ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/06 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 11
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 18
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 25
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 1
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
km 12/06 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 11

Orin 174

15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù December sílẹ̀. Jíròrò “Àpéjọ Àkànṣe Tó Ń Bọ̀ Lọ́nà.” Sọ ọjọ́ tí àpéjọ àkànṣe náà máa bọ́ sí fáwọn ará bẹ́ ẹ bá mọ̀ ọ́n. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ December 15 àti Jí! October-December. Nínú ọ̀kan lára àṣefihàn náà, fi hàn báwọn ará ṣe lè fún ẹni tí ò fẹ́ gbọ́rọ̀ wọn lésì, tó wá sọ pé “Emi kò nífẹ̀ẹ́ sí i.”—Wo ìwé Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ìwé 8.

15 min: Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ti Ọdún 2007. Àsọyé àti ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ máa bójú tó. Jíròrò àwọn kókó tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ yín tó wà nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti October 2006. Ṣàlàyé fún àwùjọ pé alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ ò ní máa kọ́kọ́ ṣèfilọ̀ ànímọ́ ọ̀rọ̀ sísọ tí akẹ́kọ̀ọ́ máa ṣiṣẹ́ lé lórí. Níwọ̀n bá a ti máa parí kíka Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù láti Aísáyà orí 24 títí dé ìparí Málákì lọ́dún 2007, àwọn arákùnrin tí wọ́n máa ń bójú tó àwọn kókó pàtàkì látinú Bíbélì àtàwọn tó bá lóhùn sí i á jàǹfààní púpọ̀ nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ilé ẹ̀kọ́ ti ọdún yìí nítorí pé àwọn ìtẹ̀jáde wa kan wà tó ṣàlàyé àwọn ìwé àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì yìí yékéyéké. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn wọ̀nyí: ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́, ọ̀dọ́ tó ń tẹ̀ síwájú nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ àti ẹni tó ti kẹ́kọ̀ọ́ jìnnà. Ní kí wọ́n sọ ọ̀nà tí ilé ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ti gbà ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lè fọwọ́ tó ṣe pàtàkì mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti ọ̀nà tí wọ́n gbà ń jọ́sìn Ọlọ́run. Gba àwùjọ níyànjú pé kí wọ́n má ṣe kẹ̀rẹ̀ nínú bí wọ́n ṣe ń bójú tó iṣẹ́ tí wọ́n bá fún wọn nínú ilé ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, kí wọ́n máa lóhùn sípàdé tó bá kan àwọn kókó pàtàkì látinú Bíbélì, kí wọ́n sì máa fi àwọn àbá tí wọ́n bá ń fúnni lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ látinú ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run sílò.

15 min: “Má Ṣe Fi Ìfẹ́ Àkọ́kọ́ Tó O Ní Sílẹ̀.”a Bí àyè bá ṣe wà sí, ní kí àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a fà yọ.

Orin 193 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 18

Orin 150

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Mẹ́nu ba ìṣètò tá a dìídì ṣe fún iṣẹ́ ìsìn pápá lóṣù December 25 àti January 1.

15 min: “Padà Lọ Sọ́dọ̀ Ẹni Yòówù Tó Bá Fìfẹ́ Hàn, Bó Ti Wù Kí Ìfẹ́ Tó Fi Hàn Kéré Mọ.”b Ní kí àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí ọgbọ́n tí wọ́n dá sí i tó fi ṣeé ṣe fún wọn láti gba àdírẹ́sì lọ́wọ́ ẹni tí wọ́n wàásù fún láìjẹ́-bí-àṣà tàbí ní òpópónà, kí wọ́n sì sọ àwọn ìrírí tó lè fúnni níṣìírí tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n padà ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. O lè ti sọ fún ẹnì kan tàbí méjì pé kí wọ́n múra ìdáhùn wọn sílẹ̀.

20 min: “A Lè Borí Àdánwò Èyíkéyìí!” Àsọyé tá a gbé ka àpilẹ̀kọ kan nínú Ilé Ìṣọ́ June 15, 2005, ojú ìwé 30 àti 31. Fún àwùjọ níṣìírí nípasẹ̀ àsọyé yìí, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé gbogbo wa la ní àdánwò tá à ń fara dà.

Orin 182 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 25

Orin 210

15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Jíròrò “Àpéjọ Àyíká Tó Ń Bọ̀ Lọ́nà,” kó o sì sọ ọjọ́ tó máa bọ́ sí fáwọn ará bẹ́ ẹ bá mọ̀ ọ́n. Ka ìròyìn ìnáwó àti lẹ́tà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ December 1 àti Jí! January-March. Ní ìparí àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, bi onílé ní ìbéèrè tó ń múni ronú jinlẹ̀ tó máa dáhùn látinú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni nígbà tó o bá padà lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.

15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.

15 min: Ìròyìn Nípa Bí Iṣẹ́ Ìwàásù Ṣe Ń Tẹ̀ Síwájú. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tó dá lórí ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, èyí tó bẹ̀rẹ̀ látorí àkọlé kékeré tó wà lójú ìwé 83 sí ibi tí orí náà parí sí lójú ìwé 91.

Orin 72 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 1

Orin 158

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù December sílẹ̀.

35 min: “Ojú Wo Ló Yẹ Kí N Fi Wo Àwọn Oògùn Tó Ní Èròjà Ẹ̀jẹ̀ Nínú, Kí Ló sì Yẹ Kí N Ṣe Báwọn Dókítà Bá Fẹ́ Fi Ẹ̀jẹ̀ Mi Tọ́jú Mi Lọ́nà Èyíkéyìí?” Ìjíròrò lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Jẹ́ kí wọ́n ṣe àṣefihàn ṣókí tó dá lórí ìpínrọ̀ àkọ́kọ́. Lẹ́yìn náà ni kó o wá béèrè àwọn ìbéèrè mẹ́ta tá a fi lẹ́tà dúdú kirikiri tẹ̀ kó o sì jíròrò àwọn ìdáhùn tó wà níbẹ̀. Jíròrò àwọn ìwé ìbéèrè méjèèjì pẹ̀lú àwùjọ. Ṣàlàyé kúnnákúnná lórí èròjà ẹ̀jẹ̀ táwọn Kristẹni kì í gbà àtàwọn ibi tó ti yẹ kí wọ́n dá pinnu irú ìtọ́jú tí wọ́n fẹ́. Rí i pé ìwé Ìtọ́ni Nípa Bí A Ṣe Máa Kọ Nǹkan Sínú Káàdì DPA, èyí tá a tún tẹ̀, wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Kó o wá ṣàlàyé báwọn ará ṣe máa kọ ohun tó yẹ sínú káàdì DPA wọn, kó o sì gba ẹnikẹ́ni tí kò bá tíì kọ ọ̀rọ̀ sínú káàdì tiẹ̀ níyànjú pé kó ṣe bẹ́ẹ̀. Sọ pé káwọn alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ ran gbogbo àwọn akéde tó wà ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ wọn lọ́wọ́ láti kọ ọ̀rọ̀ sínú káàdì náà. Kí àwọn tó ti kọ ọ̀rọ̀ sí káàdì kan tẹ́lẹ̀ máà tún òmíràn kọ àyàfi bí ti tẹ́lẹ̀ yẹn ò bá dáa mọ́.

Orin 120 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́