A Gbọ́dọ̀ Bomi Rin Irúgbìn Kí Ó Lè Dàgbà
1. Kí la gbọ́dọ̀ máa bomi rin kó lè dàgbà?
1 Bí èèyàn bá gbin irúgbìn sínú ọgbà, ó gbọ́dọ̀ máa bomi rin ín, kí irúgbìn náà lè dàgbà. Bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀rọ̀ irúgbìn òtítọ́ tá a gbìn sọ́kàn àwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa ṣe rí. (1 Kọ́r. 3:6) Kí wọ́n lè fìdí múlẹ̀, kí wọ́n dàgbà, kí wọ́n sì gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀, a gbọ́dọ̀ ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ wọn, ká lè tipa bẹ́ẹ̀ bomi rin irúgbìn ìṣàpẹẹrẹ yìí nípa lílo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
2. Báwo la ṣe lè fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ fún ìpadàbẹ̀wò?
2 Béèrè Ìbéèrè Kan: Nígbà tó o bá ń múra bó o ṣe máa gbọ́rọ̀ kalẹ̀, o tún lè ronú nípa ìbéèrè tó lè múni nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀, tí o máa dáhùn nígbà tó o bá pa dà lọ bẹ ẹni yẹn wò. Béèrè ìbéèrè náà nígbà tó o bá fẹ́ parí ọ̀rọ̀ rẹ, kó o sì ṣètò tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ láti pa dà lọ. Àwọn kan ti rí i pé ó ṣàǹfààní láti lo kókó kan nínú ìwé Kí Ní Bíbélì Fi Kọ́ni, kí wọ́n bàa lè fi bí a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì han ẹni náà.
3. Kí làwọn ohun téèyàn lè kọ sílẹ̀ nípa ẹnì kan tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa?
3 Ṣe Àkọsílẹ̀: Gbàrà tó o bá ti parí ọ̀rọ̀ pẹ̀lú ẹni kan tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ bá pàdé ni kó o ti kọ àwọn ìsọfúnni nípa ẹni yẹn sílẹ̀. Kọ orúkọ ẹni náà àti àdírẹ́sì rẹ̀. Ó tún dára kó o kọ ọjọ́ àti àkókò tó o bá ẹni náà sọ̀rọ̀ àti ohun tẹ́ ẹ sọ̀rọ̀ lé lórí, tó o bá sì fún un ní ìwé, kọ irú ìwé tó jẹ́. Ǹjẹ́ ó sọ ẹ̀sìn tó ń ṣe? Ṣé ó ní ìdílé? Ṣé ó sọ ohun tó nífẹ̀ẹ́ sí àtohun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn? Irú àwọn ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ á jẹ́ kó o lè mọ ohun tí ọ̀rọ̀ rẹ máa dá lé nígbà tó o bá pa dà lọ sọ́dọ̀ ẹni náà. Láfikún sí i, kọ ìgbà tẹ́ ẹ fi àdéhùn sí pé wàá pa dà wá àti ìbéèrè tó o fẹ́ dáhùn.
4. Kí nìdí tí a kò fi gbọ́dọ̀ jẹ́ kó sú wa láti máa pa dà lọ sọ́dọ̀ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa?
4 Má Ṣé Jẹ́ Kó Sú Ẹ: Sátánì kò ní yéé sapá láti ‘mú ọ̀rọ̀ tí a gbìn sọ́kàn ẹnì kan kúrò.’ (Máàkù 4:14, 15) Torí náà, tó bá ṣòro fún ẹ láti bá ẹnì kan tó fìfẹ́ hàn nílé, má ṣe jẹ́ kí ìyẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ẹ. Ǹjẹ́ o lè kọ lẹ́tà sí i tàbí kó o kọ ìwé pélébé kan sílẹ̀ dè é? Aṣáájú-ọ̀nà kan bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ obìnrin kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́nu ọ̀nà, àmọ́ nígbà tó yá, kì í bá obìnrin náà nílé mọ́, torí náà ó kọ lẹ́tà kan sí i. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín tí arábìnrin náà wá bá obìnrin yẹn nílé, obìnrin náà sọ bí ìfẹ́ tí arábìnrin náà fi hàn sí òun ṣe wú òun lórí tó. Bá a ṣe ń bomi rin irúgbìn òtítọ́, inú wa yóò máa dùn bá a ṣe ń rí wọn tí wọ́n ń dàgbà nípa tẹ̀mí, tí wọ́n sì ń “so èso ní ìlọ́po ọgbọ̀n àti ọgọ́ta àti ọgọ́rùn-ún.”—Máàkù 4:20.