ORIN 161
Inú Mi Ń Dùn Láti Ṣe Ìfẹ́ Rẹ
1. Nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi
Ní inú Odò Jọ́dánì,
Gbogbo ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀
Ni láti ṣe ìfẹ́ Jáà.
Ó borí ìdẹwò Sátánì.
Ó fi ìtara wàásù.
Ó ń láyọ̀ torí pó ń ṣèfẹ́ Jáà.
Èmi náà ti pinnu pé:
(ÈGBÈ)
Màá fayọ̀ ṣèfẹ́ rẹ Baba.
Ẹnu mi yóò máa ròyìn rẹ.
Mò ń láyọ̀ gan-an látọkàn wá,
Bí mo ṣe ń ṣe ìfẹ́ rẹ.
Màá fayé mi sìn ọ́ Baba.
Ìwọ l’Orísun ayọ̀ mi.
Ìfẹ́ tòótọ́ lo ní sí mi.
Títí láé nìyìn rẹ máa
Wà lẹ́nu mi!
2. Bí mo ṣe wá mọ̀ ọ́ Jèhófà,
Ayé mi ti wá dára sí i.
Mo fi gbogbo ayé mi fún ọ.
Tìrẹ ni màá máa ṣe láé.
Mò ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ará,
Tí a jọ ń ṣe ìfẹ́ rẹ.
Gbogbo iṣẹ́ àgbàyanu rẹ,
Ni màá kéde fáráyé.
(ÈGBÈ)
Màá fayọ̀ ṣèfẹ́ rẹ Baba.
Ẹnu mi yóò máa ròyìn rẹ.
Mò ń láyọ̀ gan-an látọkàn wá,
Bí mo ṣe ń ṣe ìfẹ́ rẹ.
Màá fayé mi sìn ọ́ Baba.
Ìwọ l’Orísun ayọ̀ mi.
Ìfẹ́ tòótọ́ lo ní sí mi.
Títí láé nìyìn rẹ máa
Wà lẹ́nu mi!
Màá fayọ̀ ṣèfẹ́ rẹ!