Orin 100
Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Jèhófà Ni Wá!
1. Àwa ọmọ ogun Jáà,
Bọ́ lọ́wọ́ Èṣù,
A ńwàásù Ìjọba náà,
Tí Jésù ńṣàkóso.
Bí a ṣe ńtẹ̀ síwájú,
Tinútinú wa,
Ìpinnu wa ni pé
Aò ní bẹ̀rù láé.
(ÈGBÈ)
Ọmọ ogun Jáà ni wá;
Kristi la ńtẹ̀ lé.
A ńfayọ̀ kéde pé,
“’Jọba Jáà bẹ̀rẹ̀.”
2. Àwa ni ìránṣẹ́ Jáà,
Tá ńwágùntàn rẹ̀,
Tó sọ nù lóun nìkan,
Tó tún ń kérora.
Àwọn là ńwá láti bọ́,
A ńbẹ̀ wọ́n wò ṣáá;
A ń pè wọ́n wá sí
Gbọ̀ngàn Ìjọba.
(ÈGBÈ)
Ọmọ ogun Jáà ni wá;
Kristi la ńtẹ̀ lé.
A ńfayọ̀ kéde pé,
“’Jọba Jáà bẹ̀rẹ̀.”
3. Àwa lọmọ ogun Jáà
Tí Kristi ńdarí,
A dìhámọ́ra ogun,
A sì tún dúró gbọn-in.
Àmọ́ ó yẹ ká ṣọ́ra,
Ká dúró ṣinṣin.
Tí àdánwò bá dé,
Ká jẹ́ olóòótọ́.
(ÈGBÈ)
Ọmọ ogun Jáà ni wá;
Kristi la ńtẹ̀ lé.
A ńfayọ̀ kéde pé,
“’Jọba Jáà bẹ̀rẹ̀.”
(Tún wo Éfé. 6:11, 14; Fílí. 1:7; Fílém. 2.)