A Máa Pín Ìwé Ìkésíni Síbi Ìrántí Ikú Kristi Kárí Ayé!
1. Ìpolongo àkànṣe wo la máa ṣe kárí ayé ká tó ṣe Ìrántí Ikú Kristi?
1 “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” (Lúùkù 22:19) Láti ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù yìí, àwa olùjọsìn Jèhófà pẹ̀lú àwọn olùfìfẹ́hàn máa péjọ ní March 30, ọdún 2010 láti ṣèrántí ikú Jésù. A máa pín àkànṣe ìwé ìkésíni síbi Ìrántí Ikú Kristi kárí ayé láti March 13 sí March 30.
2. Kí la lè sọ tá a bá fẹ́ fún àwọn èèyàn ní ìwé ìkésíni síbi Ìrántí Ikú Kristi?
2 Bá A Ṣe Máa Ṣe É: O lè fún ẹni tó o bá bá nílé ní ìwé náà kó bàa lè rí àwòrán tó wà lẹ́yìn rẹ̀, kó o wá sọ pé: “Nírọ̀lẹ́ March 30, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn kárí ayé máa péjọ láti ṣèrántí ikú Jésù. Ìdí rèé tí mo fi wá fún ìwọ àti ìdílé rẹ ní ìwé ìkésíni yìí kẹ́ ẹ lè wà níbẹ̀ lọ́jọ́ yẹn. Ẹ lè mú àwọn ọ̀rẹ́ yín dání pẹ̀lú. Jọ̀wọ́, wo àkókò àti ibi tá a ti máa ṣe é.” Bí àyè bá ṣe wà sí, o lè ka Lúùkù 22:19 láti fi àṣẹ tí Jésù pa nínú Ìwé Mímọ́ han onítọ̀hún. Àmọ́, ẹ má gbàgbé pé ìwọ̀nba àkókò díẹ̀ la ní láti kárí àwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, torí náà, á dáa ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa ṣe ṣókí.
3. Àwọn wo la lè pè?
3 Bí ìjọ yín bá ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tó pọ̀, àwọn alàgbà lè sọ pé kẹ́ ẹ máa fi ìwé ìkésíni sílẹ̀ fáwọn tí ò sí nílé nígbà àkọ́kọ́ tẹ́ ẹ débẹ̀. Láwọn ìgbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀, ẹ tún lè fún àwọn èèyàn ní àwọn ìwé ìròyìn. Ẹ rí i dájú pé ẹ pe àwọn ìpadàbẹ̀wò yín, àwọn tẹ́ ẹ̀ ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn ọmọléèwé yín, àwọn ìbátan yín, àwọn ará àdúgbò yín àtàwọn míì tẹ́ ẹ bá mọ̀.
4. Kí la máa ṣe tá a bá mọrírì bí Jèhófà ṣe fìfẹ́ pèsè ìràpadà fún wa?
4 Múra Tán Láti Kópa ní Kíkún: Àkókò Ìrántí Ikú Kristi jẹ́ ìgbà tó dáa gan-an tá a lè fi kún ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn wa. Ṣé o lè ṣètò àkókò rẹ kó o lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́? Ṣé o láwọn ọmọ tàbí àwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ń ṣe dáadáa nípa tẹ̀mí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, o ò ṣe sọ fún àwọn alàgbà kí wọ́n lè wò ó bóyá àwọn ẹni tuntun náà ti tóótun láti di akéde tí kò tíì ṣe ìrìbọmi, káwọn náà bàa lè kópa nínú ìgbòkègbodò àkànṣe yìí. Bá a bá mọrírì bí Jèhófà ṣe fìfẹ́ pèsè ìràpadà fún wa, láfikún sí wíwá síbi Ìrántí Ikú Kristi, a máa tún sapá láti pe ọ̀pọ̀ èèyàn, bó bá ti lè ṣeé ṣe tó wá síbẹ̀.—Jòh. 3:16.