Ṣíṣe Isin Mimọgaara fun Lilaaja
“Isin ti ó mọ́ gaara ti ó sì jẹ́ ojulowo ni oju Ọlọrun Baba yoo fi ara rẹ han nipa iru awọn nǹkan bii . . . pipa ara ẹni mọ lailabaawọn nipasẹ aye.”—JAKOBU 1:27, Phillips.
1. Bawo ni a ṣe tumọ isin, ta ni ó sì ni ẹtọ lọna ti ó bọgbọn ironu mu lati pinnu iyatọ laaarin isin èké ati ti otitọ?
ISIN ni a ti tumọ bii “ifihan igbagbọ eniyan ninu ati ọ̀wọ̀-ńlá fun agbara ti ó ju ti ẹ̀dá lọ ti a mọ dunju gẹgẹ bii ẹlẹdaa ati oluṣakoso agbaye.” Ta ni, nigba naa, lọna ti ó ba ọgbọn ironu mu ni ó ni ẹtọ naa lati pinnu iyatọ laaarin isin tootọ ati isin èké? Dajudaju o gbọdọ jẹ́ Ẹni naa ti a gbagbọ ninu rẹ̀ ti a sì bọwọ fun, Ẹlẹdaa naa. Jehofa la ipo rẹ̀ nipa isin tootọ ati èké lẹsẹẹsẹ ni kedere ninu Ọrọ rẹ̀.
Ọrọ Naa “Isin” Ninu Bibeli
2. Bawo ni awọn iwe atumọ èdè ṣe ṣalaye ọrọ Giriiki ipilẹṣẹ naa ti a tumọsi “iru ijọsin” tabi “isin,” si iru awọn ijọsin wo ni a sì lè fi wọn silo fun?
2 Ọrọ Giriiki naa ti a tumọsi “iru ijọsin,” tabi “isin,” ni thre·skeiʹa. Iwe atumọ èdè naa A Greek-English Lexicon of the New Testament tumọ ọrọ yii bii “ijọsin Ọlọrun, isin, paapaa julọ bi o ti ṣe ṣalaye araarẹ ninu ààtò isin tabi isin-awo.” Iwe Theological Dictionary of the New Testament pese kulẹkulẹ siwaju sii, ni wiwi pe: “Ipilẹṣẹ ọrọ naa ni a jiyan lé lori; . . . awọn ọmọwe ode-oni gbè sẹhin isopọ kan pẹlu therap- (‘lati ṣiṣẹsin’). . . . Iyatọ ninu itumọ ni a lè ṣakiyesi pẹlu. Oye itumọ rere naa jẹ́ ‘itara isin’ . . . , ‘ijọsin Ọlọrun,’ ‘isin.’ . . . Ṣugbọn itumọ buburu kan wà pẹlu, iyẹn ni pe, ‘àṣerégèé isin,’ ‘ijọsin ti ó ṣaitọ.’” Nipa bayii, thre·skeiʹa ni a lè tumọ si yálà “isin” tabi “iru ijọsin,” rere tabi buburu.
3. Bawo ni apọsiteli Pọọlu ṣe lo ọrọ naa ti a tumọsi “iru ijọsin,” ki sì ni ilohunsi arunilọkansoke ti a ṣe lori itumọ Kolose 2:18?
3 Ọrọ yii farahan nigba mẹrin ninu Iwe mimọ Kristẹni lede Giriiki. Apọsiteli Pọọlu lo o lẹẹmeji lati duro fun isin èké. Ni Iṣe 26:5, (NW) oun ni a kọ ọrọ rẹ silẹ pe o sọ pe ṣaaju ki oun tó di Kristẹni kan, “gẹgẹ bi iru ijọsin wa ti ó lekoko julọ [“isin,” Phillips] mo ngbe gẹgẹ bii Farisi.” Ninu lẹta rẹ si awọn ara Kolose, oun kilọ pe: “Ẹ maṣe jẹ́ ki eniyan kankan fi ẹbun eré-ìje naa dù yin, ẹni ti nṣe inudidun ninu irẹlẹ ọkan ẹlẹ́yà ati iru ijọsin awọn angẹli.” (Kolose 2:18, NW) Iru ijọsin angẹli bẹẹ lọna ti ó han gbangba gbalẹ kaakiri ni Phrygia ni awọn ọjọ wọnni, ṣugbọn ó jẹ́ iru ijọsin èké kan.a Lọna ti ó muni lọkan yọ̀, nigba ti o jẹ́ pe awọn olutumọ Bibeli kan tumọ thre·skeiʹa si “isin,” ni Kolose 2:18 ọpọ julọ lo ọrọ naa “ijọsin.” Bibeli New World Translation fi iṣedeedee tumọ thre·skeiʹa “iru ijọsin,” alaye ẹsẹ iwe ninu Reference Bible mẹnukan an nigba gbogbo pe itumọ afirọpo naa “isin” ni a lo ninu awọn ẹ̀dà ti Latin.
“Mímọ́ ati Aláìléèérí” Ni Oju-iwoye Ọlọrun
4, 5. (a) Gẹgẹ bi Jakọbu ti wi, ipo ta ni ó ṣe pataki julọ lori isin? (b) Ki ni ó lè mu iru ijọsin ẹnikan jẹ́ òtúbáńtẹ́, ki sì ni ohun ti a nilọkan nipa ọrọ naa ti a tumọsi “òtúbáńtẹ́”?
4 Ifarahan meji yooku ti ọrọ naa thre·skeiʹa jẹ́ ninu lẹta ti a kọ lati ọwọ ọmọlẹhin naa Jakọbu, mẹmba ẹgbẹ oluṣakoso ti ijọ Kristẹni ọrundun kìn-ín-ní. Oun kọwe pe: “Bi ọkunrin eyikeyii ba dabi olujọsin gẹgẹ bi aṣa loju araarẹ [“lati jẹ ‘onisin,’” Phillips] sibẹ ti kò sì kó ahọ́n rẹ̀ nijaanu, ṣugbọn ti o nbaa lọ ni titan ọkan-aya araarẹ̀ jẹ, iru ijọsin ọkunrin yii [“isin,” Phillips] jẹ́ òtúbáńtẹ́. Iru ijọsin [“isin,” Phillips] mimọ ati alaileeeri lati oju-iwoye Ọlọrun ati Baba wa ni eyi: lati bojuto awọn ọmọ aláìlóbìí ati awọn opó ninu ipọnju wọn, ati ki ẹnikan pa araarẹ mọ́ laini abaawọn kuro ninu ayé.”—Jakobu 1:26, 27, NW.
5 Bẹẹni, kikiyesi ipo Jehofa lori isin ṣekoko bi awa ba fẹ lati ni itẹwọgba rẹ̀ ki a sì laaja sinu aye titun naa ti oun ti ṣeleri. (2 Peteru 3:13) Jakọbu fihan pe ó lè dabii pe ẹnikan jẹ́ onisin nitootọ loju araarẹ ati sibẹsibẹ iru ijọsin rẹ lè jẹ́ òtúbáńtẹ́. Ọrọ Giriiki naa ti a tumọ nihin-in si “òtúbáńtẹ́” tun tumọsi “alaiṣiṣẹ, asan, alaileso, alainilaari, alailagbara, alaini otitọ.” Eyi le jẹ́ ọran naa bi ẹnikan ti ó sọ pe oun jẹ́ Kristẹni kan kò ba kó ahọ́n rẹ̀ nijaanu ki ó sì lo o lati yin Ọlọrun ati lati gbe awọn Kristẹni ẹlẹgbẹ rẹ̀ ró. Oun yoo maa “tan ọkan-aya araarẹ̀ jẹ” ti ki yoo sì maa ṣe “isin ti ó mọgaara ati ojulowo ni oju Ọlọrun.” (Phillips) Oju-iwoye Jehofa ni ó ṣe pataki.
6. (a) Ki ni ẹṣin ọrọ lẹta naa lati ọwọ Jakọbu? (b) Ki ni ohun ti a beere fun ijọsin mimọgaara ti Jakọbu tẹnumọ, ki sì ni ohun ti Ẹgbẹ Oluṣakoso tòní sọ nipa eyi?
6 Jakọbu kò ka gbogbo ohun ti Jehofa nbeere ni isopọ pẹlu ijọsin mimọgaara. Ni ìlà pẹlu ẹṣin ọrọ lẹta rẹ̀ lapapọ, eyi ti ó jẹ́ igbagbọ ti a fihan nipasẹ awọn iṣẹ ati aini naa lati ya araawa sọtọ patapata kuro ninu ibadọrẹẹ pẹlu aye Satani, oun tẹnumọ kiki ohun abeere fun meji. Ọkan jẹ “lati bojuto awọn ọmọ aláìlóbìí ati awọn opó ninu ipọnju wọn.” Eyi mu ifẹ Kristẹni tootọ lọwọ. Jehofa ti fi igba gbogbo fi aniyan onifẹẹ rẹ̀ han fun awọn alaini baba ati opo. (Deutaronomi 10:17, 18; Malaki 3:5) Ọkan ninu awọn igbesẹ akọkọ ti ẹgbẹ oluṣakoso ọrundun kìn-ín-ní ti ijọ Kristẹni jẹ́ nitori awọn opo Kristẹni. (Iṣe 6:1-6) Apọsiteli Pọọlu funni ni kulẹkulẹ itọni fun pipese abojuto onifẹẹ fun awọn agbalagba opó ti wọn jẹ́ otoṣi ti wọn ti fi araawọn han ni oluṣotitọ fun ọpọ ọdun ti wọn kò sì ni idile eyikeyii lati ran wọn lọwọ. (1 Timoti 5:3-16) Ẹgbẹ Oluṣakoso awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ode-oni lọna kan naa ti mu awọn itọni pato jade lori “Titọju Awọn Alaini,” ni ṣiṣalaye pe: “Ijọsin tootọ wémọ́ titọju awọn eniyan oloootọ ati olododo tí wọn lè fẹ́ iranwọ nipa ti ara.” (Wo iwe Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa, oju-iwe 122 si 123.) Ẹgbẹ awọn alagba tabi Kristẹni kọọkan ti wọn fi araawọn han bi alaibikita ni ìhà yii ngbojufo apa pataki kan dá ninu iru ijọsin ti ó mọ́ ti ó sì jẹ́ aláìléèérí ni oju-iwoye Baba ati Ọlọrun wa.
“Laisi Abaawọn Kuro Ninu Ayé”
7, 8. (a) Ki ni ohun keji ti a beere fun isin tootọ ti Jakọbu mẹnukan? (b) Njẹ ẹgbẹ alufaa ati awọn alufaa ha dójú ohun ti a beere fun yii bi? (c) Ki ni ohun ti a lè sọ nipa awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa?
7 Ohun abeere fun keji fun isin tootọ ti Jakọbu mẹnukan jẹ́ “ki ẹnikan pa araarẹ mọ́ laini abaawọn kuro ninu ayé.” Jesu sọ pe: “Ijọba mi kii ṣe ti aye yii”; lọna ti ó ṣe deedee, awọn ọmọlẹhin rẹ̀ tootọ ki yoo jẹ́ “apakan aye.” (Johanu 15:19, NW; 18:36) Njẹ a lè sọ eyi nipa ẹgbẹ alufaa ati awọn alufaa eyikeyii ninu awọn isin ayé yii bi? Wọn tẹwọgba Iparapọ Awọn Orilẹ-ede. Ọpọ ninu awọn aṣaaju wọn tẹwọgba ikesini Poopu lati pade ni Assisi, Italy, ni October 1986 lati pa awọn adura wọn pọ ṣọkan fun aṣeyọri si rere “Ọdun Alaafia Agbaye” tí Iparapọ Awọn Orilẹ-ede ṣagbatẹru rẹ̀. Bi o ti wu ki o ri, isapa wọn jasi asan, bi a ba gbe e yẹwo loju araadọta ọkẹ ti a pa ninu awọn ogun ni ọdun yẹn ati lati awọn ọdun ẹhin ìgbà naa wa. Ẹgbẹ alufaa saba maa nwa ajọṣepọ olojurere pẹlu ẹgbẹ oṣelu ti nṣakoso, nigba ti wọn nfi àdàkàdekè ni ibaṣepọ oníbòókẹ́lẹ́ pẹlu awọn alatako ki ó baa lè jẹ́ pe ẹnikẹni ti ó ba ṣakoso yoo wò wọn gẹgẹ bi “ọrẹ.”—Jakobu 4:4.
8 Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ṣe orukọ rere fun araawọn gẹgẹ bi awọn Kristẹni ti wọn duro laidasi tọtuntosi ninu awọn alaamọri oṣelu ati ninu iforigbari aye yii. Wọn di iduro yii mu ni gbogbo apa ilẹ-aye ati ni gbogbo orilẹ-ede, gẹgẹ bi a ti jẹ́rìí sii nipasẹ awọn irohin awọn ajọ onirohin ati awọn akọsilẹ itan ode-oni ni gbogbo apa aye. Niti tootọ wọn jẹ́ “alailabaawọn kuro ninu ayé.” Tiwọn jẹ́ “isin ti ó mọ́gaara ati ojulowo ni oju Ọlọrun.”—Jakobu 1:27, Phillips.
Awọn Ami Miiran Ti Isin Tootọ
9. Ki ni ohun abeere fun kẹta fun ijọsin tootọ, eesitiṣe?
9 Bi isin bá jẹ́ “ọ̀wọ̀-ńlá fun agbara ti ó ju ti ẹ̀dá lọ ti a mọ daju gẹgẹ bi ẹlẹdaa ati oluṣakoso agbaye,” dajudaju isin tootọ nilati dari ijọsin si Ọlọrun tootọ kanṣoṣo naa, Jehofa. Kò nilati mu òye awọn eniyan nipa Ọlọrun ṣokunkun nipa kíkọ́ wọn ni awọn èròǹgbà oloriṣa iru bii ọlọrun ẹlẹni mẹta ninu eyi ti Baba ti ṣajọpin jijẹ Olodumare, ogo, ati ayeraye rẹ̀ pẹlu awọn ẹni meji miiran ninu Mẹtalọkan olohun ijinlẹ kan. (Deutaronomi 6:4; 1 Kọrinti 8:6) Ó tun gbọdọ sọ orukọ alailafiwe Ọlọrun, Jehofa, di mímọ̀ ki ó sì bọla fun orukọ yẹn, pe niti tootọ ki ó jẹ orukọ Ọlọrun gẹgẹ bi awọn eniyan ti a ṣetojọ. (Saamu 83:18; Iṣe 15:14) Ninu eyi awọn oluṣe isin naa nilati tẹle apẹẹrẹ Jesu Kristi. (Johanu 17:6) Awọn eniyan wo lonii ni wọn doju ohun abeere fun yii ju awọn Kristẹni Ẹlẹ́rìí Jehofa lọ?
10. Fun isin kan lati nawọ lilaaja sinu ayé titun Ọlọrun funni, ki ni ohun ti ó gbọdọ ṣe, eesitiṣe?
10 Apọsiteli Peteru sọ pe: “Kò si igbala lọdọ ẹlomiran: nitori kò si orukọ miiran [Jesu Kristi] labẹ ọrun ti a fifunni ninu eniyan, nipa eyi ti a lè fi gbà wá là.” (Iṣe 4:8-12) Nigba naa isin mimọgaara ti yoo funni ni igbala sinu aye titun Ọlọrun gbọdọ, mu igbagbọ dagba ninu Kristi ati ninu iniyelori ẹbọ irapada naa. (Johanu 3:16, 36; 17:3; Efesu 1:7) Siwaju sii, o gbọdọ ran awọn olujọsin tootọ lọwọ lati juwọsilẹ fun Kristi gẹgẹ bi Ọba Jehofa ti njọba ati Alufaa Agba ti a fami ororo yan.—Saamu 2:6-8; Filipi 2:9-11; Heberu 4:14, 15.
11. Lori ki ni a gbọdọ gbe ijọsin tootọ kà, ki sì ni ipo awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nipa eyi?
11 Ijọsin mimọgaara ni a nilati gbekari ifẹ-inu Ọlọrun tootọ naa ti a ṣipaya kii ṣe lori awọn ẹkọ atọwọdọwọ tabi imọ ọran ti ó ti ọwọ eniyan wá. A kì bá tí mọ ohunkohun nipa Jehofa ati ète agbayanu rẹ̀, tabi nipa Jesu ati ẹbọ irapada naa, bi kii ba ṣe nitori Bibeli. Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ngbin igbọkanle diduro gbọnyin ninu Bibeli sinu awọn eniyan. Wọn sì nfihan pẹlu nipasẹ igbesi-aye ojoojumọ wọn pe wọn fohunṣọkan pẹlu awọn ọrọ apọsiteli Pọọlu pe: “Gbogbo iwe mímọ́ ti o ni imisi Ọlọrun ni ó sì ni èrè fun ẹkọ, fun ibaniwi, fun itọni, . . . ki eniyan Ọlọrun ki ó lè pé, ti a ti murasilẹ patapata fun iṣẹ rere gbogbo.”—2 Timoti 3:16, 17.
Isin Tootọ —Ọna Igbesi-aye Kan
12. Ni afikun si igbagbọ, ki ni ó pọndandan fun ijọsin lati jẹ́ tootọ, ni awọn ọna wo sì ni ijọsin tootọ fi jẹ́ ọna igbesi-aye kan?
12 Jesu polongo pe: “Ẹmi ni Ọlọrun: awọn ẹni ti nsin in kò lè ṣe alaisin in ni ẹmi ati ni otitọ.” (Johanu 4:24) Isin, tabi iru ijọsin tootọ, nitori naa, kii ṣe, aṣefihan sode iwa-bi-Ọlọrun alayẹyẹ, alaato isin. Ijọsin mimọgaara jẹ ti ẹmi, ti a gbekari otitọ. (Heberu 11:6) Igbagbọ yẹn, bi o ti wu ki o ri, ni a nilati tì lẹhin nipasẹ awọn iṣẹ. (Jakobu 2:17) Isin tootọ pa aṣa olokiki tì. Ó dirọ mọ awọn ọ̀pá idiwọn Bibeli lori iwarere ati ọrọ sisọ mimọ tonitoni. (1 Kọrinti 6:9, 10; Efesu 5:3-5) Awọn ti nṣe e nfi ootọ inu saapọn lati mu awọn eso ẹmi Ọlọrun jade ninu igbesi-aye idile wọn, ni ibi iṣẹ ounjẹ oojọ wọn, ni ile-ẹkọ, ati koda ninu eré itura wọn. (Galatia 5:22, 23) Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ngbiyanju lati maṣe gbagbe awọn imọran apọsiteli Pọọlu lae pe: “Nitori naa bi ẹyin ba njẹ, tabi bi ẹyin bá nmu, tabi ohunkohun ti ẹyin ba nṣe, ẹ maa ṣe gbogbo wọn fun ogo Ọlọrun.” (1 Kọrinti 10:31) Ijọsin wọn kii wulẹ ṣe aato aṣa kan lasan; ó jẹ́ ọna igbesi-aye.
13. Ki ni ohun ti ijọsin tootọ mú lọwọ, eesitiṣe ti a fi lè sọ pe awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa jẹ́ awọn eniyan onisin nitootọ?
13 Dajudaju, isin tootọ mu awọn igbokegbodo tẹmi lọwọ. Eyi ní adura idile ati tẹni funra ẹni ninu, ikẹkọọ Ọrọ Ọlọrun deedee ati ikẹkọọ Bibeli nṣeranwọ, ati lilọ si awọn ipade ijọ Kristẹni tootọ. Iwọnyi ti a mẹnukan gbẹhin yii ni a nbẹrẹ ti a sì npari pẹlu orin iyin si Jehofa ati pẹlu adura. (Matiu 26:30; Efesu 5:19) Awọn koko ẹkọ ti ngbeniro nipa tẹmi ni a nṣayẹwo nipasẹ awọn awiye ati ijiroro onibeere ati idahun ti awọn ọrọ-ẹkọ títẹ̀ ti ó wà larọọwọto fun gbogbo eniyan. Iru awọn ipade bẹẹ ni a saba maa nṣe ninu awọn Gbọngan Ijọba ti wọn wà letoleto ṣugbọn ti a kò ṣe lọṣọọ lọna aṣeregee, eyi ti a nlo kiki fun awọn ete tí ó jẹmọ́ isin: ṣiṣe awọn ipade deedee, ayẹyẹ igbeyawo, awọn ipade ijọsin iṣe iranti. Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa bọwọ fun Gbọngan Ijọba wọn ati awọn Gbọngan Apejọ nla gẹgẹ bi awọn ibi ti a yà sí mimọ fun ijọsin Jehofa. Laidabii ọpọ ṣọọṣi Kristẹndọmu, awọn Gbọngan Ijọba kii ṣe ibi apejọ ẹgbẹ-oun-ọgba.
14. Ki ni ohun ti ijọsin tumọsi fun awọn eniyan ti nsọ èdè Heberu, ki sì ni igbokegbodo ti ó ya awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa sọtọ lonii?
14 Awa ri i ni ibẹrẹ pe awọn ọmọwe so ọrọ Giriiki naa ti a tumọ si “iru ijọsin” tabi “isin” pọ̀ pẹlu ọrọ iṣe naa “lati ṣiṣẹsin.” Lọna ti o runilọkansoke, ọrọ Heberu alabaadọgba naa, ‛avo·dhahʹ, ni a lè tumọsi “iṣẹ-isin” tabi “ijọsin.” (Fiwe alaye ẹsẹ iwe lori Ẹkisodu 3:12 ati 10:26.) Fun awọn Heberu, ijọsin tumọsi iṣẹ-isin. Ohun ti ó sì tumọsi niyii fun awọn olujọsin tootọ lonii. Ami iyatọ ṣiṣe pataki gan-an ti isin tootọ ni pe gbogbo awọn ti nṣe e nṣajọpin ninu iṣẹ-isin oniwa-bi-Ọlọrun ti wiwaasu “ihinrere ijọba yii ni gbogbo aye lati ṣe ẹ̀rí fun gbogbo orilẹ-ede.” (Matiu 24:14; Iṣe 1:8; 5:42) Isin wo ni a mọ̀ yika aye fun ijẹrii rẹ̀ nigbangba si Ijọba Ọlọrun gẹgẹ bi ireti kanṣoṣo fun araye?
Ipá Asonipọṣọkan Didaju Kan
15. Ki ni ami idayatọ titayọ ti isin tootọ?
15 Isin èké ńpín yẹlẹyẹlẹ. O ti ṣokunfa, o ṣì tun nṣokunfa, ikoriira ati itajẹsilẹ sibẹ. Ni iyatọ si eyi, isin tootọ nsonipọṣọkan. Jesu sọ pe: “Nipa eyi ni gbogbo eniyan yoo fi mọ pe, ọmọ-ẹhin mi ni ẹyin nṣe, nigba ti ẹyin ba ni ifẹ si ọmọnikeji yin.” (Johanu 13:35) Ifẹ yẹn ti ó so awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa pọ gbooro rekọja aala orilẹ-ede, ẹgbẹ-oun-ọgba, iṣunna owo, ati ti ẹ̀yà iran ti ó pin iyooku araye sọtọ. Awọn Ẹlẹ́rìí “duro ṣinṣin ninu ẹmi kan, [wọn] jumọ njijakadi nitori igbagbọ ihinrere, pẹlu ọkan kan.”—Filipi 1:27.
16. (a) Ki ni “ihinrere” ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nwaasu? (b) Awọn asọtẹlẹ wo ni a nmuṣẹ lori awọn eniyan Jehofa, ki sì ni awọn ibukun ti ó ti tẹle e?
16 “Ihinrere” naa ti wọn nwaasu ni pe laipẹ ète alaiṣeeyipada Ọlọrun ni a o ṣaṣepari rẹ̀. Ifẹ inu rẹ̀ ni a o ṣe, “bii ti ọrun, bẹẹ ni ni ayé.” (Matiu 6:10) Orukọ ologo Jehofa ni a o dalare, ti ilẹ-aye yoo sì di paradise kan, nibi ti yoo ti ṣeeṣe fun awọn olujọsin tootọ lati walaaye titilae. (Saamu 37:29) Niti gidi araadọta ọkẹ awọn eniyan ni gbogbo ilẹ-aye nkẹgbẹpọ pẹlu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ni sisọ, ni imuṣẹ asọtẹlẹ Bibeli pe: “A o bá ọ lọ, nitori awa ti gbọ pe, Ọlọrun wà pẹlu rẹ.” (Sekaraya 8:23) Jehofa nbukun awọn eniyan rẹ̀. “Ẹni kekere kan” niti tootọ ti di “alagbara orilẹ-ede,” ijọ kan yika ayé ti a sopọ patapata ni gbogbo ọna—ninu ero, ninu iṣẹ́, ninu ijọsin. (Aisaya 60:22) Eyi ni ohun kan ti kò tii ṣeeṣe fun isin èké lati ṣaṣepari rẹ̀.
Ayọ Iṣẹgun Isin Mimọgaara
17. Ki ni ó wà ni ipamọ fun Babiloni Nla, bawo ni a o sì ṣe mu eyi wá?
17 Ọrọ Ọlọrun ti sọ asọtẹlẹ iparun ilẹ-ọba isin èké agbaye, ti a pe lọna iṣapẹẹrẹ ni “Babiloni Nla.” Bibeli tun fi “awọn ọba,” tabi awọn aluṣakoso oṣelu, ilẹ-aye wé ami awọn iwo ẹranko ẹhanna kan. Ó sọ fun wa pe Ọlọrun yoo fi sinu ọkan-aya awọn oluṣakoso wọnyi ète naa lati dojú eto idasilẹ Satani Eṣu ti ó dabii aṣẹwo yii délẹ̀ ki ó sì pa á run patapata.—Wo Iṣipaya 17:1, 2, 5, 6, 12, 13, 15-18.b
18. Ki ni idi pataki ti Bibeli fifunni fun pipa Babiloni Nla run, nigba wo sì ni isin èké bẹrẹ ipa ọna buburu jai yii?
18 Eeṣe ti Babiloni Nla fi yẹ fun iparun? Bibeli dahun pe: “Ati ninu rẹ̀ ni a gbe ri ẹ̀jẹ̀ awọn wolii, ati ti awọn eniyan mímọ́, ati ti gbogbo awọn ti a pa lori ilẹ-aye.” (Iṣipaya 18:24) Ni fifihan pe ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ tí isin èké mu wa sori araarẹ pada sẹhin ani rekọja ipilẹṣẹ Babiloni, Jesu dẹbi fun awọn aṣaaju isin Juu, eyi ti o ti so araarẹ pọ̀ mọ́ Babiloni Nla, nigba ti o wi pe: ‘Ẹyin ejo, ọmọ awọn paramọlẹ, bawo ni ẹyin yoo ṣe sa fun idajọ Gẹhẹna? . . . Ẹ̀jẹ̀ gbogbo awọn olododo ti a ti ta silẹ lori ilẹ aye yoo wa sori yin, lati ẹ̀jẹ̀ Ebẹli olododo.’ (Matiu 23:33-35, NW) Bẹẹni, isin èké, eyi ti o bẹrẹ lori ilẹ-aye ni akoko iṣọtẹ ni Edeni, nilati dahun fun ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ buburu jai rẹ̀.
19, 20. (a) Ki ni awọn olujọsin tootọ yoo ṣe lẹhin ti a ba ti mu idajọ ṣẹ lori Babiloni Nla? (b) Ki ni yoo ṣẹlẹ lẹhin naa, ki sì ni ifojusọna ti yoo ṣí silẹ niwaju gbogbo awọn olujọsin tootọ?
19 Lẹhin iparun Babiloni Nla, awọn olujọsin tootọ lori ilẹ-aye yoo pa ohùn wọn pọ̀ pẹlu ẹgbẹ́ akọrin oke ọrun ti nkọrin jade pe: “Ẹ yin Jaa, ẹyin eniyan! . . . Nitori ó ti ṣe idajọ lara aṣẹwo nla naa . . . , ó sì ti gbẹsan ẹ̀jẹ̀ awọn ẹru rẹ̀ lara rẹ̀. . . . Èéfín rẹ̀ sì ngoke lae ati laelae.”—Iṣipaya 19:1-3.
20 Lẹhin naa awọn apa pataki miiran ti wọn parapọ di eto-ajọ Satani ti a le fojuri ni a o parun. (Iṣipaya 19:17-21) Lẹhin eyi, Satani, oludasilẹ gbogbo isin èké, ati awọn ẹmi eṣu rẹ̀ ni a ó jù sinu ọgbun ainisalẹ. A kò tun ni fun wọn lominira mọ lae lati ṣenunibini si awọn olujọsin tootọ Jehofa. (Iṣipaya 20:1-3) Ijọsin mimọgaara yoo ti ṣẹgun èké. Awọn ọkunrin ati obinrin oluṣotitọ ti wọn ti kọbiara si ikilọ atọrunwa lati sá kuro ninu Babiloni Nla nisinsinyi yoo ni anfaani lati laaja ki wọn sì wọnu ayé titun Ọlọrun. Nibẹ, yoo ṣeeṣe fun wọn lati ṣe ijọsin tootọ ki wọn sì fi ijọsin ṣiṣẹsin Jehofa titilae.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fun àlàyé nipa ijọsin angẹli ti a mẹnukan ni Kolose 2:18, wo Ilé-ìṣọ́nà, June 15, 1986, oju-iwe 12 si 13.
b Fun ẹkunrẹrẹ àlàyé lori asọtẹlẹ yii, wo iwe naa Revelation—Its Grand Climax At Hand! ti a tẹjade lati ọwọ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ori 33 si 36.
Dán Agbara Iranti Rẹ Wò
◻ Ipo ta ni ó ṣe pataki julọ lori isin, eesitiṣe?
◻ Ki ni ohun meji naa ti a beere fún fun isin tootọ ti Jakọbu tẹnumọ?
◻ Ki ni awọn ohun abeere fun miiran fun ijọsin mimọgaara?
◻ “Ihinrere” wo ni awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nwaasu rẹ̀?
◻ Bawo ni isin tootọ yoo ṣe ṣẹgun lori isin èké?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Awọn aṣaaju isin pejọpọ ni Assisi, Italy, ni October 1986
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Isin tootọ wémọ́ pipade papọ fun ijọsin