ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 2/8 ojú ìwé 10-11
  • Ó Ha Yẹ Kí A Bọlá fún Òkú Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ó Ha Yẹ Kí A Bọlá fún Òkú Bí?
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ààtò Tí A Gbé Karí Ìlànà Èké
  • Ojú Ìwòye Tí Ó Wà Déédéé
  • Ó Ha Lòdì Láti Yin Òkú Bí?
  • Ojú Ìwòye Kristẹni Nípa Àṣà Ìsìnkú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsìnkú Kristẹni—Kó Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì, Kó Lọ́wọ̀, Kó Dára Lójú Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Kí Làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gbà Gbọ́ Lórí Ọ̀rọ̀ Ìsìnkú?
    Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Ṣọ́ra fún Àwọn Àṣà Ìbílẹ̀ Tí Inú Ọlọ́run Kò Dùn Sí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 2/8 ojú ìwé 10-11

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ó Ha Yẹ Kí A Bọlá fún Òkú Bí?

“ÌMỌ̀LÁRA TÍ Ó JINLẸ̀ MÁA Ń SÚN Ọ̀PỌ̀ ÈNÌYÀN LÁTI MÁA FÚN ÒKÚ ÈNÌYÀN NÍ Ọ̀WỌ̀ TÍ A KÌ Í FÚN ÒKÚ ẸRAN.”—ENCYCLOPÆDIA BRITANNICA.

Ọ̀PỌ̀ ènìyàn máa ń bọlá fún òkú àwọn olólùfẹ́ wọn ní ọ̀nà kan ṣáá. A ń bọlá fún àwọn òkú nípa gbígbé ìkéde òkú jáde nínú ìwé ìròyìn, a sì máa ń sọ̀rọ̀ ìyìn nípa wọn. Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, ó wọ́pọ̀ láti máa ṣe ìsìnkú ti ẹ̀sìn tàbí ti àṣà ìbílẹ̀ tí ń ná ni lówó gan-an. Ayẹyẹ ìsìnkú lè máa bá a lọ fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, ọ̀sẹ̀, tàbí oṣù. A máa ń fi orúkọ àwọn tó ti kú pe àwọn ilé ìwé, pápákọ̀ òfuurufú, àdúgbò, àti ìlú. A ń ṣe àwọn ohun ìrántí, a sì ń gbé àwọn ọjọ́ ìsinmi kalẹ̀ láti máa rántí àwọn tó kú ikú akọni.

Bí ó ti wù kí ó rí, ní ìbámu pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, òkú kò mọ ohunkóhun nípa ọlá èyíkéyìí tí a lè fún wọn. (Jóòbù 14:10, 21; Sáàmù 49:17) Àwọn òkú wà láàyè kìkì nínú ìrántí àwọn tí ń rántí wọn. Bíbélì sọ pe: “Àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá.” (Oníwàásù 9:5) Ìwé Mímọ́ fún wa ní ìrètí àjíǹde tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú. (Jòhánù 5:28, 29; 11:25) Àmọ́ títí di ìgbà náà, àwọn òkú kò sí níbì kankan. Ní ti gidi, wọ́n ti di ekuru.—Jẹ́nẹ́sísì 3:19; Jóòbù 34:15.

Pẹ̀lú ohun tí Bíbélì sọ ní kedere nípa ipò tí àwọn òkú wà, ǹjẹ́ ó yẹ kí a máa bọlá fún wọn? Ó ha yẹ kí àwọn Kristẹni máa tẹ̀ lé àwọn àṣà ìbílẹ̀ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ààtò ìsìnkú àti ìsìnkú àwọn olólùfẹ́ wọn bí?

Ààtò Tí A Gbé Karí Ìlànà Èké

Ọ̀pọ̀, tàbí kí a kúkú sọ pé èyí tí ó pọ̀ jù nínú àwọn àṣà tí ó ní í ṣe pẹ̀lú òkú ni ó fìdí múlẹ̀ ṣinṣin sínú àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn tí kì í ṣe ti Bíbélì. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica sọ pé, àwọn ààtò kan jẹ́ “láti dáàbò bo òkú náà kúrò lọ́wọ́ ìkọlù ẹ̀mí èṣù; ìgbà mìíràn, ète ààtò náà jẹ́ láti dáàbò bo àwọn alààyè nítorí àkúfà tàbí láti gbà wọ́n lọ́wọ́ jàǹbá tí òkú náà lè fẹ́ ṣe.” Irú àṣà bẹ́ẹ̀ tí a gbé karí ìlànà èké pé àwọn òkú wà láàyè síbẹ̀ ní ilẹ̀ ọba àìrí kan tako òtítọ́ Bíbélì ní tààràtà.—Oníwàásù 9:10.

Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń jọ́sìn àwọn òkú. Irú ìjọsìn yìí ní rírú ẹbọ àti gbígbàdúrà sí àwọn baba ńlá ìgbàanì nínú. Àwọn kan tó ń lọ́wọ́ sí irú ààtò bẹ́ẹ̀ kò ka ohun tí wọ́n ń ṣe sí ìjọsìn bí kò ṣe ọ̀nà láti fi ọlá àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ hàn sí òkú náà. Síbẹ̀, irú ìfọkànsìn yìí fún òkú àwọn baba ńlá ìgbàanì ní a gbé karí ọ̀ràn ìsìn, ó sì forí gbárí pẹ̀lú ẹ̀kọ́ Bíbélì. Jésù Kristi sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ìwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni ìwọ gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún.”—Lúùkù 4:8.

Ojú Ìwòye Tí Ó Wà Déédéé

Fífi ọlá àti ọ̀wọ̀ fún àwọn òkú kì í fi gbogbo ìgbà ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ẹ̀kọ́ ìsìn èké. Fún àpẹẹrẹ, ìṣẹ̀lẹ̀ kan nínú Bíbélì ròyìn bí wọ́n ṣe bọlá fún olóòótọ́ Ọba Hesekáyà lẹ́yìn ikú. Àwọn ènìyàn Ọlọ́run “sin ín síbi ìgòkè lọ sí àwọn ibi ìsìnkú àwọn ọmọ Dáfídì; gbogbo Júdà àti àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù sì bu ọlá fún un nígbà ikú rẹ̀.” (2 Kíróníkà 32:33) Àpẹẹrẹ mìíràn ni ti Jésù. Bíbélì sọ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ “gbé òkú Jésù, wọ́n sì fi àwọn ọ̀já ìdìkú dì í pẹ̀lú àwọn èròjà atasánsán . . . , gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn Júù ti ní àṣà mímúra sílẹ̀ fún ìsìnkú.”—Jòhánù 19:40.

Ìwé Mímọ́ ní ọ̀pọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn nínú, níbi tí wọ́n ti ṣe àwọn ààtò tí ó jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ nípa òkú àti ìsìnkú. Àṣà wọ̀nyí kì í ṣe ti jíjọ́sìn àwọn baba ńlá, bẹ́ẹ̀ ni kò sinmi lórí ìgbàgbọ́ òdì náà pé àwọn òkú ń nípa lórí àlámọ̀rí àwọn alààyè. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ fi ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ hàn fún àwọn olólùfẹ́ wọn. Bíbélì kò lòdì sí irú ọ̀wọ̀ bẹ́ẹ̀, níwọ̀n bí o ti sinmi lórí ìmọ̀lára tí a dá mọ́ ẹ̀dá ènìyàn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kò fọwọ́ sí nínáwó nínàákúnàá lọ́nà tí kò ṣeé sàkóso níbi ìsìnkú. Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, kò fún àwọn Kristẹni níṣìírí láti di ẹni tí kò ní ìmọ̀lára tàbí tí kò ka nǹkan sí nígbà tí olólùfẹ́ wọn kan bá kú.

Nítorí náà, nígbà tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá lọ sí ibi ìsìnkú olólùfẹ́ wọn, wọ́n máa ń fi ọ̀wọ̀ àti ọlá tí ó yẹ hàn fún òkú náà. (Oníwàásù 7:2) Nígbà tí ó bá kan ọ̀ràn jíjá òdòdó, ṣíṣe ìsìn ìsìnkú, àti àwọn àṣà mìíràn ládùúgbò, àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ fìṣọ́ra yàn fún ara wọn láti yẹra fún àwọn àṣà tí ó forí gbárí pẹ̀lú ẹ̀kọ́ Bíbélì. Nínú èyí, a nílò ìpinnu tó dára tí ó sì wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia of Religion and Ethics, ṣàlàyé pé, “ìjẹ́pàtàkì àti iyì ààtò kan máa ń yí padà láti ìgbà dé ìgbà, débi pé ohun tí a pè é níkẹyìn lè yàtọ̀ pátápátá sí ohun tó jẹ́ ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, kí àlàyé tí a wá ń ṣe nípa rẹ̀ má tilẹ̀ sọ ohunkóhun nípa ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.”a

Ó Ha Lòdì Láti Yin Òkú Bí?

Ìlànà níní ojú ìwòye tó wà déédéé tún ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ nípa yínyin òkú. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń tiraka láti tu àwọn ti ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ nínú níbi ìsìn ìsìnkú. (2 Kọ́ríńtì 1:3-5) Ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan tí a ti ṣètò lè ní olùbánisọ̀rọ̀ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú. Àmọ́, kò ní bọ́gbọ́n mu láti sọ ìṣẹ̀lẹ̀ náà di èyí tí àwọn asunrárà ti to lọ́wọ̀ọ̀wọ́, tí wọ́n sì ń kì, tí wọ́n sì ń sa olóògbé náà ní mẹ́sàn-án mẹ́wàá. Dípò ìyẹn, ààtò ìsìnkú náà pèsè àǹfààní láti gbé àwọn ànímọ́ yíyanilẹ́nu tí Ọlọ́run ní ga, títí kan inú rere rẹ̀ ní pípèsè ìrètí àjíǹde fún wa.

Síbẹ̀, èyí kò túmọ̀ sí pé ó lòdì láti rántí àwọn ànímọ́ rere olóògbé náà ní àkókò àwíyé ìsìnkú náà. (Fi wé 2 Sámúẹ́lì 1:17-27.) Bí òkú náà bá ti jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run títí di ọjọ́ ikú, yóò jẹ́ àpẹẹrẹ títayọ láti fara wé. (Hébérù 6:12) Ó dára láti sinmẹ̀dọ̀ ronú lórí ipa ọ̀nà onídùúró-ṣinṣin àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Bíbá àwọn ẹlòmíràn jíròrò èrò olójú ìwòye dídára yìí ní àkókò ìsìn ìsìnkú ń pèsè ìtùnú fún àwọn alààyè àti ọ̀wọ̀ fún ìrántí ẹni tó kú.

Àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í jọ́sìn òkú. Wọn kì í lọ́wọ́ sí àwọn ààtò olókìkí tó tako òtítọ́ Bíbélì. Síbẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kọ èròǹgbà aláṣejù pé nítorí pé òkú jẹ́ ekuru lásán, gbogbo ààtò ìsìnkú jẹ́ àṣedànù kò sì pọndandan. Wọ́n máa ń ṣọ̀fọ̀, wọ́n sì máa ń rántí ènìyàn wọn tó kú. Àmọ́, òtítọ́ Bíbélì náà pé àwọn òkú kò jìyà àti pé ìrètí wà fún àjíǹde ń dín ẹ̀dùn ọkàn àti ìbànújẹ́ wọn kù.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ilé-Ìṣọ́nà, October 15, 1991, ojú ìwé 31, pèsè àwọn ìtọ́sọ́nà wọ̀nyí pé: “Kristẹni ojulowo kan nilati ṣagbeyẹwo pe: Njẹ titẹle aṣa kan ha le fihan awọn ẹlomiran pe mo ti tẹwọgba awọn igbagbọ ati aṣa ti kò bá iwe mimọ mu bi? Saa akoko ati ibi ti a wà le nipa lori idahun naa. Aṣa kan (tabi iṣẹ́ ọnà) ti le ni itumọ isin eke ninu ni ẹgbẹẹgbẹrun ọdun sẹhin tabi ti le ni iru rẹ̀ lonii ni ilẹ jijinna réré kan. Ṣugbọn lai lọ sinu iṣayẹwo ti o gba akoko, beere lọwọ araa rẹ pe: ‘Ki ni oju iwoye ti o wọpọ nibi ti mo ngbe?’—Fiwe 1 Kọrinti 10:25-29.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ìtọ́wọ̀ọ́rìn ìsìnkú tí a fi bọlá fún Gustav Kejì, ọba ilẹ̀ Sweden, nígbà tí ó kú ní ọdún 1632

[Credit Line]

Láti inú ìwé Bildersaal deutscher Geschichte

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́