Ìdí Tí Àwọn Ilé Ìjọsìn Fi Ń kógbá Sílé
ÀWỌN ṣọ́ọ̀ṣì, ilé ìjọsìn, ẹgbẹ́ akọrin, àti èédú—ní ìwọ̀nba 50 ọdún péré sẹ́yìn, wọ́n jẹ́ àmì gidi tí ń fi hàn pé o wà ní àwọn àfonífojì ìwakùsà ní Gúúsù Wales. Ó jọ pé ní gbogbo ọgọ́rọ̀ọ̀rún mítà, ìwọ yóò rí yálà ilé ìjọsìn Baptist tí wọ́n ti ń sọ ède Welsh tàbí Gẹ̀ẹ́sì tàbí èyí tí ó bá a dọ́gba, tí ó jẹ́ fún àwọn Mẹ́tọ́díìsì, Mẹ́tọ́díìsì ti Calvin, Congregational, Presbyterian, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé èdè orílẹ̀-èdè wọn ni ọ̀pọ̀ lára àwọn ènìyàn Wales ń sọ, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ìsìn kọ̀ọ̀kan ló ní ilé ìjọsìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fún èdè kọ̀ọ̀kan. Tẹlifíṣọ̀n àti ìlànà tí ń yí padà ti yí gbogbo iyẹn padà láàárín ẹ̀wádún márùn-ún tí ó ti wà.
Islwyn Jones, ọmọ ilẹ̀ Wales, tí ń gbé Blaenclydach ní Àfonífojì Rhondda, ti lo ọ̀pọ̀ ọdún ní ṣíṣàkọsílẹ̀ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tí ń ṣẹlẹ̀ sí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ilé ìjọsìn ní Rhondda. Ìwé ìròyìn àdúgbò náà, Rhondda Leader, tẹ àwọn ilé ìjọsìn tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún, tí ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọ́n ti wà láti ọ̀rúndún kọkàndínlógún, jáde, ó sì tọ́ka sí ipò tí wọ́n wà ní lọ́ọ́lọ́ọ́. Ìròyìn náà sọ pé: “Àwọn ilé ńláńlá yìí jẹ́ apá pàtàkì ní Rhondda bí ó ti ń la àwọn ọdún ìbúrẹ́kẹ́ èédú já títí dé ìgbà tí àwọn ìpìlẹ̀ méjèèjì wọ̀nyí [ìsìn àti èédú] tí ń gbé ẹ̀mí ró ní àfonífojì náà fi jó rẹ̀yìn pátápátá.”
Àkọsílẹ̀ náà ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dàyà ìwólulẹ̀ ipa tí ìsìn ń ní, kì í ṣe ní Wales nìkan ṣùgbọ́n ní apá ibi púpọ̀ ní ilẹ̀ Europe. A ṣàkọsílẹ̀ pé àwọn ilé ìjọsìn 68 ni a ti “wó palẹ̀ nísinsìnyí.” A ti yí ìlo 19 padà sí ṣíṣe àwọn ohun mìíràn. Àwọn àpẹẹrẹ nìyí: “a yí i padà sí ilé ẹ̀kọ́ ọ̀nà ìgbèjà ara ẹni ti Aikido,” “a yí i padà sí ilé àdágbé [ilé gbéetán],” “a yí i padà sí ilé ẹrù,” “a sọ ọ́ di ibi ìtajà,” “a sọ ọ́ di ilé ìtajà egbòogi.” Ọ̀kan tí a kò kọ sílẹ̀, tí ó wà ní Penygraig, ni a yí padà sí Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, fún ìlò Ìjọ Rhondda tí ń gbèrú sí i.
Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀ nípa “Bábílónì Ńlá,” ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé, àwọn omi ìṣàpẹẹrẹ rẹ̀, ìtìlẹ́yìn àwọn ènìyàn, ti ń gbẹ ní àwọn apá ibi púpọ̀ lágbàáyé. Láìpẹ́, àwọn ìsọ̀rí àwùjọ olóṣèlú àgbáyé yóò dojú ìjà kọ ìsìn bí wọ́n ti ń “mú ìrònú [Ọlọ́run] ṣẹ” láti pa ìsìn èké, tí ó ti sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ Jèhófà Ọlọ́run àti ète rẹ̀, run.—Ìṣípayá 17:5, 15-17.a
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ìsọfúnni kíkún nípa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí Bábílónì Ńlá, wo ìwé náà Revelation—Its Grand Climax At Hand!, ojú ewé 258 sí 266, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ṣe jáde.