Padà Lọ Sọ́dọ̀ Ẹni Yòówù Tó Bá Fìfẹ́ Hàn, Bó Ti Wù Kí Ìfẹ́ Tó Fi Hàn Kéré Mọ
1 Ọ̀pọ̀ nínú wa ló wà nínú òtítọ́ lónìí nítorí pé ẹnì kan kíyè sí ìfẹ́ tá a ní fún ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, tó sì ní sùúrù láti padà wá sọ́dọ̀ wa, ó ṣeé ṣe kẹ́ni náà pààrà ọ̀dọ́ wa lọ́pọ̀ ìgbà, torí kó ṣáà lè rí i pé ìfẹ́ tá a ní yẹn jinlẹ̀ sí i. Bákan náà, ó yẹ ká fọkàn sí iṣẹ́ ìwàásù wa débi pé a ó máa fẹ́ láti padà lọ sọ́dọ̀ gbogbo ẹni tó bá ṣáà ti fìfẹ́ hàn sí ọ̀rọ̀ wa, bó ti wù kí ìfẹ́ tó fi hàn kéré mọ. Kò síyè méjì pé pípadà lọ sọ́dọ̀ àwọn tá a bá wàásù fún wà lára iṣẹ́ tá a gbà, pé ká sọ gbogbo èèyàn “di ọmọ ẹ̀yìn.”—Mát. 28:19, 20.
2 Fòye Mọ Ẹni Tó Nífẹ̀ẹ́ sí Ọ̀rọ̀ Wa: Kódà ká tiẹ̀ ní ẹni kan lóun ò gbàwé wa, a lè fòye mọ̀ bó bá nífẹ̀ẹ́ níwọ̀nba sí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tá à ń wàásù, bóyá nípa ìṣesí rẹ̀, nínú ọ̀nà tó ń gbà sọ̀rọ̀ tàbí irú èdè tó ń lò. Bá a bá rí i pé ẹnì kan fìfẹ́ hàn, a lè padà lọ sọ́dọ̀ ẹ̀. Ẹ̀ẹ̀márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni arákùnrin wa kan padà lọ sọ́dọ̀ ọkùnrin kan, síbẹ̀ tí ọkùnrin náà kọ̀ tí ò gbà ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́. Ìgbà tí arákùnrin wa tóó padà lọ nígbà kẹfà ló tó gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, tó sì wá gbà kí arákùnrin wa bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
3 Gbàrà tó o bá ti róye pé ẹnì kan máa nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa ni kó o ti padà lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ bóyá kó má ju ọjọ́ mélòó kan sígbà náà. Má ṣe gba “ẹni burúkú náà” láyè láti fa ohun tó o ti gbìn sọ́kàn ẹni yẹn tu. (Mát. 13:19) Tẹ́ ẹ bá jọ ṣàdéhùn pé wàá padà lọ, rí i dájú pé o padà lọ lákòókò tẹ́ ẹ fi àdéhùn sí.—Mát. 5:37.
4 Lẹ́nu Ìwàásù Òpópónà: Ṣó o máa ń sapá láti padà lọ sọ́dọ̀ ẹni tó bá fìfẹ́ hàn nígbà tó o bá ń wàásù ní òpópónà tàbí nígbà tó o bá ń jẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà? Lẹ́yìn ìjíròrò náà, o lè sọ pé: “Mo gbádùn ìjíròrò yìí gan-an. Ibo ni mo ti lè rí ẹ ká bàa lè sọ̀rọ̀ síwájú sí i?” Báwọn akéde kan bá rí i pé ó bójú mu, wọ́n máa ń fẹ́ láti fún ẹni tó fìfẹ́ hàn ní nọ́ńbà tẹlifóònù wọn tàbí kí wọ́n gba nọ́ńbà tẹlifóònù tiẹ̀. Báwọn èèyàn ṣe ń rí ẹ lẹ́nu ìwàásù òpópónà déédéé, ara lè tù wọ́n láti fún ọ ní nọ́ńbà tẹlifóònù wọn. Ká tiẹ̀ wá ní wọ́n kọ̀ láti fún ẹ ní àdírẹ́sì wọn, o ṣì lè gbìyànjú láti tẹ̀ síwájú nínú ìjíròrò náà nígbà míì tẹ́ ẹ bá tún jọ pàdé ní òpópónà.
5 Bá a bá rí ohun ọ̀gbìn kan tá a ti bomi rin dáadáa, tó hù tó sì ń dàgbà, inú wa máa ń dùn. Bákan náà, inú wa á dùn bá a bá padà lọ sọ́dọ̀ àwọn tá a wàásù fún tá a sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run. (1 Kọ́r. 3:6) Pinnu pé wàá máa padà lọ sọ́dọ̀ gbogbo ẹni yòówù tó bá fìfẹ́ hàn, bó ti wù kó kéré mọ.