Ìgbà Wo Ló Yẹ Ká Pa Dà Lọ Sọ́dọ̀ Àwọn Tó Fetí sí Ọ̀rọ̀ Wa?
1. Kí ni sísọni dọmọ ẹ̀yìn ní nínú?
1 Sísọni di ọmọ ẹ̀yìn gba pé kéèyàn pa dà lọ sọ́dọ̀ ẹnikẹ́ni tó fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ìjọba Jèhófà. (Mát. 28:19, 20) Lọ́pọ̀ ìgbà, bí àwa àti ẹni tó fetí sọ́rọ̀ wa bá ṣe ráyè sí ló máa ń pinnu ìgbà tó dáa jù lọ láti pa dà lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Kí nìdí tí kò fi yẹ kó pẹ́ ká tó pa dà lọ sọ́dọ̀ ẹni tá a wàásù fún?
2, 3. Kí nìdí tó fi yẹ ká tètè pa dà lọ?
2 Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Tètè Pa Dà Lọ? Iṣẹ́ ìwàásù “ìhìn rere ìjọba yìí” kò ní pẹ́ dópin, ètò nǹkan ìsinsìnyí sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kógbá sílé. (Mát. 24:14; 1 Pét. 4:7) Torí náà, ní báyìí táwọn tó ń fetí sí ìwàásù wa ṣì wà ní “ọjọ́ ìgbàlà,” ó yẹ ká fetí sí ọ̀rọ̀ ìṣítí náà pé ká ‘wàásù ọ̀rọ̀ náà ní kánjúkánjú,’ èyí sì gba pé ká má ṣe jẹ́ kó pẹ́ ká tó pa dà lọ sọ́dọ̀ àwọn tó fetí sí ìwàásù wa.—2 Kọ́r. 6:1, 2; 2 Tím. 4:2.
3 Sátánì ń wá ọ̀nà láti mú irúgbìn Ìjọba Ọlọ́run tá a bá gbìn sọ́kàn àwọn èèyàn kúrò. (Máàkù 4:14, 15) Àwọn tó sábà máa ń kẹ́gàn àwọn tó bá fetí sí ìwàásù wa ni ìdílé wọn, àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ àtàwọn míì. Torí náà, tá a bá tètè pa dà lọ, a ó lè máa bá ìjíròrò wa lọ pẹ̀lú wọn kó tó di pé àwọn míì paná ìfẹ́ tí wọ́n ní.
4. Kí la lè ṣe nígbà tá a bá wàásù fún ẹnì kan tá mú ká lè máa bá ìjíròrò wa lọ nígbà ìpadàbẹ̀wò?
4 Ẹ Jọ Ṣàdéhùn: Ohun tó dáa jù ni pé kẹ́ ẹ jọ ṣe àdéhùn kan pàtó nípa ìgbà tó o máa pa dà wá kó o tó fi ibẹ̀ sílẹ̀ nígbà àkọ́kọ́. Bi í ní ìbéèrè kan tó o máa dáhùn nígbà tó o bá pa dà lọ. Ó ṣe pàtàkì pé ká máa ní àkọsílẹ̀ tó péye nípa àwọn tá a bá wàásù fún. Tó o bá máa ráyè, o lè bi onítọ̀hún bóyá kó o pa dà wá lọ́jọ́ kejì tàbí kó máà pẹ́ sígbà yẹn. Tó bá jẹ́ pé òpin ọ̀sẹ̀ lo kọ́kọ́ wàásù fún un, tó sì jẹ́ pé onítọ̀hún máa ń ṣiṣẹ́ láàárín ọ̀sẹ̀, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òpin ọ̀sẹ̀ tó máa tẹ̀ lé e ló máa fẹ́ kó o pa dà wá. Tí o bá bá ẹnì kan ṣàdéhùn, rí i dájú pé àdéhùn náà kò yẹ̀.—Mát. 5:37.
5. Tá a bá ń tètè pa dà lọ, báwo nìyẹn á ṣe jẹ́ ká pa àṣẹ Jésù mọ́ pé ká máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn?
5 Ọ̀pọ̀ àǹfààní ló wà nínú ká tètè pa dà lọ sọ́dọ̀ àwọn tó fetí sọ́rọ̀ wa. Torí náà, ṣe àdéhùn kó o sì tètè pa dà lọ, torí pé “àkókò tí ó ṣẹ́ kù ti dín kù.” (1 Kọ́r. 7:29) Tá a bá ń tètè pa dà lọ sọ́dọ̀ àwọn tó fetí sí ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run, iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa á túbọ̀ máa méso jáde.