ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/97 ojú ìwé 7
  • Àpótí Ìbéèrè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àpótí Ìbéèrè
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìsìnkú Kristẹni—Kó Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì, Kó Lọ́wọ̀, Kó Dára Lójú Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ojú Ìwòye Kristẹni Nípa Àṣà Ìsìnkú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Kí Làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gbà Gbọ́ Lórí Ọ̀rọ̀ Ìsìnkú?
    Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
km 3/97 ojú ìwé 7

Àpótí Ìbéèrè

◼ Nígbà tí a bá ké sí ìjọ láti ṣèrànwọ́ ní ṣíṣètò fún ìsìnkú kan, àwọn ìbéèrè tí ó tẹ̀ lé e yìí lè dìde:

Ta ni ó yẹ kí ó sọ àwíyé ìsìnkú? Àwọn mẹ́ńbà ìdílé ni yóò pinnu èyí. Wọ́n lè yan arákùnrin èyíkéyìí tí ó ti ṣe batisí, tí ó wà ní ìdúró rere. Bí a bá sọ pé kí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà pèsè olùbánisọ̀rọ̀ kan, gẹ́gẹ́ bí ó ti sábà máa ń jẹ́, wọn yóò yan alàgbà dídáńgájíá kan láti sọ àsọyé tí a gbé karí ìlapa èrò àsọyé Society. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kì yóò ṣe àṣejù pípọ́n olóògbé náà ní àpọ́njù, ó lè bá a mu pé kí a pe àfiyèsí sí àwọn ànímọ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ tí ó fi hàn.

Ǹjẹ́ a lè lo Gbọ̀ngàn Ìjọba bí? A lè lò ó bí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà bá ti fọwọ́ sí i, tí kò bá sì dí ìṣètò ìpàdé tí a ń ṣe déédéé lọ́wọ́. A lè lo gbọ̀ngàn náà bí olóògbé náà bá ti ní orúkọ rere, tí ó sì jẹ́ mẹ́ńbà ìjọ náà tàbí tí ó jẹ́ ọmọ aláìtójúúbọ́ ti mẹ́ńbà kan. Bí ẹni náà bá ti gbajúgbajà láwùjọ fún ìwà tí kò bá ti Kristẹni mu, tàbí bí àwọn kókó abájọ mìíràn bá wà tí ó lè fi ìjọ hàn lọ́nà tí kò bára dé, àwọn alàgbà lè pinnu láti má ṣe jẹ́ kí a lo gbọ̀ngàn náà.—Wo ìwé Iṣetojọ, ojú ìwé 62, 63.

Gẹ́gẹ́ bí ó ti sábà máa ń rí, a kì í lo Gbọ̀ngàn Ìjọba fún ìsìnkú àwọn aláìgbàgbọ́. Àyàfi kan lè wà bí àwọn mẹ́ńbà ìdílé tí ó gbẹ̀yìn ẹni náà bá ń dara pọ̀ dáradára gẹ́gẹ́ bí akéde tí ó ti ṣe batisí, tí àwọn akéde tí ó pọ̀ tó nínú ìjọ sì mọ olóògbé náà pé ó ní ìṣarasíhùwà tí ó bójú mu sí òtítọ́, tí ó sì ní orúkọ rere fún ìwà títọ́ láwùjọ, tí a kò sì mú àwọn àṣà ayé wọ inú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà.

Nígbà tí wọ́n bá ń yọ̀ǹda lílo Gbọ̀ngàn Ìjọba, àwọn alàgbà yóò ṣàyẹ̀wò bóyá ó jẹ́ àṣà láti retí pé kí pósí náà wà ní ibi ààtò ìsìnkú náà. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, wọ́n lè fàyè gba kí a gbé e wá sínú gbọ̀ngàn náà.

Ìsìnkú fún àwọn ẹni ayé ńkọ́? Bí olóògbé náà bá ní orúkọ rere láwùjọ, arákùnrin kan lè sọ àsọyé Bíbélì tí ń tuni nínú kan ní ilé tàbí ní agboolé olóògbé náà tàbí lẹ́bàá sàréè. Ìjọ yóò kọ̀ láti bójú tó ìsìnkú fún ẹnì kan tí a mọ̀ fún ìwà pálapàla tí kò bófin mu, tàbí tí ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ̀ ta ko àwọn ìlànà Bíbélì lọ́nà tí ó burú jáì. Dájúdájú, arákùnrin kan kì yóò bá àlùfáà kan ṣàjọpín nínú ṣíṣe ìsìn alámùúlùmálà ìgbàgbọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò nípìn-ín nínú ìsìnkú tí a ṣe nínú ṣọ́ọ̀ṣì Bábílónì Ńlá.

Bí ó bá jẹ́ pé a ti yọ olóògbé náà lẹ́gbẹ́ ńkọ́? Ní gbogbogbòò, ìjọ kì yóò lọ́wọ́ sí i. A kì yóò lo Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bí ẹni náà bá ti ń fi ẹ̀rí ìrònúpìwàdà hàn, tí ó sì ń fi ìfẹ́ ọkàn láti di ẹni tí a mú pa dà bọ̀ sípò hàn, ẹ̀rí ọkàn arákùnrin kan lè gbà á láyè láti sọ àsọyé Bíbélì ní ilé tàbí ní agboolé olóògbé náà tàbí lẹ́bàá sàréè, láti jẹ́rìí fún àwọn aláìgbàgbọ́, kí ó sì tu àwọn mọ̀lẹ́bí nínú. Bí ó ti wù kí ó rí, kí ó tó ṣe ìpinnu yìí, yóò bọ́gbọ́n mu fún arákùnrin náà láti bá ẹgbẹ́ àwọn alàgbà fikùn lukùn, kí ó sì ronú lórí ohun tí wọ́n bá dámọ̀ràn. Nínú ipò tí kò bá ti bọ́gbọ́n mu fún arákùnrin yẹn láti nípìn-ín nínú rẹ̀, ó lè bójú mu kí arákùnrin kan tí ó jẹ́ mẹ́ńbà ìdílé olóògbé náà sọ àsọyé kan láti tu àwọn mọ̀lẹ́bí nínú.

A lè rí ìtọ́sọ́nà síwájú sí i nínú àwọn ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ ti October 15, 1990, ojú ìwé 30, 31; January 15, 1982, ojú ìwé 30, 31; September 15, 1980, ojú ìwé 5 sí 7; December 1, 1978, ojú ìwé 4 sí 8; December 1, 1977, ojú ìwé 731, 732; January 1, 1971, ojú ìwé 31, 32; àti Jí! March 8, 1991, ojú ìwé 22 sí 23, àti January 8, 1978, ojú ìwé 20 sí 23.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́