Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ February 24
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ FEBRUARY 24
Orin 101 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 3 ìpínrọ̀ 11 sí 18 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 32-35 (10 min.)
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run (20 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Sátidé Àkọ́kọ́. Àsọyé. Sọ ètò tí ìjọ ṣe fún jíjáde òde ẹ̀rí ní Sátidé àkọ́kọ́ lóṣù March. Lo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó wà lójú ìwé 4 láti ṣe àṣefihàn kan.
15 min: Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Pé Ká Máa Mú Sùúrù Ká Má sì Jẹ́ Kó Sú Wa. Ìjíròrò tá a gbé ka ìwé Ọdọọdún 2013, ojú ìwé 45, ìpínrọ̀ 1, sí ojú ìwé 46, ìpínrọ̀ 1; àti ojú ìwé 136 sí 137. Ní kí àwọn ará sọ ẹ̀kọ́ tí wọ́n rí kọ́.
10 min: “A Máa Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Pín Ìwé Ìkésíni Síbi Ìrántí Ikú Kristi Ní March 22.” Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ni kó sọ àsọyé yìí. Fún àwọn ará ní ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan ìwé ìkésíni náà, kó o sì jíròrò ohun tó wà nínú rẹ̀. Jíròrò àwọn kókó pàtàkì látinú ìtọ́ni tó wà nínú lẹ́tà tá a fi ránṣẹ́ sí àwọn alàgbà, kó o sì sọ ètò tí ìjọ ṣe kẹ́ ẹ lè kárí ìpínlẹ̀ ìwàásù yín.
Orin 109 àti Àdúrà