Má Ṣe Fi Ìfẹ́ Àkọ́kọ́ Tó O Ní Sílẹ̀
1 Ní ọ̀rúndún kìíní, Jésù fún ìjọ Éfésù ní ìbáwí látọ̀run, ó ní: “Mo ní èyí lòdì sí ọ, pé ìwọ ti fi ìfẹ́ tí ìwọ ní ní àkọ́kọ́ sílẹ̀.” (Ìṣí. 2:4) Ẹ̀rí wà pé ọ̀pọ̀ ti fi ìfẹ́ àkọ́kọ́ tí wọ́n ní fún Jèhófà sílẹ̀. Nígbà tá a kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn aládùúgbò wa gidigidi, èyí ló sì ń jẹ́ ká lè máa fi ìtara wàásù nípa ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀. Kí ni ò ní jẹ́ ká fi ìfẹ́ àkọ́kọ́ tá a ní sílẹ̀ tá ò sì fi ní dẹwọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
2 Ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti Lílọ sí Ìpàdé: Kí ló mú ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti aládùúgbò wa nígbà tá a kọ́kọ́ mọ òtítọ́? Àwọn ẹ̀kọ́ tá a kọ́ nípa Jèhófà látinú Ìwé Mímọ́ ni, àbí? (1 Jòh. 4:16, 19) Nítorí náà, kí ìfẹ́ tá a ní bàa “lè túbọ̀ máa pọ̀ gidigidi síwájú àti síwájú,” a ní láti máa gba ìmọ̀ pípéye sínú, ká máa walẹ̀ jìn nínú àwọn “ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run.”—Fílí. 1:9-11; 1 Kọ́r. 2:10.
3 Kì í rọrùn rárá láti máa ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ déédéé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn tó kún fún àníyàn àti ìpínyà ọkàn yìí. (2 Tím. 3:1) Àfi ká yáa rí i pé a ya àkókò sọ́tọ̀ nínú ìgbòkègbodò wa láti lè máa fi kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Lílọ sí ìpàdé ìjọ déédéé tún ṣe pàtàkì, pàápàá léyìí tá a ti “rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.”—Héb. 10:24, 25.
4 Iṣẹ́ Òjíṣẹ́: Bá a bá ń fi ìtara lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù, ó máa ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ àkọ́kọ́ tá a ní fún Ọlọ́run pẹ̀dín. Bá a ṣe ń wàásù ìhìn rere, ṣe là ń rán ara wa létí àwọn ohun tó dáa tí Jèhófà ṣèlérí pé òun máa ṣe, èyí sì ń mú kí ìrètí tá a ní dá wa lójú sí i, bákan náà ló ń mú kí iná ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà máa jó lala. Ìwádìí tá a máa ń ṣe kí àwọn ẹ̀kọ́ inú Bíbélì tá a máa ń fi kọ́ àwọn èèyàn lè yé àwa fúnra wa yékéyéké sí i máa ń mú kí ìgbàgbọ́ tiwa fúnra wa jinlẹ̀.—1 Tím. 4:15, 16.
5 Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ sí ohun gbogbo títí kan ìfẹ́ tá a ní fún un. (Ìṣí. 4:11) Má ṣe jẹ́ kí ìfẹ́ náà tutù. Bó ò bá fẹ́ kí ìfẹ́ rẹ àkọ́kọ́ pẹ̀dín, sapá láti máa dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, láti máa wà ní ìpàdé déédéé àti láti máa fi ìtara sọ ohun tó o mọ̀ pó ṣe pàtàkì jù fáwọn ẹlòmíì.—Róòmù 10:10.