Orin 75
Ìdí Ayọ̀ Wa Pọ̀
1. Ìdí ayọ̀ wa yìí pọ̀ púpọ̀,
Ó ńbúrẹ́kẹ gan-an bí ọrọ̀.
Ohun fífanimọ́ra gbogbo
Ńrọ́ wọlé ní gbogbo ayé.
Ojúlówó ni ìdùnnú wa,
Gbòǹgbò rẹ̀ wá ń’nú Bíbélì.
A ńkọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀ lójoojúmọ́;
Ìgbàgbọ́ máa ńbá gbígbọ́ rìn.
Ìdí ayọ̀ wa jinlẹ̀ púpọ̀,
Ṣe ló ńkẹ̀ bí ẹyín iná.
Bíṣòro, àdánwò bá tiẹ̀ dé,
Jèhófà ń mú wa dúró.
(ÈGBÈ)
Ọlọ́run wa ni ayọ̀ wa,
Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ńdùn mọ́ wa.
Èrò rẹ̀ jinlẹ̀, iṣẹ́ rẹ̀ tóbi,
Oore àtagbára rẹ̀ pọ̀!
2. A ńfi ìdùnnú wo iṣẹ́ rẹ̀,
Ọ̀run, òkun àti ilẹ̀.
A ńwo ìṣẹ̀dá rẹ̀ bí ìwé,
Wọ́n ńmú wa hó ìhó ayọ̀.
A wá ńfayọ̀ wàásù fáráyé,
A ńkéde ’jọba Ọlọ́run.
Ìbí rẹ̀ àti ìbùkún rẹ̀,
Là ńfayọ̀ ròyìn káàkiri.
Ayọ̀ ayérayé wọlé dé,
Bójúmọ́ ṣe ńtẹ̀ lé òru.
Ayé àtọ̀run t’Ọ́lọ́run wí
Yóò máyọ̀ ayérayé wá.
(ÈGBÈ)
Ọlọ́run wa ni ayọ̀ wa,
Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ńdùn mọ́ wa.
Èrò rẹ̀ jinlẹ̀, iṣẹ́ rẹ̀ tóbi,
Oore àtagbára rẹ̀ pọ̀!
(Tún wo Diu. 16:15; Aísá. 12:6; Jòh. 15:11.)