Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní February: Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé tàbí Sún Mọ́ Jèhófà. March: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà àkọ́kọ́ tẹ́ ẹ bá wàásù fún ẹnì kan. April àti May: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Ẹ fún ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ yín ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́?, kẹ́ ẹ sì sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tàbí àwọn àpéjọ míì tí ètò Ọlọ́run ṣètò àmọ́ tí wọn kò tíì máa dara pọ̀ mọ́ ìjọ déédéé, ẹ ní in lọ́kàn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn nínú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni.
◼ Òpin ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé Ìrántí Ikú Kristi la máa sọ àkànṣe àsọyé. Ẹṣin ọ̀rọ̀ àsọyé náà ni, “Ǹjẹ́ Òpin Ti Sún Mọ́lé Ju Bó O Ṣe Rò Lọ?”
◼ Nígbàkigbà tó o bá ń ṣètò láti rìnrìn àjò lọ sí orílẹ̀-èdè tí kò sí lára àwọn orílẹ̀-èdè tá a máa ń tẹ ìròyìn iṣẹ́ ìsìn wọn jáde lọ́dọọdún, tàbí tí àdírẹ́sì rẹ̀ kò sí lára àwọn àdírẹ́sì àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní ojú ìwé tó kẹ́yìn nínú ìwé ọdọọdún wa, ìyẹn Yearbook, jọ̀wọ́ rí i pé o kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè rẹ láti mọ ohun tó yẹ kó o ṣọ́ra fún tàbí kó o lè mọ̀ bóyá àwọn ìtọ́ni kan wà tó yẹ kó o tẹ̀ lé. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti fi òfin de iṣẹ́ wa ní orílẹ̀-èdè náà. (Mát. 10:16) Ó lè jẹ́ ohun tí kò bọ́gbọ́n mu pé kí ẹnì kan tó ń ṣèbẹ̀wò sí àwọn orílẹ̀-èdè bẹ́ẹ̀ kàn sí àwọn ará tàbí ìjọ tó wà níbẹ̀. O tún lè rí ìtọ́ni gbà nípa bó o ṣe lè jẹ́rìí lọ́nà àìjẹ́ bí àṣà tàbí bó o ṣe lè tọ́jú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó o ní lọ́wọ́. Tó o bá tẹ̀ lé ìtọ́ni tí wọ́n fún ọ, o ò ní kó sínú ìṣòro, bẹ́ẹ̀ sì ni o kò ní ṣàkóbá fún iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run tí àwọn ará ń ṣe ní orílẹ̀-èdè tó o ṣèbẹ̀wò sí náà.—1 Kọ́r. 14:33, 40.