Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 5
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MARCH 5
Orin 103 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 17 ìpínrọ̀ 15 sí 19 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jeremáyà 1-4 (10 min.)
No. 1: Jeremáyà 3:14-25 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ìdí Tí A Kì Í Fi Í Tijú Láti Jẹ́ Orúkọ Mọ́ Jèhófà—Aísá. 43:12 (5 min.)
No. 3: Kì Í Ṣe Ọlọ́run Kan Náà Ni Gbogbo Èèyàn Ń Sìn—td 34E (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn Ìfilọ̀.
10 min: Jàǹfààní Látinú Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2012. Ní ṣókí, fi ọ̀rọ̀ ìṣáájú tó wà nínú ìwé náà sọ àsọyé. Lẹ́yìn náà ní káwọn ará sọ ìgbà tí wọ́n máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ojoojúmọ́, kí wọ́n sì sọ àǹfààní tí wọ́n ti jẹ. Ní ìparí, jíròrò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2012.
10 min: Àwọn Ọ̀ràn Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ.
10 min: Àwọn Àbá Tá A Lè Lò Láti Fi Ìwé Ìròyìn Lọni Ní Oṣù March. Ìjíròrò. Fi ìṣẹ́jú kan tàbí méjì tọ́ka sí àwọn àpilẹ̀kọ tó lè fa àwọn èèyàn mọ́ra ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Lẹ́yìn náà, lo àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Ilé Ìṣọ́ yìí, kó o sì ní kí àwọn ará sọ àwọn ìbéèrè tó lè mú kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wọn, kí wọ́n sì sọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n á fi ti ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn. Ohun kan náà ni kó o ṣe nípa àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Jí! January–March, tí àkókò bá ṣì wà, ẹ tún lè jíròrò àpilẹ̀kọ mìíràn nínú ìwé ìròyìn méjèèjì. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà lọni.
Orin 75 àti Àdúrà