A Ní Àǹfààní Púpọ̀ Sí I Láti Yin Jèhófà
1. Ètò tuntun wo la ṣe tó máa jẹ́ ká lè ní àǹfààní púpọ̀ sí i láti yin Jèhófà?
1 Ní oṣù March ọdún tá a wà yìí, a bẹ̀rẹ̀ ètò tuntun kan tó máa jẹ́ kó ṣeé ṣe fún àwọn akéde tó bá ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ láti máa lo ọgbọ̀n [30] wákàtí ní gbogbo oṣù March àti April àti láwọn oṣù tí alábòójútó àyíká bá bẹ ìjọ yín wò. Bí ọ̀sẹ̀ ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká sí ìjọ yín bá bẹ̀rẹ̀ ní ìparí oṣù kan tó sì wọ ìbẹ̀rẹ̀ oṣù míì, àwọn aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tó fẹ́ lo ọgbọ̀n wákàtí lè yan ọ̀kan nínú oṣù méjèèjì. Láfikún sí i, gbogbo aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ló máa láǹfààní láti wà ní ìpàdé tí alábòójútó àyíká máa bá àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe àtàwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé ṣe látìbẹ̀rẹ̀ dópin. Torí náà, ẹni tí kò bá ṣeé ṣe fún láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ oní àádọ́ta [50] wákàtí ṣì lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ọlọ́gbọ̀n [30] wákàtí kó lè láǹfààní púpọ̀ sí i láti yin Jèhófà. Kódà, ó lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ ọlọ́gbọ̀n [30] wákàtí ní ẹ̀ẹ̀mẹrin lọ́dún!—Sm. 109:30; 119:171.
2. Àǹfààní wo làwọn tó bá ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ nígbà ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká máa gbádùn?
2 Nígbà Ìbẹ̀wò Alábòójútó Àyíká: Ní báyìí, àwọn akéde púpọ̀ sí i máa lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ nígbà ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká, wọ́n á sì lè gbádùn pàṣípààrọ̀ ìṣírí nígbà tí wọ́n bá bá alábòójútó àyíká ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. (Róòmù 1:11, 12) Ọ̀pọ̀ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ sì lè gbàyè ọjọ́ kan lẹ́nu iṣẹ́ wọn láàárín ọ̀sẹ̀ kí wọ́n lè ráyè bá alábòójútó àyíká ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ láàárín ọ̀sẹ̀ tún lè béèrè lọ́wọ́ alábòójútó àyíká bóyá àwọn lè bá a ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí lọ́jọ́ Saturday tàbí Sunday. Láfikún sí i, ó múnú ẹni dùn gan-an láti mọ̀ pé àwọn akéde tó bá ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù tí alábòójútó àyíká bá bẹ ìjọ yín wò lè wá sí ìpàdé tí alábòójútó àyíká máa bá àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe àtàwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé ṣe!
3. Kí nìdí tí ìgbà Ìrántí Ikú Kristi fi jẹ́ àkókò tó dáa gan-an láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́?
3 Lóṣù March àti April: Àwọn aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tí wọ́n sábà máa ń lo ọgbọ̀n [30] wákàtí lásìkò Ìrántí Ikú Kristi ti wá ní àǹfààní láti sọ ẹbọ ìyìn wọn di ìlọ́po méjì! (Héb. 13:15) Àǹfààní ńlá gbáà la ní lóṣù March àti April láti máa fi ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Láwọn oṣù méjèèjì yìí, a máa ń ké sí àwọn èèyàn láti wá sí Ìrántí Ikú Kristi. Ọ̀pọ̀ akéde ló máa ń ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lásìkò yẹn, torí náà, a máa láǹfààní láti bá onírúurú àwọn akéde ṣiṣẹ́. Lẹ́yìn tá a bá parí Ìrántí Ikú Kristi, a máa ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó bá wá, a sì tún máa ń pè wọ́n láti wá gbọ́ àkànṣe àsọyé. Ǹjẹ́ ìwọ náà á fi gbogbo okun rẹ lo àwọn àǹfààní tó ṣí sílẹ̀ yìí láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́?—Lúùkù 6:45.