Bọ́ Ti Ògbólógbòó Sílẹ̀, Kí O Sì Gbé Tuntun Wọ̀,” yóò gbé ṣíṣàyẹ̀wò Éfésù orí 4 kalẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ lọ́nà tí ń lani lóye. Bí ìyẹn bá ti ń parí, ọ̀rọ̀ àsọyé náà, “Pa Ara Rẹ Mọ́ Láìní Èérí Kúrò Nínú Ayé” àti àpínsọ ọ̀rọ̀ àsọyé alápá mẹ́ta náà, “Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ Tẹ̀ Lé Ọ̀nà Ọlọ́run,” yóò pèsè ìṣílétí àtàtà tí a gbé ka Ìwé Mímọ́. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọ̀sán yóò parí pẹ̀lú àsọyé náà, “Ẹlẹ́dàá Náà—Àkópọ̀ Ìwà Rẹ̀ àti Ọ̀nà Rẹ̀.”
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ òwúrọ̀ Sunday yóò gbé àpínsọ ọ̀rọ̀ àsọyé alápá mẹ́ta kan kalẹ̀, tí yóò jíròrò àwọn orí tí ó gbẹ̀yìn ìwé Ìsíkíẹ́lì inú Bíbélì àti ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ wọn. Àwòkẹ́kọ̀ọ́ ti ìgbàanì tí ó dá lórí ìṣòtítọ́ àwọn ọ̀dọ́ Hébérù mẹ́ta ni yóò kásẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ òwúrọ̀ nílẹ̀. Pàtàkì àpéjọpọ̀ náà lọ́sàn-án ni àwíyé fún gbogbo ènìyàn náà, “Ọ̀nà Kan Ṣoṣo sí Ìyè Àìnípẹ̀kun.”
Dájúdájú, a óò bù kún ọ nípa tẹ̀mí bí o kó bá pa ọjọ́ kan jẹ́ nínú gbogbo ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. A fi tìfẹ́tìfẹ́ pè ọ́ sí gbogbo àkókò ìjókòó, ọ̀fẹ́ ni, kò ṣẹ̀ṣẹ̀ láà ń sọ ọ́. Láti mọ ibi tí ó sún mọ́ ilé rẹ jù lọ, kàn sí Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ó wà ládùúgbò rẹ tàbí kí o kọ̀wé sí àwọn tí ń ṣe ìwé ìròyìn yìí jáde.