Ìwé Ìkésíni Pàtàkì
1. Ìgbà wo la máa bẹ̀rẹ̀ sí í pín ìwé ìkésíni sí àpéjọ ti ọdún 2014?
1 Tó o bá náwó nára gan-an láti se àkànṣe àsè kan fún àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ rẹ, ó dájú pé yóò yá ọ lára láti pe àwọn èèyàn wá síbi àpèjẹ náà. Bákan náà, iṣẹ́ ti lọ gan-an lórí àsè tẹ̀mí tá a máa gbádùn láwọn àpéjọ àgbáyé àti àpéjọ àgbègbè ti ọdún 2014. A ó láǹfààní láti fi ìwé ìkésíni pe àwọn èèyàn wá sí àpéjọ àgbègbè tó bá ku ọ̀sẹ̀ mẹ́ta tá a máa ṣe é. Kí ló máa mú kó yá wa lára láti pé àwọn èèyàn wá sí àwọn àpéjọ yìí?
2. Kí ló máa mú ká kópa lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ nínú pípín ìwé ìkésíni sí àpéjọ yìí?
2 Tá a bá ronú nípa bí àwa fúnra wa ṣe jàǹfààní látinú àsè tẹ̀mí tí Jèhófà ń pèsè fún wa láwọn àpéjọ wa, èyí á mú ká kópa lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ nínú pínpín ìwé ìkésíni sí àwọn àpéjọ yìí. (Aísá. 65:13, 14) Ó yẹ ká rántí pé àwọn ìwé ìkésíni tí à ń pín lọ́dọọdún máa ń méso rere jáde. Àwọn kan lára àwọn tá a fún ní ìwé ìkésíni máa wá sí àpéjọ náà. Láìka bí àwọn tó wá ṣe pọ̀ tó, akitiyan tá a ṣe nígbà tí à ń pín ìwé ìkésíni yìí máa mú ìyìn bá orúkọ Jèhófà, á sì tún fi hàn pé a jẹ́ ọ̀làwọ́ bíi ti Jèhófà.—Sm. 145:3, 7; Ìṣí. 22:17.
3. Báwo lá ṣe máa pín ìwé ìkésíni yìí?
3 Ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ìjọ kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu bí ìjọ ṣe máa pín ìwé ìkésíni yìí, wọ́n á sì sọ fún yín bóyá kí ẹ fi ìwé ìkésíni sí ẹnu ọ̀nà àwọn tí kò bá sí nílé tàbí bóyá kí ẹ pín in nígbà tẹ́ ẹ bá ń wàásù láwọn ibi tí èrò pọ̀ sí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Tí ẹ bá ń pín ìwé ìkésíni lópin ọ̀sẹ̀, ẹ lè fún àwọn èèyàn ní ìwé ìròyìn níbi tẹ́ ẹ bá ti rí i pé ó yẹ bẹ́ẹ̀. Tí ọjọ́ tẹ́ ẹ máa bẹ̀rẹ̀ sí í pín ìwé ìkésíni bá bọ́ sí Sátidé àkọ́kọ́ lóṣù, ẹ gbájú mọ́ bí ẹ ṣe máa pín ìwé ìkésíni dípò kí ẹ bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn tá a bá parí pínpín ìwé ìkésíni náà, ẹ wo bí inú wa ṣe máa dùn tó láti mọ̀ pé àwa náà fi ìtara kópa nínú rẹ̀ tá a sì tún pe ọ̀pọ̀ èèyàn láti wá gbádùn àsè tẹ̀mí tí Jèhófà pèsè!