ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 2/09 ojú ìwé 1
  • A Máa Pín Ìwé Ìkésíni Síbi Ìrántí Ikú Kristi Lákànṣe!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Máa Pín Ìwé Ìkésíni Síbi Ìrántí Ikú Kristi Lákànṣe!
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Máa Pín Ìwé Ìkésíni Síbi Ìrántí Ikú Kristi Kárí Ayé!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • A Máa Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Pín Ìwé Ìkésíni Síbi Ìrántí Ikú Kristi Ní March 17
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • A Máa Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Pín Ìwé Ìkésíni Síbi Ìrántí Ikú Kristi Ní March 22
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
  • A Máa Pín Ìwé Ìkésíni Síbi Ìrántí Ikú Kristi Bẹ̀rẹ̀ Láti April 2
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
km 2/09 ojú ìwé 1

A Máa Pín Ìwé Ìkésíni Síbi Ìrántí Ikú Kristi Lákànṣe!

1. Kí làwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe láti March 21, 2009, kí sì nìdí?

1 Lọ́jọ́ Thursday, April 9, 2009, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run jákèjádò ayé máa pé jọ láti ronú lórí ọ̀nà tó ga jù lọ tí Jèhófà gbà fìfẹ́ hàn sí aráyé. (Róòmù 5:6-8) Ara wa ti wà lọ́nà láti rí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn olùfìfẹ́hàn tó máa pé jọ pẹ̀lú wa nígbà tá a bá ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi. A máa pín àkànṣe ìwé ìkésíni síbí Ìrántí Ikú Kristi kárí ayé bẹ̀rẹ̀ láti March 21.

2. Àwọn nǹkan wo ló yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá ń fún àwọn èèyàn ní ìwé ìkésíni náà?

2 Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Fi Sọ́kàn: Lo àwọn àwòrán, àwọn ìbéèrè àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nínú ìwé ìkésíni náà lọ́nà tó múná dóko. Bí àpẹẹrẹ, o lè fi àwòrán tó wà níwájú han ẹni tó ò ń bá sọ̀rọ̀, kó o wá sọ pé: “Mo fẹ́ kó o wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tá a máa ṣe lọ́jọ́ Thursday, April 9, 2009.” Lẹ́yìn náà kó o wá tọ́ka sí àkòrí ìwé ìkésíni náà àtàwọn ìbéèrè tó wà lábẹ́ ẹ̀. Sọ fún ẹni tó ò ń bá sọ̀rọ̀ pé òun náà lè pé àwọn ìdílé ẹ̀ àtàwọn míì tó bá fẹ́ dáni.

3. Kí ló yẹ ká ṣe lẹ́yìn tá a bá ti fún àwọn èèyàn ní ìwé ìkésíni?

3 Tí ìpínlẹ̀ ìwàásù yín bá tóbi, àwọn alàgbà lè sọ pé kẹ́ ẹ máa fi ìwé ìkésíni náà sílẹ̀ fáwọn tẹ́ ò bá bá nílé. Ní òpin ọ̀sẹ̀, kẹ́ ẹ máa pín àwọn ìwé ìròyìn pẹ̀lú ìwé ìkésíni náà. Kẹ́ ẹ fi ṣe àfojúsùn yín láti pé àwọn ìpadàbẹ̀wò, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìbátan, ọmọ iléèwé, àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́, ará àdúgbò, àtàwọn ojúlùmọ̀ yín wá. Lọ́dún tó kọjá, arábìnrin kan fún ọgbọ̀n [30] lára àwọn ìbátan rẹ̀ ní ìwé ìkésíni, ó sì máa ń rán wọn létí látìgbàdégbà nípa bí ọjọ́ náà ti ṣe pàtàkì tó. Inú arábìnrin yìí dùn gan-an nígbà tó rí mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] lára wọn tó wá, tí mẹ́rin lára wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́yìn náà.

4. Ìmúra sílẹ̀ wo ló yẹ ká ṣe báyìí, kí sì nìdí?

4 Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Múra Sílẹ̀ Báyìí: Ọ̀pọ̀ akéde ló lè fi kún ìgbòkègbodò wọn nínú iṣẹ́ ìsìn pápá lóṣù March àti April. Tó o bá láwọn ọmọ tàbí àwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ń tẹ̀ síwájú, àkókò yìí máa dára gan-an fún wọn láti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi. Ìsinsìnyí ló yẹ kó o ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò láti kọ́wọ́ ti ìpolongo Ìrántí Ikú Kristi tó ṣàgbéyọ ìfẹ́ gíga jù lọ tí Ọlọ́run àti Jésù ní sí wa.—Jòh. 3:16; 15:13.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́