Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 24
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JUNE 24
Orin 123 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 11 ìpínrọ̀ 1 sí 8 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ìṣe 8-10 (10 min.)
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run (20 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: “Fún Wọn Ní Ìwé Ìròyìn Méjèèjì, àmọ́ Àkòrí Kan Ni Kó O Sọ̀rọ̀ Lé Lórí.” Àsọyé. Lẹ́yìn àsọyé náà, lo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó wà lójú ìwé 4 láti ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Sátidé àkọ́kọ́ lóṣù July.
10 min: Iṣẹ́ Wa Kì Í Ṣe Asán. (Héb. 6:10) Ìjíròrò tó dá lórí Ìwé Ọdọọdún 2013, ojú ìwé 113, ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 115, ìpínrọ̀ 1 àti ojú ìwé 117 ìpínrọ̀ 1. Ní kí àwọn ará sọ ẹ̀kọ́ tí wọ́n rí kọ́.
10 min: Ìwé Tá A Máa Lò Lóṣù July àti August. Ìjíròrò. Ní ṣókí, sọ ohun tó wà nínú àwọn ìwé tá a máa lò, kó o sì ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè fi méjì lára ìwé náà lọni. Kí ọ̀kan nínú àṣefihàn náà dá lórí ìwé Ìròyìn Ayọ̀, ẹ lo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó wà lójú ìwé 4 tàbí ọ̀kan lára èyí tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù March 2013.
Orin 129 àti Àdúrà