Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ February 9
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ FEBRUARY 9
Orin 118
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 25-28
No. 1: Jẹ́nẹ́sísì 25:1-18
No. 2: Olùkọ́ Ńlá Náà Sin Àwọn Ẹlòmíràn (lr orí 6)
No. 3: Kí Ni Ìyàtọ̀ Tó Wà Láàárín Ọkàn àti Ẹ̀mí? (td-YR 40B)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Orin 211
5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.
8 min: Ìwé Ìléwọ́ Tuntun. Àsọyé tó ṣàlàyé ìwé ìléwọ́ tuntun náà àti bá a ṣe lè lò ó. Gbogbo àwọn tó bá fìfẹ́ hàn sí ìwàásù wa ni ká máa fún. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo ìwé ìléwọ́ yìí tá a bá ń wàásù láti ilé dé ilé àti nígbà ìpadàbẹ̀wò.
10 min: Àwọn Ìrírí Tá A Ní Nígbà Tá A Fi Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ Àwọn Èèyàn. Sọ àwọn àṣeyọrí táwọn ará ṣe nínú ìjọ yín lópin ọ̀sẹ̀ tẹ́ ẹ yà sọ́tọ̀ láti fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ àwọn èèyàn lóṣù tó kọjá. Fún àwọn ará níṣìírí pé kí wọ́n máa kópa lọ́jọ́ tá a yà sọ́tọ̀ láti máa fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ àwọn èèyàn.
12 min: “A Máa Pín Ìwé Ìkésíni Síbi Ìrántí Ikú Kristi Lákànṣe!” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fún gbogbo àwọn tó wà nípàdé ní ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan ìwé ìkésíni síbí Ìrántí Ikú Kristi, kẹ́ ẹ sì jíròrò ohun tó wà níbẹ̀. Ṣàṣefihàn bá a ṣe lè fún àwọn èèyàn ní ìwé ìkésíni náà.
Orin 87