Àwọn Ìfilọ̀
◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní March: Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. April àti May: Àsansílẹ̀ owó fún Ilé Ìṣọ́. Fún iṣẹ́ ìsìn àárín ọ̀sẹ̀ àti ní àwọn ìpínlẹ̀ ti a sábà máa ń kárí, a lè lo ìwé pẹlẹbẹ tuntun náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? June: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Pọkàn pọ̀ sórí bíbẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. ÀKÍYÈSÍ: Àwọn ìjọ tí yóò bá nílò àwọn ìwé ìgbétásì tí a mẹ́nu kàn lókè yí ní láti béèrè fún wọn lórí Literature Order Form (S-14) olóṣooṣù wọn ti oṣù tí ń bọ̀.
◼ Kí alábòójútó olùṣalága tàbí ẹnì kan tí òun yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní March 1 tàbí bí ó bá ti lè ṣeé ṣe kí ó yá tó lẹ́yìn náà. Ẹ ṣe ìfilọ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tí ẹ bá ti ṣe èyí.
◼ Ní ọdún yìí, a óò sọ àkànṣe ọ̀rọ̀ àsọyé fún gbogbo ènìyàn fún àkókò Ìṣe Ìrántí ní ọ̀pọ̀ jù lọ ìjọ ní ọjọ́ Sunday, April 6. A pe àkọlé ọ̀rọ̀ àsọyé náà ní, “Ẹ Pa Ara Yín Mọ́ Tónítóní Kúrò Nínú Ẹ̀gbin Ayé.” Ó yẹ kí gbogbo wa pésẹ̀ síbẹ̀, a sì gbọ́dọ̀ ṣètìlẹyìn fún àwọn olùfìfẹ́hàn tí wọ́n wá sí Ìṣe Ìrántí láti wà níbẹ̀ fún ọ̀rọ̀ àsọyé náà. Ó dájú pé ohun tí a bá gbọ́ yóò jẹ́ ìdí kan fún ìpinnu tí a sọ dọ̀tun láti mú inú Ọlọ́run dùn.
◼ Ní gbogbo àwùjọ, ní onírúurú àkókò nínú ọdún, àwọn họlidé ayé máa ń wà tí ó máa ń fún àwọn ọmọ ní àyè kúrò ní ilé ẹ̀kọ́, tí ó sì máa ń fúnni láyè kúrò lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́. Ìwọ̀nyí jẹ́ àǹfààní títayọlọ́lá fún ìjọ láti ní ìpín tí ó pọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Kí àwọn alàgbà fojú sọ́nà fún ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí yóò wáyé, kí wọ́n sì fi àwọn ìṣètò tí wọ́n ti ṣe fún ìjẹ́rìí àjẹ́pọ̀ ní àwọn àkókò họlidé tó ìjọ létí tipẹ́tipẹ́ ṣáájú.