Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣe àtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní February 24, 2014.
Kí ni Sátánì mú kí Éfà pọkàn pọ̀ lé lórí, kí sì ni bí Éfà ṣe jẹ èso tí Ọlọ́run kà léèwọ̀ náà fi hàn? (Jẹ́n. 3:6) [Jan. 6, w11 5/15 ojú ìwé 16 sí 17 ìpínrọ̀ 5]
. Kí ló ṣeé ṣe kó ti mú kí Ébẹ́lì ní ìgbàgbọ́ tó fẹsẹ̀ múlẹ̀, kí sì ni àbájáde rẹ̀? (Jẹ́n. 4:4, 5; Héb. 11:4) [Jan. 6, w13 1/1 ojú ìwé 12 ìpínrọ̀ 3; ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 4 sí 5]
Báwo làwọn òbí ṣe lè dáàbò bo àwọn ọmọ wọn, tí kò fi ní máa wù wọ́n láti dà bí ‘àwọn alágbára ńlá’ àti “àwọn ọkùnrin olókìkí”? (Jẹ́n. 6:4) [Jan. 13, w13 4/1 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 2]
Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Lọ́ọ̀tì àti ìyàwó rẹ̀ bó ṣe wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 19:14-17 àti 26? [Jan. 27, w03 1/1 ojú ìwé 16 sí 17 ìpínrọ̀ 20]
Báwo ni Ábúráhámù ṣe fi hàn pé òun ní ìgbàgbọ́ nínú àjíǹde àti nínú ìlérí tí Jèhófà ṣe fún un pé irú ọmọ náà máa wá nípasẹ̀ Ísákì? (Jẹ́n. 22:1-18) [Feb. 3, w09 2/1 ojú ìwé 18 ìpínrọ̀ 4]
Òótọ́ pàtàkì wo la rí kọ́ nínú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 25:23, tó sọ pé “ẹ̀gbọ́n ni yóò sì sin àbúrò”? [Feb. 10, w03 10/15 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 2]
Kí ni ìtumọ̀ àlá tí Jékọ́bù lá tó ní ín ṣe pẹ̀lú àkàsọ̀, báwọn Bíbélì kan ṣe pè é? (Jẹ́n. 28:12, 13) [Feb. 10, w04 1/15 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 6]
Kí nìdí tí Jékọ́bù fi fẹ́ gba ère tẹ́ráfímù tí wọ́n jí náà pa dà? (Jẹ́n. 31:30-35) [Feb. 17, it-2-E ojú ìwé 186 ìpínrọ̀ 2]
Kí la kọ́ nínú ìdáhùn tí áńgẹ́lì kan fún Jékọ́bù bó ṣe wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 32:29? [Feb. 24, w13 8/1 ojú ìwé 10]
Kí ni ọ̀nà kan tá a lè gbà yẹra fún irú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dínà? (Jẹ́n. 34:1, 2) [Feb. 24, w01 8/1 ojú ìwé 20 sí 21]