Ojú Ìwòye Kristẹni Nípa Àṣà Ìsìnkú
IKÚ olólùfẹ́ wa kan tí ó ṣẹlẹ̀ lójijì, láìròtẹ́lẹ̀, máa ń bani nínú jẹ́ púpọ̀. Ó ń dani láàmú, àròdùn ọkàn jíjinlẹ̀ sì máa ń tẹ̀ lé e. Ọ̀tọ̀ tún ni pé kí a máa wo olólùfẹ́ wa kan tí ó sùn nínú oorun ikú lẹ́yìn tí ó ti ṣàìsàn lílekoko fún ìgbà pípẹ́, ṣùgbọ́n ẹ̀dùn ọkàn àti ìmọ̀lára òfò ńláǹlà ṣì máa ń wà níbẹ̀.
Ohun yòówù tí ó lè fa sábàbí ikú olólùfẹ́ kan, àwọn ẹbí olóògbé náà nílò ìrànlọ́wọ́ àti ìtùnú. Kristẹni kan tí ẹbí rẹ̀ dolóògbé lè ní láti dojú kọ inúnibíni láti ọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n fi dandan lé títẹ̀lé àwọn àṣà ìsìnkú tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Èyí wọ́pọ̀ ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè Áfíríkà àti ní àwọn apá ibòmíràn lágbàáyé.
Kí ni yóò ran Kristẹni kan tí ẹbí rẹ̀ dolóògbé lọ́wọ́ láti yẹra fún àwọn àṣà ìsìnkú tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu? Báwo ni àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ṣe lè ràn án lọ́wọ́ ní irú àkókò àdánwò bẹ́ẹ̀? Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí jẹ́ ohun tí ó kan gbogbo àwọn tí ń fẹ́ láti wu Jèhófà, nítorí “ọ̀nà ìjọsìn tí ó mọ́, tí ó sì jẹ́ aláìlẹ́gbin ní ojú ìwòye Ọlọ́run àti Baba wa ni èyí: láti máa bójú tó àwọn ọmọ òrukàn àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn, àti láti pa ara ẹni mọ́ láìní èérí kúrò nínú ayé.”—Jákọ́bù 1:27.
Ìgbàgbọ́ So Mọ́ Ọn
Kókó abájọ wíwọ́pọ̀ tí ó so mọ́ àwọn àṣà ìsìnkú ni ìgbàgbọ́ náà pé àwọn òkú ṣì wà láàyè ní ilẹ̀ àkóso àìrí ti àwọn baba ńlá. Láti tù wọ́n lójú, ọ̀pọ̀ àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ rò pé ojúṣe àwọn ni láti ṣe àwọn ààtò kan. Wọ́n sì lè máa bẹ̀rù pé àwọn yóò ṣe ohun tí yóò mú inú bí àwọn aládùúgbò wọn tí wọ́n gbà gbọ́ pé aburú yóò ṣẹlẹ̀ láwùjọ, bí àwọn kò bá ṣe ààtò náà.
Kristẹni tòótọ́ kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìbẹ̀rù ènìyàn borí òun, kí ó sì tìtorí bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ nínú àwọn àṣà tí kò wu Ọlọ́run. (Òwe 29:25; Mátíù 10:28) Bíbélì fi hàn pé àwọn òkú kò mọ ohunkóhun rárá, nítorí tí ó sọ pé: “Nítorí àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá . . . Kò sí iṣẹ́ tàbí ìhùmọ̀ tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n ní Ṣìọ́ọ̀lù, ibi tí ìwọ ń lọ.” (Oníwàásù 9:5, 10) Nítorí náà, Jèhófà Ọlọ́run kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ìgbàanì láti má ṣe gbìyànjú láti tu àwọn òkú lójú tàbí láti bá wọn sọ̀rọ̀. (Diutarónómì 14:1; 18:10-12; Aísáyà 8:19, 20) Àwọn òtítọ́ Bíbélì wọ̀nyí forí gbárí pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àṣà ìsìnkú tí ó lókìkí.
“Ìfọ̀mọ́ ti Ìbálòpọ̀” Ńkọ́?
Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan ní àárín gbùngbùn Áfíríkà, a retí pé kí ẹni tí ọkọ tàbí aya rẹ̀ dolóògbé ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ìbátan tímọ́tímọ́ olóògbé náà kan. Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìgbàgbọ́ wọn ni pé òkú náà yóò ṣèpalára fún ìdílé tí ó wà láàyè. Ààtò yìí ni a ń pè ní “ìfọ̀mọ́ ti ìbálòpọ̀.” Ṣùgbọ́n Bíbélì pe ìbálòpọ̀ èyíkéyìí lẹ́yìn òde ìgbéyàwó ní “àgbèrè.” Níwọ̀n bí àwọn Kristẹni ti ní láti “sá fún àgbèrè,” wọ́n ń fi ìgboyà lòdì sí àṣà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu yìí.—1 Kọ́ríńtì 6:18.
Gbé ọ̀ràn opó kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mercy yẹ̀ wò.a Nígbà tí ọkọ rẹ̀ kú ní ọdún 1989, àwọn ẹbí rẹ̀ fẹ́ kí òun pẹ̀lú mọ̀lẹ́bí kan tí ó jẹ́ ọkùnrin jọ ṣe ìfọ̀mọ́ ti ìbálòpọ̀. Ó kọ̀ jálẹ̀, ó ṣàlàyé pé ààtò náà tako òfin Ọlọ́run. Inú bí àwọn ẹbí rẹ̀, wọ́n sì bá tiwọn lọ, lẹ́yìn tí wọ́n bú u dáadáa. Oṣù kan lẹ́yìn rẹ̀, wọ́n wá kó ẹrù inú ilé rẹ̀ lọ, wọn tú páànù òrùlé rẹ̀. Wọ́n wí pé: “Ìsìn rẹ̀ yóò bójú tó ọ.”
Ìjọ náà tu Mercy nínú, wọ́n sì kọ́ ilé tuntun fún un. Ó wú àwọn aládùúgbò rẹ̀ lórí tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn kan fi pinnu láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ náà, aya olórí ẹ̀sìn Kátólíìkì ni ó sì kọ́kọ́ kó ewéko wá láti fi ṣe òrùlé. Ìṣòtítọ́ Mercy fún àwọn ọmọ rẹ̀ níṣìírí. Láti ìgbà yẹn, mẹ́rin lára wọn ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run, láìpẹ́ yìí, ọ̀kan lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́.
Nítorí àṣà ìfọ̀mọ́ ti ìbálòpọ̀, àwọn Kristẹni kan ti jẹ́ kí a fipá mú wọn kó wọnú ṣíṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú aláìgbàgbọ́. Fún àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan tí aya rẹ̀ ti kú, tí ó sì ti lé ní ẹni 70 ọdún fi ìwàǹwára gbé ọ̀dọ́mọbìnrin kan tí ó jẹ́ mọ̀lẹ́bí aya rẹ̀ tí ó ti kú níyàwó. Nípa ṣíṣe èyí, ó lè sọ pé òun ti ṣe ìfọ̀mọ́ ti ìbálòpọ̀. Ṣùgbọ́n, irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ tako ìmọ̀ràn Bíbélì pé àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ ṣègbéyàwó “kìkì nínú Olúwa.”—1 Kọ́ríńtì 7:39.
Ayẹyẹ Àìsùn Àṣemọ́jú
Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ máa ń pé jọ sílé olóògbé náà, wọ́n a sì ṣàìsùn ní gbogbo òru. Àìsùn yìí tún máa ń ní pọ̀pọ̀ṣìnṣìn àti orin tí ń kọ lálá nínú. Ìgbàgbọ́ wọn ni pé yóò tu àwọn òkú lójú, yóò sì gba ìdílé tí ó wà láàyè náà lọ́wọ́ àwọn àjẹ́. Wọ́n lè máa sọ̀rọ̀ ìpọ́nni láti lè jèrè ojú rere ẹni tí ó dolóògbé náà. Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ ráńpẹ́, àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ náà le kọ orin ẹ̀sìn kan, lẹ́yìn èyí, ẹnì kan yóò dìde sọ̀rọ̀. Èyí lè máa bá a lọ títí ilẹ̀ yóò fi mọ́.b
Kristẹni tòótọ́ kì í nípìn-ín nínú irú ayẹyẹ àìsùn àṣemọ́jú bẹ́ẹ̀, nítorí pé, Bíbélì fi hàn pé àwọn òkú kò lè ran àwọn alààyè lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò lè pa wọ́n lára. (Jẹ́nẹ́sísì 3:19; Sáàmù 146:3, 4; Jòhánù 11:11-14) Ìwé Mímọ́ sọ pé ìbẹ́mìílò lòdì. (Ìṣípayá 9:21; 22:15) Síbẹ̀, ó lè nira fún Kristẹni opó kan láti má ṣe jẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn mú ìbẹ́mìílò wọlé. Wọ́n lè fàáké kọ́rí pé àwọn yóò ṣe àìsùn àṣemọ́jú nínú ilé rẹ̀. Kí ni àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ àwọn Kristẹni tí mọ̀lẹ́bí wọn dolóògbé lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kojú irú àfikún ìrora ọkàn yìí?
Ó ti ṣeé ṣe lọ́pọ̀ ìgbà fún àwọn alàgbà ìjọ láti ran ìdílé Kristẹni tí mọ̀lẹ́bí wọn dolóògbé lọ́wọ́ láti bá wọn fèrò wérò pẹ̀lú àwọn mọ̀lẹ́bí àti aládùúgbò. Lẹ́yìn irú ìfèròwérò bẹ́ẹ̀, àwọn wọ̀nyí lè gbà láti fi ilé náà sílẹ̀ ní ìrọwọ́rọsẹ̀, kí wọ́n sí péjọ lẹ́yìn náà fún ààtò ìsìnkú ní ọjọ́ mìíràn. Ṣùgbọ́n bí àwọn kan bá jẹ́ kìígbọ́-kìígbà ńkọ́? Bíbá a nìṣó láti fèrò wérò pẹ̀lú wọn lè fa arukutu. ‘Kò yẹ kí ẹrú Olúwa máa jà, ṣùgbọ́n ó yẹ kí ó máa kó ara rẹ̀ ní ìjánu lábẹ́ ibi.’ (2 Tímótì 2:24) Nítorí náà bí àwọn mọ̀lẹ́bí tí kò fọwọ́ sowọ́ pọ̀ bá fi ìbínú tẹ́rí gba ṣíṣe kòkáárí, Kristẹni opó kan àti àwọn ọmọ rẹ̀ lè má lè ṣe ohunkóhun láti dènà èyí. Ṣùgbọ́n wọn kò ní lọ́wọ́ nínú ayẹyẹ ìsìn èké èyíkéyìí tí ó bá ṣẹlẹ̀ nínú ilé wọn, nítorí wọ́n ń ṣègbọràn sí àṣẹ Bíbélì pé: “Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba so pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́.”—2 Kọ́ríńtì 6:14.
Ìlànà yìí tún kan ìsìnkú. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í lọ́wọ́ nínú orin kíkọ, àdúrà, tàbí ààtò ìsìn tí òjíṣẹ́ ìsìn èké kan bá darí rẹ̀. Bí àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà ìdílé tí wọ́n tan mọ́ ẹni tí ó dolóògbé náà pẹ́kípẹ́kí bá rí i pé ó pọndandan láti lọ sí irú ìsìn bẹ́ẹ̀, wọn kò ní lọ́wọ́ nínú rẹ̀.—2 Kọ́ríńtì 6:17; Ìṣípayá 18:4.
Ètò Ìsìnkú Tí Ó Gbayì
Ètò ìsìnkú tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá darí kì í ní ààtò tí a pète láti tu àwọn òkú lójú nínú. A óò sọ àsọyé Bíbélì yálà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, nínú ilé ìsìnkú, nínú ilé ẹni tí ó dolóògbé náà, tàbí létí sàréè. Ète àsọyé náà ni láti tu àwọn tí mọ̀lẹ́bí wọn dolóògbé nínú nípa ṣíṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa ikú àti ìrètí àjíǹde fún wọn. (Jòhánù 11:25; Róòmù 5:12; 2 Pétérù 3:13) A lè kọ orin kan tí a gbé ka Ìwé Mímọ́, a óò sì fi àdúrà atuninínú mú ètò ìsìnkú náà wá síparí.
Láìpẹ́ yìí, a ṣe irú ètò ìsìnkú báyìí fún obìnrin kan tí í ṣe ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí ó sì wá jẹ́ àbúrò Nelson Mandela, ààrẹ Gúúsù Áfíríkà. Lẹ́yìn ètò ìsìnkú náà, ààrẹ náà fi tọkàntọkàn dúpẹ́ lọ́wọ́ olùbánisọ̀rọ̀ náà. Ọ̀pọ̀ àwọn lóókọ-lóókọ láwùjọ àti àwọn lọ́gàá-lọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ọba ni ó pésẹ̀ síbẹ̀. Mínísítà kan wí pé: “N kò tí ì rí ètò ìsìnkú tí ó gbayì tó báyìí rí.”
Wíwọ Aṣọ Ọ̀fọ̀ Ha Ṣètẹ́wọ́gbà Bí?
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣọ̀fọ̀ nítorí ikú olólùfẹ́ wọn. Gẹ́gẹ́ bíi Jésù, wọ́n tilẹ̀ lè da omijé lójú. (Jòhánù 11:35, 36) Ṣùgbọ́n wọn kò gbà pé ó pọndandan láti fi ẹ̀dùn ọkàn wọn hàn ní gbangba nípa lílo àwọn àmì kan tí yóò hàn sóde. (Fi wé Mátíù 6:16-18.) Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, a retí pé kí àwọn opó wọ aṣọ àkànṣe kan láti lè tu àwọn òkú lójú. Wọ́n gbọ́dọ̀ máa wọ àwọn aṣọ wọ̀nyí fún ọ̀pọ̀ oṣù tàbí fún ọdún kan lẹ́yìn ìsìnkú náà, ayẹyẹ mìíràn sì tún máa ń wáyé nígbà tí wọ́n bá tún bọ́ ọ sílẹ̀.
Wọ́n ka kíkùnà láti fi àmì ọ̀fọ̀ hàn sí dídẹ́ṣẹ̀ sí ẹni tí ó kú náà. Nítorí ìdí yìí, ní àwọn apá ibì kan ní Swaziland, àwọn ọba ti lé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kúrò nínú ilé àti lórí ilẹ̀ wọn. Ṣùgbọ́n, àwọn arákùnrin wọn nípa tẹ̀mí tí ń gbé níbòmíràn ti fìgbà gbogbo bójú tó irú àwọn Kristẹni olóòótọ́ bẹ́ẹ̀.
Ilé Ẹjọ́ Gíga ti Swaziland ti dá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láre, ní sísọ pé kí wọ́n jẹ́ kí wọ́n padà sí ilé àti ilẹ̀ wọn. Nínú ọ̀ràn mìíràn, a gbà kí Kristẹni opó kan wà lórí ilẹ̀ rẹ̀, lẹ́yìn tí ó ti pèsè lẹ́tà àti kásẹ́ẹ̀tì kan, nínú èyí tí ọkọ rẹ̀ tí ó dolóògbé ti sọ kedere pé aya òun kò gbọ́dọ̀ wọ aṣọ ọ̀fọ̀. Nípa báyìí, ó ṣeé ṣe fún un láti fẹ̀rí hàn pé ní tòótọ́ ni òun ń bọ̀wọ̀ fún ọkọ òun.
Àǹfààní ńláǹlà wà nínú níní ìtọ́ni tí ó ṣe kedere lórí ètò ìsìnkú kí ó tó di pé ẹnì kan kú, ní pàtàkì ní àwọn ibi tí àṣà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu bá ti wọ́pọ̀. Gbé àpẹẹrẹ ti Victor, tí ń gbé ní Cameroon yẹ̀ wò. Ó kọ ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí a óò tẹ̀ lé níbi ìsìnkú rẹ̀ sílẹ̀. Nínú ìdílé rẹ̀, àwọn èèyàn sàràkí-sàràkí ń bẹ, tí wọ́n fọwọ́ dan-in dan-in mú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn ti jíjúbà àwọn òkú, títí kan bíbọ agbárí òkú. Níwọ̀n bí Victor ti jẹ́ mẹ́ńbà kan tí a bọ̀wọ̀ fún nínú ìdílé, ó mọ̀ pé wọ́n a fẹ́ bọ agbárí òun. Nítorí náà, ó pèsè ìtọ́ni ṣíṣe kedere nípa bí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò ṣe bójú tó ìsìnkú òun. Èyí mú kí ipò náà rọrùn fún opó rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀, a sì ṣe ìjẹ́rìí tí ó jíire ní àwùjọ náà.
Yẹra fún Títẹ̀lé Àwọn Àṣà Tí Kò Bá Ìwé Mímọ́ Mu
Àwọn kan tí wọ́n ní ìmọ̀ Bíbélì ń bẹ̀rù láti dá yàtọ̀. Láti yẹra fún inúnibíni, wọ́n ti gbìyànjú láti tẹ́ àwọn aládùúgbò wọn lọ́rùn nípa ṣíṣe bí ẹni pé àwọn ń ṣe ohun tí ó jọ àìsùn òkú gẹ́gẹ́ bí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò burú láti ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ti mọ̀lẹ́bí wọn dolóògbé kí a bàa lè tù wọ́n nínú, èyí kò béèrè pé a gbọ́dọ̀ darí ètò ìsìnkú kan nínú ilé ẹni tí ó dolóògbé náà ní alẹ́ tí ó ṣáájú ìsìnkú gan-an. Ṣíṣe èyí lè mú àwọn òǹwòran kọsẹ̀, níwọ̀n bí ó ti lè fún wọn ní èrò pé àwọn olùkópa kò gbà gbọ́ nínú ohun tí Bíbélì sọ nípa ipò tí àwọn òkú wà ní ti gidi.—1 Kọ́ríńtì 10:32.
Bíbélì rọ àwọn Kristẹni láti fi ìjọsìn Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wọn, kí wọ́n sì fi ọgbọ́n lo àkókò wọn. (Mátíù 6:33; Éfésù 5:15, 16) Ṣùgbọ́n, ní àwọn ibì kan, ìgbòkègbodò ìjọ dẹnu kọlẹ̀ fún ọ̀sẹ̀ kan gbáko tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nítorí ètò ìsìnkú. Áfíríkà nìkan kọ́ ni ìṣòro yìí wà. Nípa ètò ìsìnkú kan, ìròyìn láti Gúúsù Amẹ́ríkà sọ pé: “Iye àwọn tí ó wá sì àwọn ìpàdé Kristẹni mẹ́ta lọ sílẹ̀ gidigidi. Àwọn ará kò jáde fún iṣẹ́ ìsìn pápá fún nǹkan bí ọjọ́ mẹ́wàá. Kódà ẹnu ya àwọn ará ìta àti àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti rí i pé àwọn kan lára àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò ìsìnkú náà, ó sì já wọn kulẹ̀.”
Ní àwọn àwùjọ kan, ìdílé tí mọ̀lẹ́bí wọn dolóògbé lè ké sí àwọn ọ̀rẹ́ díẹ̀ tí ó sún mọ́ wọn gan-an sínú ilé wọn fún oúnjẹ ráńpẹ́ lẹ́yìn ìsìnkú náà. Ṣùgbọ́n ní ibi púpọ̀ ní Áfíríkà, ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn tí ó wá síbi ètò ìsìnkú ni ó máa ń wọ́ lọ sílé olóògbé náà, tí wọ́n sì ń retí pé kí a filé pọntí, kí a fọ̀nà rokà, kí a sì pẹran. Àwọn kan tí wọ́n dara pọ̀ mọ́ ìjọ Kristẹni ti tẹ̀ lé irú àṣà yìí, wọ́n ń jẹ́ kí a ní èrò náà pé àwọn ń ṣe ayẹyẹ gẹ́gẹ́ bí àṣà láti tu àwọn òkú lójú.
Ètò ìsìnkú tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe kì í gbé ẹrù ìnira karí àwọn tí mọ̀lẹ́bí wọn dolóògbé. Nítorí náà, kò pọndandan láti ní ètò àkànṣe fún àwọn tí ó wá láti lè fúnni lówó tí yóò ká ìsìnkú onínàáwó rẹpẹtẹ. Bí àwọn opó tí kò ní lọ́wọ́ kò bá lé gbọ́ bùkátà ìnáwó náà, ó dájú pé àwọn mìíràn nínú ìjọ yóò láyọ̀ láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Bí irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ kò bá tó, àwọn alàgbà lè ṣètò láti pèsè ìrànlọ́wọ́ nípa ti ara fún àwọn tí ó yẹ.—1 Tímótì 5:3, 4.
Kì í ṣe gbogbo ìgbà náà ni àwọn àṣà ètò ìsìnkú máa ń forí gbárí pẹ̀lú àwọn ìlànà Bíbélì. Nígbà tí ó bá ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, àwọn Kristẹni ti pinnu láti hùwà ní ìbámu pẹ̀lú Ìwé Mímọ́.c (Ìṣe 5:29) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí lè mú ìpọ́njú ńláǹlà wá, ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ Ọlọ́run lè jẹ́rìí sí i pé wọ́n ti kojú irú ìdánwò bẹ́ẹ̀ lọ́nà tí ó kẹ́sẹ járí. Wọ́n ti ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú okun láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo,” àti pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ onífẹ̀ẹ́ ti àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn tí wọ́n ti tù wọ́n nínú nínú ìpọ́njú wọn.—2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti lo àwọn orúkọ àfidípò nínú àpilẹ̀kọ yìí.
b Nínú àwọn èdè àti àṣà ìbílẹ̀ kan, a máa ń lo ọ̀rọ̀ náà, “àìsùn,” fún ìbẹ̀wò kúkúrú tí a ṣe láti tu àwọn tí mọ̀lẹ́bí wọn dolóògbé nínú. Ó lè máà ní ohun kan tí ó lòdì sí Ìwé Mímọ́ nínú. Wo Jí! ti May 22, 1979, ojú ìwé 27 sí 28.
c Níbi tí ó bá ti jẹ́ pé àwọn àṣà ìsìnkú ti lè mú ìdánwò lílekoko bá Kristẹni kan, àwọn alàgbà lè mú kí àwọn tí ó ń nàgà fún ìbatisí gbára dì fún ohun tí ń bẹ níwájú. Nígbà tí wọ́n bá ń jókòó pẹ̀lú àwọn ẹni tuntun wọ̀nyí láti jíròrò àwọn ìbéèrè láti inú ìwé náà, Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa, a gbọ́dọ̀ fún àwọn apá náà “Ọkàn, Ẹ̀ṣẹ̀ àti Ikú” àti “Àmúlùmálà-Ìgbàgbọ́,” ní àfiyèsí fínnífínní. Apá méjèèjí ni ó ní àwọn ìbéèrè yàn-bí-o-bá-fẹ́ fún ìjíròrò. Níhìn-ín ni àwọn alàgbà ti lè pèsè ìsọfúnni nípa àwọn àṣà ìsìnkú tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu kí ẹni tí ó ń nàgà fún ìbatisí lè mọ ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bí ó bá dojú kọ irú ipò bẹ́ẹ̀.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 23]
A Bù Kún Wọn fún Dídúró Ṣinṣin
Sibongili jẹ́ opó Kristẹni onígboyà kan tí ń gbé ní Swaziland. Lẹ́yìn tí ọkọ rẹ̀ kú láìpẹ́ yìí, ó kọ̀ láti tẹ̀ lé àwọn àṣà tí ọ̀pọ̀ rò pé ó lè tu òkú lójú. Fún àpẹẹrẹ, kò fá irun orí rẹ̀. (Diutarónómì 14:1) Èyí bí àwọn mẹ́jọ tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà ìdílé nínú gidigidi, wọ́n sì fipá fá orí rẹ̀. Wọn kò tún gbà kí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣèbẹ̀wò sí ilé náà láti tu Sibongili nínú. Ṣùgbọ́n, àwọn ẹlòmíràn tí inú wọn dùn sí ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà láyọ̀ láti bẹ̀ ẹ́ wò pẹ̀lú àwọn lẹ́tà ìṣírí tí àwọn alàgbà kọ. Lọ́jọ́ tí wọ́n ń retí pé kí Sibongili wọ àkànṣe aṣọ ọ̀fọ̀, ohun kan tí ó yani lẹ́nu ṣẹlẹ̀. Ẹnì kan tí ó jẹ́ abẹnugan nínú ìdílé náà pe ìpàdé láti jíròrò ìdí tí ó fi kọ̀ láti ṣe ohun tí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ nípa ọ̀fọ̀ ṣíṣe béèrè.
Sibongili ròyìn pé: “Wọ́n béèrè bí ìgbàgbọ́ mi ní ti ìsìn bá gbà kí ń fi ẹ̀dùn ọkàn mi hàn nípa wíwọ aṣọ àwọ̀kanlẹ̀ dúdú fún ṣíṣọ̀fọ̀. Lẹ́yìn tí mo ti ṣàlàyé ipò mi, wọ́n sọ fún mi pé wọn kò ní fipá mú mi. Sí ìyàlẹ́nu mi, gbogbo wọn bẹ̀bẹ̀ fún híhùwà sí mi lọ́nà tí kò tọ́ àti fún fífá orí mi láìjẹ́ pé ó ti inú mi wá. Gbogbo wọn ní kí ń jọ̀wọ̀ forí jì wọ́n.” Lẹ́yìn náà, àbúrò Sibongili tí ó jẹ́ obìnrin sọ èrò ọkàn rẹ̀ jáde pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ń ṣe ìsìn tòótọ́, ó sì ní kí a máa bá òun ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Tún gbé àpẹẹrẹ mìíràn yẹ̀ wò: Ọkùnrin ará Gúúsù Áfíríkà kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Benjamin jẹ́ ọmọ ọdún 29 nígbà tí ó gbọ́ lójijì pé baba òun ti kú. Ní àkókò yẹn, Benjamin nìkan ni Ẹlẹ́rìí nínú ìdílé rẹ̀. Nígbà ààtò ìsìnkú náà, wọ́n retí pé kí olúkúlùkù tò kọjá lẹ́bàá sàréè náà, kí wọ́n sì bu ẹ̀kúnwọ́ yẹ̀pẹ̀ sórí pósí náà.* Lẹ́yìn ìsìnkú náà, gbogbo mẹ́ńbà ìdílé náà fá orí wọn. Níwọ̀n bí Benjamin kò ti kópa nínú ààtò wọ̀nyí, àwọn aládùúgbò àti mẹ́ńbà ìdílé sọ tẹ́lẹ̀ pé baba rẹ̀ tí ó kú yóò fìyà jẹ ẹ́.
Benjamin wí pé: “Nítorí tí mo fi ìgbẹ́kẹ̀lé mi sínú Jèhófà, láburú kan kò ṣe mí.” Àwọn mẹ́ńbà ìdílé mi ṣàkíyèsí pé láburú kan kò ṣe mí. Nígbà tí ó yá, ọ̀pọ̀ nínú wọn bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì ṣe ìbatisí ní fífi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wọn nínú Ọlọ́run hàn. Benjamin wá ńkọ́? Ó wọnú iṣẹ́ ìjíhìnrere alákòókò kíkún. Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ó ti ní àǹfààní láti sin ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
Àwọn kan lè rò pé kò sí ohun tí ó lòdì nínú jíju òdòdó tàbí ẹ̀kúnwọ́ yẹ̀pẹ̀ sínú sàréè. Ṣùgbọ́n, Kristẹni kan yóò yẹra fún àṣà yìí bí àwùjọ náà bá kà á sí ọ̀nà kan láti tu òkú lójú tàbí bí ó bá jẹ́ apá kan ayẹyẹ tí òjíṣẹ́ ìsìn èké kan darí rẹ̀.—Wo Jí! March 22, 1977, ojú ìwé 15.