ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/00 ojú ìwé 8
  • Rí I Dájú Pé O Padà Lọ!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Rí I Dájú Pé O Padà Lọ!
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìpadàbẹ̀wò Ń Ṣamọ̀nà sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Máyà Le Láti Ṣe Ìpadàbẹ̀wò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Ran Àwọn Tó Ní “Ìtẹ̀sí-Ọkàn Títọ́” Lọ́wọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Ṣàkọsílẹ̀ Àwọn Tó Fìfẹ́ Hàn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
km 4/00 ojú ìwé 8

Rí I Dájú Pé O Padà Lọ!

1 “Ìjíròrò yẹn mà lárinrin o! Ó dáa kí n yáa rántí padà débẹ̀.” Ṣé o ti sọ gbólóhùn yìí rí, ṣùgbọ́n tí o ò rántí ibi tí ẹni yẹn ń gbé mọ́ nígbà tó yá? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, o ti wá rí i pé ọ̀nà kan ṣoṣo tí o fi lè máa rí i dájú pé o padà ṣèbẹ̀wò ni nípa kíkọ àkọsílẹ̀.

2 Kọ Gbogbo Ohun Tó Bá Yẹ Sílẹ̀: Nígbà tóo bá ṣì rántí gbogbo ohun tóo bá ẹnì kan tó fìfẹ́ hàn sọ, wá àyè láti kọ gbogbo ìsọfúnni tó bá yẹ nípa ìjíròrò náà sílẹ̀. Kọ orúkọ ẹni yẹn àti bóo ṣe lè dá a mọ̀. Kọ àdírẹ́sì rẹ̀, ṣùgbọ́n má ṣe méfò nípa rẹ̀, ṣàyẹ̀wò kí o lè rí i dájú pé ohun tí o kọ sílẹ̀ tọ̀nà. Ṣàkọsílẹ̀ kókó ọ̀rọ̀ tẹ́ẹ jíròrò, ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tẹ́ẹ kà, àti ìwé tí o fi sóde.

3 Bó bá jẹ́ pé o bi ẹni náà ní ìbéèrè kan tí ẹ máa dáhùn nígbà tí o bá tún padà lọ, kọ ọ́ sílẹ̀. Ǹjẹ́ ohun kan wà tí o mọ̀ nípa ẹni náà, tàbí nípa ìdílé rẹ̀, tàbí nípa ẹ̀sìn tó ń ṣe? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, kọ ọ́ sílẹ̀. Nígbà náà, bí o bá padà ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹni náà, tí o sì sọ ohun tóo kọ sílẹ̀ yẹn, ìyẹn á jẹ́ kẹ́ni náà mọ̀ pé o fi òun sọ́kàn. Ní paríparí rẹ̀, kọ ọjọ́ àti àkókò tí o bá ẹni yẹn sọ̀rọ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́ àti ìgbà tóo sọ pé wàá padà wá. Nípa kíkọ àkọsílẹ̀ tó péye, ìránnilétí tó dájú á wà fún ẹ, o ò sì ní lè gbàgbé pé o ṣèlérí láti padà lọ.—1 Tím. 1:12.

4 Bóo bá ti kọ àkọsílẹ̀ tó péye tán, fi í sínú àwọn ohun yòókù tí o ń lò fún iṣẹ́ ìsìn pápá, ìyẹn àpò rẹ, Bíbélì, ìwé Reasoning, àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, kí o lè tètè máa rí i lò. Ó dáa pé kí o lo àkọsílẹ̀ ilé dé ilé mìíràn láti ṣàkọsílẹ̀ àwọn tí kò bá sí nílé, dípò tí wàá fi lo èyí tí o fi ń ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìpadàbẹ̀wò rẹ. Àmọ́ ṣá o, bó ti wù kóo máa kọ àkọsílẹ̀ nípa àwọn ìpadàbẹ̀wò tó, ohun tó ṣe pàtàkì ni pé kí o rí i dájú pé o padà lọ!

5 Fi Ẹni Náà Sọ́kàn: Nígbà tóo bá ń múra iṣẹ́ òjíṣẹ́, ṣàtúnyẹ̀wò àkọsílẹ̀ rẹ nípa ìpadàbẹ̀wò. Fi ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sọ́kàn, kí o sì ronú nípa ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò nígbà tóo bá padà ṣèbẹ̀wò. Ronú nípa bóo ṣe lè mú kí ìfẹ́ tí ẹni náà fi hàn ga dórí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé. Irú ìwéwèé bẹ́ẹ̀ lè mú kí o túbọ̀ ṣàṣeyọrí gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ ìhìn rere náà, èyí sì lè mú kí o túbọ̀ láyọ̀.—Òwe 21:5a.

6 Nítorí náà, tóo bá tún rí ẹni tó fetí sílẹ̀, má ṣe ronú pé á rọrùn fún ẹ láti rántí ẹni náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, kọ àkọsílẹ̀, ṣàtúnyẹ̀wò ohun tóo kọ sílẹ̀, fi ẹni náà sọ́kàn, kí o sì rí i dájú pé o padà lọ!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́