Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 27
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ FEBRUARY 27
Orin 135 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 17 ìpínrọ̀ 8 sí 14, àti àpótí tó wà ní ojú ìwé 137 (25 min.)
Bíbélì kíkà: Aísáyà 63-66 (10 min.)
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run (20 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Àwọn Ìfilọ̀. Lo àbá tó wà lójú ìwé 4 láti ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Saturday àkọ́kọ́ ní oṣù March.
25 min: Ẹ Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Ní Ìgbàgbọ́ Nínú Bíbélì. Ìjíròrò tá a gbé ka ìwé pẹlẹbẹ náà, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, ojú ìwé 14 sí 17. Ṣe àṣefihàn kan tàbí méjì tó máa jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè fèrò wérò pẹ̀lú ẹnì kan, kí á sì mú kí ó dá ẹnì náà lójú pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ tó wà nínú Bíbélì.
Orin 100 àti Àdúrà