Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣe àtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní February 27, 2012. A fi déètì ọ̀sẹ̀ tá a máa jíròrò kókó kọ̀ọ̀kan sínú àwọn ìbéèrè náà, kó bàa lè ṣeé ṣe fún wa láti ṣèwádìí nípa wọn nígbà tá a bá ń múra ìpàdé ilé ẹ̀kọ́ sílẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.
1. Ǹjẹ́ ó tọ̀nà láti sọ pé àánú Jèhófà ń pẹ̀rọ̀ sí ìdájọ́ òdodo rẹ̀? (Aísá. 30:18) [Jan. 9, w02 3/1 ojú ìwé 30]
2. Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nínú bí wọ́n ṣe gbaṣẹ́ ìríjú lọ́wọ́ Ṣébínà tó jẹ́ ìríjú Hesekáyà? (Aísá. 36:2, 3, 22) [Jan. 16, w07 1/15 ojú ìwé 8 ìpínrọ̀ 6]
3. Kí la rí kọ́ nípa béèyàn ṣe lè yanjú ìṣòro tá a bá wo àkọ́sílẹ̀ tó wà nínú Aísáyà 37:1, 14-20? [Jan. 16, w07 1/15 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 1 àti 2]
4. Báwo ni àkàwé tó wà nínú Aísáyà 40:31 ṣe ń fún àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà níṣìírí? [Jan. 23, w96 6/15 ojú ìwé 10 àti 11]
5. Ìkọlù tí ń bọ̀ wo ló mú kí ọ̀rọ̀ Jèhófà tó wà ní Aísáyà 41:14 jẹ́ ìṣírí gan-an lóde òní? [Jan. 23, ip-2 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 16]
6. Báwo ni a ṣe lè jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé à “ń lépa òdodo”? (Aísá. 51:1) [Feb. 6, ip-2 ojú ìwé 165 sí 166 ìpínrọ̀ 2]
7. Àwọn wo ni “ọ̀pọ̀lọpọ̀” tí ìwé Aísáyà 53:12 sọ nípa rẹ̀, ẹ̀kọ́ tó ń mọ́kàn ẹni yọ̀ wo la sì rí kọ́ nínú ohun tí Jèhófà ṣe fún wọn? [Feb. 13, ip-2 ojú ìwé 213 ìpínrọ̀ 34]
8. Ìrírí wo ni àwọn èèyàn Jèhófà ti ní láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí bí ìwé Aísáyà 60:17 ṣe ṣàpẹẹrẹ rẹ̀? [Feb. 20, ip-2 ojú ìwé 316 ìpínrọ̀ 22]
9. Kí ni ìjẹ́pàtàkì “ọdún ìtẹ́wọ́gbà” tí Ọlọ́run yan Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n pòkìkí? (Aísá. 61:2) [Feb. 20, ip-2 ojú ìwé 324 àti 325 ìpínrọ̀ 7 àti 8]
10. Àgbàyanu ànímọ́ Jèhófà wo ni ìwé Aísáyà 63:9 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? [Feb. 27, w03 7/1 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 22 àti 23]